Mister Johnson (fíìmù)
Mister Johnson | |
---|---|
Fáìlì:Mister Johnson.jpg | |
Adarí | Bruce Beresford |
Olùgbékalẹ̀ | Michael Fitzgerald |
Àwọn òṣèré | |
Orin | Georges Delerue |
Ìyàwòrán sinimá | Peter James |
Olóòtú | Humphrey Dixon |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Avenue Pictures |
Olùpín | 20th Century Fox |
Déètì àgbéjáde |
|
Àkókò | 97 minutes |
Orílẹ̀-èdè | United States |
Èdè | English |
Owó àrígbàwọlé | $1,464,242 |
Mister Johnson jẹ́ fíìmù ilẹ̀ America ti ọdún 1990 tó dá lórí ìwé ìtàn àròsọ ti 1939, láti ọwọ́ Joyce Cary. Wọ́n ṣe ìṣẹ̀dá fíìmù náà gẹ́gẹ́ bí èyí tó wáyé ní ọdún 1929. Nínú fíìmù náà, òṣèrékùnrin, ìyẹn Maynard Eziashi ṣe eré gẹ́gẹ́ bí ọmọ Nàìjíríà tó ń ṣiṣẹ́ ní [1] British civil service. Fíìmù yìí ni fíìmù ilẹ̀ America àkọ́kọ́ tí wọ́n máa yà ní Nàìjíríà.[2]
Àhunpọ̀ ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mister Johnson, tó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tó gbé àṣà ilẹ̀ Britain wọ, tó sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ adájọ́ Harry Rudbeck. Ó fẹ́ Bamu ní ìlànà kìrìsìtẹ́ẹ́nì, ó sì gbà láti pín ọrọ̀ àti ayé ọ̀làjú rẹ̀ pẹ̀lú obìnrin náà. Àmọ́ obìnrin yìí ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Nàìjíríà tó jẹ́, kò sì hùwá bí i ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Waziri gbìyànjú láti fi owó lọ Johnson kí ó ba lè fi lẹ́tà ìjọba láti ọ́fíísì Rudbeck's hàn òun, àmọ́ Johnson kọ̀ jálẹ̀ nítorí ìwà ìfọkàntán tó ní sí ilẹ̀ Britain. Johnson jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lówó àmọ́ Rudbeck ò ṣetán láti fún ní owó àsan-án-lẹ̀. Bamu náà padà sí ilé àwọn òbí rẹ̀ nítorí Johnson ò le san owó orí oṣooṣù rẹ̀ mọ́. Johnson gbà láti gba owó lọ́wọ́ Waziri ní pàṣípáàrọ̀ lẹ́tà láti ọ́fíìsì Rudbeck.
Oríṣiríṣi nǹkan ṣẹlẹ̀ ní ibiṣé tó mú wọn da dúró lẹ́nu iṣẹ́. Johnson, Bamu, àti ọmọ wọn padà sí Zungo, nítorí àwọn ìdílé Bamu ta kú pé ó gbọdọ̀ padà wá sí ilé. Johnson bèrè owó lọ́wọ́ Waziri, àmọ́ Waziri pàṣẹ fún àwọn aṣọ́bodè rẹ̀ kí wọ́n kán ẹsẹ̀ Johnson. Johnson fo fèrèsé náà jáde, ó sì sálọ, àmọ́ ó ṣàkíyèsi pé ìyàwó rẹ̀ ti lọ. Ó mu ọtí yó, ó sì lọ sí ilé-ìtàjà Sargy Gollup láti lọ jí owó nínú igbá owó rẹ̀. Àmọ́ Sargy mú un, ó sì yin ìbọn fun ní. Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí ní jà, Johnson sì pa Sargy nípa fífí píìnì gún un. Olóyè ìlù pàṣẹ̀ fún Waziri kí ó ṣàwárí Johnson tàbí kó pèsè ẹlòmìíràn tó máa gba ìdá́lẹ́bi náà. Johnson ṣe ìbẹ̀wò sí ìyàwó rè láti bèrè oúnjẹ, ibẹ̀ sì ni ẹ̀gbọ́nkùnrin Bamu mu, tí ó sì fi lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́. Wọ́n padà pa Johnson.
Àwọn akópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Maynard Eziashi bí i Mister Johnson
- Pierce Brosnan bí i Harry Rudbeck
- Edward Woodward bí i Sargy Gollup
- Beatie Edney bí i Celia Rudbeck
- Denis Quilley bí i Bulteen
- Nick Reding bí i Tring
- Bella Enahoro bí i Bamu
- Femi Fatoba bí i Waziri
- Kwabena Manso bí i Benjamin
- Hubert Ogunde bí i Brimah
- Sola Adeyemi bí i Ajali
- Jerry Linus bí i Saleh
- George Menta bí i Emil
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ D'Angelo, Mike. "The director of Driving Miss Daisy chased that Oscar winner with Mister Johnson". Film. Archived from the original on 2019-11-27. Retrieved 2024-02-13.
- ↑ Sinyard, Neil. "Mister Johnson: Off the Beaten Track". The Criterion Collection.