Orin-ìyìn orílẹ̀-èdè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti National anthem)
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Èyí ni orin tí orílè-ède kan máa n ko nígbà tí wón bá n se ayeye. Wón máa n ko ó tí olórí orílè-èdè mìíràn bá wá bè wón wò. Wón máa n ko ó níbi tí àwon ènìyàn bá pé jo sí tàbí ibi òsèlú tó bá se pàtàkì. Enìkan lè dá a ko fún gbogbo ènìyàn tàbí kí gbogbo ènìyàn kópa níní kíko rè.

Òrò inú orin yìí máa n yin orílè-èdè àti àwon ènìyàn tí ó wà nínú rè. Orin yìí máa n sábàá so àwon ohun ribiribi tí ilè kan ti gbé se. Bouget de I’Isle ni ó ko orin ti ilè Faranse ní àsìkò ogun ní 1792. Francis Scott Key ni o ko ti ilè Àmérìkà ní 1814. A kò mo eni tí ó ko ‘God save the Queen’ ti ilè Gèésì sùgbón 1745 ni wón kókó ko ó. ‘Arise, O Compatriots’ ni ó bèrè orin orílè-èdè Nàìjíríà tí a n lò lówólówó báyìí.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]