Ọba Ònpetu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Oba Onpetu)
Jump to navigation Jump to search

Oba Onpetu

==ORÌKÌ OBA ÒNPETU ÒJÉ== lati ENU LÀGBÀOYÈKALÈ ÀLÀDÉ(OMO ISÉ FOYÁNMU)

Ó dilé wa lóhùn-ún òòò

Témi bá n lo sónà token òkun lolórí omi, in

Mo fé lolé Oba bí adé ò mèedi òjé aa dígò sorò


1 Lótùú olójà lodòjé ilé

Omo afínjú eye tíí mumi lágbada tòdò tí mo n bà lonà èbì, Òró gangan ni wón fomo odó fún odó òòò,

N lé ni lóhùn ú nose okúmorò lónpetu,

Lóòró gangan gan táwo todò lónpetu

Ìda kàlà n baba mi àgbà kan ó tó mùko àdò mònyàn

Ìyá ò dámi ní àgbalè rí, n dúró gangan le fi múmi ní omo

Obí n jesu kò wale írí,

Mo bá tòde baba mi lo,

Omo obí tàlùpò lówó won ò wasà,

Obí, obí te túkùú ò gba toríigi keke

Omo Oba gbélo, gbébò lebì.

Mo pàdé egún kan lókè lààká o

Ojó ò t òòjó, oojó ò tojò,

Tí mo pàdé egún kan lókè lààká o,

Mo rò pé were ò tètè dami mo pemi ni in,

Témi b á n lo sónà be mo monlé e wa,

Ó ní banyan ò gòkè, tó dòkè kó mo on rókè, kómó on bo á sísàlè èè

2 Ó ni ò ní bóun dé pálò baba òun

Mo ní n bo ni in?

