Jump to content

Nabot Manasse

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Nabot Manasse tàbí Nabot Shiyoma (b. Ovamboland, Namibia — tí ó fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ ogbọ̀n oṣù Kínní ọdún 1958[1]) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùsọ́ àgùntàn méje tí Matti Tarkkanen yàn ní Oniipa, Ovamboland, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 1925, lábé ìdarí Bishop Tampere, Jaakko Gummerus.[2][3][4]

A ò mọ ìgbà tí a bí Manasse. Ìgbà tí a ṣe ìtẹ̀bomi fun ni ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1908.[1]

Manasse kó nípa iṣẹ́ àlùfáà Oniipa láàrin ọdún 1922 sí 1925. Ó ṣisẹ́ ní Onayena láàrin ọdún 1925 sí 1950 àti láàrin ọdún 1953 sí 1958, àti ní Okankolo láàrin ọdún 1950 sí 1953.[1]

Manasse ṣe ìgbéyàwó lẹ́ẹ̀mejì, lákọ́kọ́ pẹ̀lú Helena yaKalunduka láàrin ọdún 1909 sí 1933, àti pẹ̀lú Kristina kaNambuli láti 1933. Kò ní ọmọ.[1]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 Nambala, Shekutaamba V. V. (1995). Ondjokonona yaasita naateolohi muELCIN 1925–1992. Oniipa, Namibia: ELCIN. p. 197. 
  2. Peltola 1958, p. 212.
  3. Pentti 1958, p. 113.
  4. Vilho Shigwedha & Lovisa Nampala (2006). Aawambo Kingdoms, History and Cultural Change. Perspectives from Northern Namibia.. Switzerland: P. Schlettwein Publishing. p. 80.