Jump to content

Obadja Iihuhua

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Uushunga Obadja Iihuhua (tí a bí ní c. 1875, Omapale, Ondonga, Ovamboland, Namibia — tí ó fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ Kẹ̀wá oṣù kẹfà ọdún)[1] jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùsọ́ àgùntàn méje tí Matti Tarkkanen yàn ní Oniipa, Ovamboland, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 1925 lábé ìdarí Bíṣọ́bù Tampere, Jaakko Gummerus. Wọ́n yan Arákùnrin rẹ̀ Sakeus Iihuhua sípò àlùfáà ní ọjọ́ kan náà.[2]

Iihuhua lọ sí ilé ìwé ní Oniipa ní àárín ọdún 1916 sí 1919 ó sì kọ́ nípa isẹ olùṣọ́ àgùntàn ní láàrin ọdún 1922 sí ọdún 25. Ó ṣiṣẹ̀ ní ilé ìwé Oniipa láàrin ọdún 1920 sí 21, àti gẹ́gẹ́ bi olùṣọ́ àgùntàn Uukwaluudhi ní ọdún 1925 àti gẹ́gẹ́ bi olùṣọ́ àgùntàn Uukolonkadhi láàrín ọdún 1926 sí 1940.[1]

Iihuhua fẹ́ Maria gaNepundo (ọdún ìbí 1906) ní ọdún 1925, àwọn méjèèjì sì ní ọmọkùnrin méjì àti ọmọbìnrin mẹ́ta.[1]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 1.2 Nambala, Shekutaamba V. V. (1995). Ondjokonona yaasita naateolohi muELCIN 1925–1992. Oniipa, Namibia: ELCIN. 
  2. Peltola 1958, p. 212.