Olóun lomo èbì òjé a dígò soorò

Mo bèèrè, mo bèèrè lówóo láyèwú n jósí òòò

Ólólúefón leni tó kókó joba lójèé

O lólú eyìn ló tèle

Mo níró loo pa

Mo ní àwon lomo Oba mínrin,

Àwon lomo Oba mìnrin

Omo Oba òmìnrìn mínrín tolú òmínrín tó kókó tile-ifè wá

jònpetu,

Eléyun nì baba tó bi Obandí,

Obándé un ló bí ògánndolè

Ògándolè un lóbí Ona dede

Obadede un lóbí ifátólú

Ifátólú un baba Àsàmú Atóèbí eni tó kókó degbó òòjé tó ò parun

Àsàmú òhún un ló sore onílè

À sore onílé

Un ló sore Olóólà

Un ló dìyekan won


3 Tí an bá pónko olóólà òhún tí jé

Olóólà ohun nííjé abú-bí ekùn-mo-pani-je

Aké kaaka kí olórò ó gbo baba òtún àgòrò

Òtún àgòrò, kó tó kolúdé, òkìkí amúlè bí ìbon

Òkè léyìn pòrò

Akìí kamo fónbí, un ó bi t`mi pòpò Oba mèdì òjé maa dígò sorò

Lókùú Olójà lodòjé ilé

Omo afínjú eye tí í mumi lágbada

Témi bá n lo sónà bè mo mo on lée waaa

Ojó ò tójó

Ojo òò tojò

Ìyàwó Olúòjé ó lo sí àwon ona èyìnkùlé

Ó lo rèé sègbònsè

O rógun lókèè odò loogun bá sú dededee

Un ló bá sáré wolé

Ó ni baálé wa, òlóòdè e wa

Ó ni wá wogun lókè odò, ogun sú dededee

N baálé re bá kápó, ó kórun

Olúòjé ó kófà

N ló bá sòló

Ó wàgbo sòló

N ló bá lógun lo


4 Ìgbà tó di ni sègbè eléèkejì yi èwèwè wè,

Ìyàwó lo sí ònà àwon èyìnkùlé n

N ló bá rógun lókè odò n logun bá su de de de,

Ó ní baálé wa, olóòdè wa

O ní wá wogun lókè odò ogun sú de dè dee,

N ní baálé re, n lo ba kápó,

N ló bá kórun Olúòjé ba wàgbo sàlàà, n lo ba wàgbo sòló, n lóbá lógun lo

Lóòtó ní, béè ni, òdodo ni

Ìgbà tó di ní sègbè eléèketa yí èwè wèwè

Lóòtó ni béèni òdodo ni

Baálè, ìyàwó bá lo sónà oja

N ló bá rógun lókè odò,

N logun bá sú de de de

N ló bá sáré wolé wá

Ó ni baálé won, òlóòdè wa

O ní wáá wogun lékùlé re ogun dé dan dan dan an


5 N ló bá w’`agbo sàlà, o wàgbo sòló

N ló bá kápó

N ló bá kórun

N ni ún bá n lógun ún lo

Ó lógun ti ti ti

Owó re ò bógun

O lógun tí tí tí, lówó re ò bógun

Ìgbà tó lógun tí tí tí ogun jìnnà

N logun bá polúòjé ò ò ò

Ó polúòjé so sáàrin ììgbé òo

Won retí Olúòjé tí tí tí, won ò ri

Ìgbà tó dojó èkejì

Ni wón bá fín wá Obi á kiri

Igbà ti an waja Obi ti an fi woba kiri títí

Wón bá koba láàrin ìgbé òo

Níbi tógún paá si ò ò ò ò,

In wón bá kàn-án níhòhò

Kò sáso kankan lára re

Wón léèse,

Èétirí enìkan kìíri, enìkan kìí rùkú oolójà nihòhò,

N wón bá mája Oba


6 N wón bá pa á

Ni wón bá bó awo re

Ni wón bá fi bo Oba

Ni wón bá n pé àbáà dáso epínrín lé epínrín,

Kòtíì táso òjé mu ròrun aso aláso ni,

Èbáà dáso kókò lagbàlá alé

Kòtíì táso táwon òjé mú ròrun aso alaso ni,

Kée dáso kókò láàrán

Kèè táso tólúòjé múròrun aso aláso ni

Awo ajá pélénjá pèlènjà pélénjá

N laso òjé é mú pèkun

Moparun yékété etí I yemetu

Ìrà mokò un o sòkùn fún won lónà tèbì

Omo gbálújobi,


7 Mo sùsú lódò kan oso ti í je weru

Sùsú lelénmò bínú, eléruku jámò

Akìí bèèrè àgbà nílé Olúòjé mo olórí adé ò ò ò

N jé nú lé lóhùn-ún san àbi ò san

Bí ò bá san mó, baba anìnùn ló dà hun un

Témi bá n lo sónà an bè è, mo mo on le e wa aa

Àlàfià ke wàà bí o ?

Àjàmú ní n be lólúòjé níhà hin ò,

Àjàmú ní n be lólúòjé mó on gbórò enu mi

Tí ùn n bá n lo sónà be mo monlée wa

Bóri gbeni gbeni bá gbeni,

Àtàrí gbènyàn gbènyàn tí an ba n gbàwon ènìyàn

Oò póríi taa ní ó mo gbè è o o o ?

Lóòtó ni béè ni òdodo ni, Òri sàlàkó, oníìlí ò fé ó tú

Agbara-bi-awú abáni gbélé ní se bée

Òjúòjú elérù gbérù

Ó tì lójú elégàn mo rèé tamó baárú

Sàlàkó, ni kúrú níhìn-ín, lóhùn-ún


8 Lèkùn òjòwú, wón tìgbásè gbó tútú

Aso pami un kú in ní lu kára bí ajere

O láì wíni loran kó sìì di teni

Oníkálùkù kó yáa senu ti è láàbò

Bóri gbeni gbeni báa’gbeni,

Atari gbènyàn, bí won bá gbawon ènìyàn,

Oò póríi taa ni ó mo on gbèè ó o ?

Àjàmú mó on gbórò enu mi

Abídoyè Àjàmú tí n be lólúòjé lòò ni o,

Òò pórí taa ní ó mo gbèè o o ?

Lóòtó ni, béè ni òdodo ni,

Oríi Bóládé, bí ó ti mo on gbè ó tòó pin ni

Àwon omo Atóbatélè kó tó wáá joba

Bémi bá n lo sónà bè mo molé wa aa

Àjàa`mú àró afúgò sorò

Àjàmú àró okúmorò lónpetu mo aparun jékété etíi yemetu ìlá mokò un ò sokùn tún won lónà an tèbì

Témi bá n lo sónà be, mo monú ilé waa


9 Oò pori ta ní ó mo gbe ó ò ò ò ò ?

Orí Adéolé bí ó ti mó on gbèè ó ótóópin in in

Ò póri ta ni ó mo gbèè ó o ?

