Mọfọ́lọ́jì èdè Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Mofoloji ede Yoruba)
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Mofoloji[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Mofólójì: Harrison Adéníyì Ojú-Ìwé 71-100.

Ìfáárà

Ìpele tàbí ìsòrí márùn-ún ni a lè pín gírámà èdè sí. Àwon ìpèle yìí náà ni fònétíìkì tàbí ètò sísàpèjúwe ìró, fonólójì tàbí ìbásepò ìró; sèméntíìkì tabí èt`o ìtumò; síntáàsì tàbí ètò tí ó dale gbólóhùn, àti mofólójì tabí ètò nípa sísèdá òrò. Gbogbo àwon ìpele wònyí ni ó ní ìbásepò tí ó sòro láti yà sótò. ...

Ifunniloruko[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìfúnnilórúko ní Èdè Yorùbá: Olú Àlàbá Ojú-Ìwé 101-116.

Ìfáárà

Ní àwùjo adúláwò káàkiri ayé, orúko se pàtàkì púpò. Ojú ayé nìkan kó ni a fi í wò ó; a máa fi ojú-inú àti ojú èmí pàápàá wò ó. Nítorí náà orúko je mó ìhun òrò-orúko nínú èdè adúláwò kòòkan; ó je mó ìmòlára ènìyàn, ó je mó ìgbàgbó, ìfé, àníyan àti ìrètí ènìyàn pèlú....

Amulo ede Yoruba[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àmúlò (Èdè Yorùbá) Dèjì Médùbi Ojú-Ìwé 117-129.

Ìfáárà

Èdè, èdè, èdè láìsí èdè, èèyàn kò sunwòn láwùjo. Eròngbà wa nínú aròko yìí ni láti tanná sí àmúlò èdè Yorùbá ní orísirísi ònà. A kò gbìdánwò láti parí isé síbí, nítorí náà, ìpàjùbà lásán ni eyí jé fún isé ribiribi tó wa níwájú....

Aayan ogbufo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Aáyan Ògbufò: Ayò Yusuff Ojú-Ìwé 130-144.

Ìfáárà

Tí ènìyàn bá se alábàápàdé àkosílè kan tí wón se ní èdè tó se àjòjì sí i, ònà àbáyo tí yóò kókó wá sókan rè ni ìranwó eni tí yóò se aáyan ògbufò irú àkosílè béè. A le so pé isé ògbufò ni ó férè nira jùlo nínú gbogbo isé. ...

Apola oruko[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àpólà Orúko (ní Èdè Yorùbá): títí Sàlámì Ojú-Ìwé 145-

Ìfáárà

Àpólà-orúko ni eyo òrò tàbí àsopò òrò tí a le lò gégé bí olùwà, àbò tàbí àbò-atókùn nínú gbólóhùn aseégbà. A lè fi ipò métèèta yìí hàn nínú àwon àpeere ìsàlè yìí.


Iwe ti a yewo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Harrison Adéníyì (2000) Ìlò Èdè àti Èdá-Èdè Yorùbá Olu Akin Printing Press. ISBN 978-047-386-6. Ìmò Èdá-Èdè àti Èdè Yorùbá: Harrison Adéníyì & títí Onàdípè Ojú-Ìwé 1-23.