Orí òsékùnmólá, bí ó ti mó on gbè e o tóò pin ni,

Ò pórí ta ni ó mo gbèè ó o ?

Orí Atóyèbí bí ó ti mó on gbè è o tóò pin ni in

Ó póri ta ni ó mo gbèè ó o ?

Orí Atóyèbí atówúrà sabàjà

Atóyèbí Alárìnje è baaka, abi kété kété babaáje ní tako tabo

Ìbaaka bàbà sojú òtún ní kànnà kànna kànna

O ní, kì í se pésin baba enìkan màrà

Kìí jé pésin baba enìkan mo òn jó

Sùgbón esin Atóyèbí

N lo mò ón jó ju taráyòókù lo

Abi kété kété baba á jó wariwo ojú ogun

Àbénté ta, n lorúko tó bí baba Oba lómo

Àbèntè ta, n lorúko tó bí baba Oba lómo káloolé lónìí mo jákàn mo on jììgan bìbaaka bàbá soojú òtún kànnà

O pori ta ní ó mo gbè ó ò ò ò ò ?


10 Orí Àmódù, bí ó ti mo on gbè ó tó ò pin ni,

Eja ló nibú, bí ó ti mó on gbè ó tó ò pin ni

O pórí ta ní ó mo gbè o ?

Adédoyin, Àgbàkiri Òsùn sí,

N wón n yoko Efúndélé lénu

O fárí kondoro o fiyawo kan, babaa lúfóyè

Bóri won bí ó ti mó on gbèè ó tóòpin ni in

Témi bá n lo sónà bè mo mo on le e waa Ò póríi ta ni ó mo gbèè ó o

Témi gbogbo Oba sónà bè mo mo on le wa

Bórí gbogbo Oba wònwònyi dááko bórí won ó ti mó on gbèè o tóò pin ni

Témi bá n lo sónà bè mo mo on le wa aa

Àlà e wà bi ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ní tiwaaa?


11 Tí ùn n bá n lo sónà tòòkun, nkun lolórí omi

Ojàre òsà làbábi níyìn yò

Àjeku, a jèkàà làbá lókèrè

Èmi náà làbá bi lókì orin mi

Orin láwèéréke, orin àwérèke

Orin asínsínndada, asìnsínndada

Bàtá ògèdè

Saworo Òkótó

Atiro ò yàrìnjó

Àrìnjó ò yeni ti n tiro

E kilo fún mo lárìnjó

     Ki molárìnjó mó on mésè rè le le le 


     Témi bá n lo sónà be mo mo on lé e e wa a a 
     Omo Oba n mínni 

Omo Oba minni

Omo Oba òmìnnì mínní tolú òmínní to kókó tile-Ifè wa jònpetuu

Témi bá n lo sónà an bè mo mo on lé e wa aa

Bóri won bí ó ti mó on gbèè ó tóò pin ni in

Tí un bá n lo sónà bè mo mo on lé e wa aa

12 Àlà e wà bí òòò?

Inú ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ni tiwaa,

Èbì òjèé a bidò sorò

Lótùnún Olójà lodoje ilé,

Omo afinjú eye tíí muni inú agbada

Orin: Àlùfáà ni ò ya ní wá

Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo


Lílé: Àlùfáà ni ò yà ní wa

Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo

Lílé: Àlùfáà ni ò yà níí wa

Ègbè: Bódún dé áá fòkó sebo

Lilé: Àlùùfáà ni ò yà nííu wa

Ègbè: Bódún dé aá fòkó sebo o o o .


ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KOKO NÍUN ORÍKÌ OBA ÒNPETU


1 Omo Odùduwà ni ònpetu kí ó tó wá je Oba ni Òjé Ilé.

2 Oríkì Òrànányàn Òrànmíyàn Akòtún

Akin nílé

Akin lógun

Òràn ni mo yàn, un ò yankú

Òràn mo yan, un ò yàrùn

Baba ni á yènà àyèbá

Ó ní a yenú òwú, a rook abé re.