Odò Bẹ́núé
Odò Benue (Faransé: la Bénoué), tí a mọ̀ sí Odò Chadda tàbí Tchadda, jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn odò tí ó ń sùn sínú Odò Niger. Odò yìí gùn tó ìwọ̀n ẹgbèje (Àádọ́rinlẹ́gbẹ̀rin) ìsun jágere dáadáa lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Fún ìdí èyí, ó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì ní àgbègbè tí ó ti ń ṣàn.
Ojú-ilẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó máa gbéra láti Adamawa Plateau ní apá Àríwá Cameroon, ní apá ìwọ̀-oòrùn tí yóò ti gba ìlú Garoua àti amù-ìsọlọ́jọ̀ Lagdo ṣàn lọ sí apá gúúsù Nàìjíríà tí àwọn òkè Mandara, yóò gba Jimeta, Makurdi kí ó tó wà pàdé Odò Niger ní Lọ́kọ́ja.
Àwọn ìsun-omi ńláńlá ni Odò Faro àti Gongola àti Mayo ní Kebbi, èyí tí ó so Odò Logone (lára odò Chad) lásìkò omíyalé. Àwọn ìsun-omi yòókù ni Odò Taraba àti Odò Katsina Ala. Níbi tí odò tí ń pàdé, odò Benue jù tí Niger lọ pẹ̀lú ìwọ̀n. Ìdásílẹ̀ gbòógì kí ó ti di ọdún 1960 jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé irínwó (3,400) ìwọ̀n cubic ní ìṣẹ́jú àáyá (120, 000 cu ft/s) fún odò Benue tí Niger sì jẹ́ (2,500) ní ìṣẹ́jú àáyá (88,000 cu ft/s). Ni gbogbo ọdún yẹn, ìsun omi dinku torí pé kò sí omi.
Omíyalé wáyé ní odò Benue ní oṣù Òwàrà, 2012 tí ó fa àlékún púpọ̀ bá àwọn ejò olóró ní ẹ̀kùn Duguri, ìjọba Ìbílẹ̀ Alkaleri, Ìpínlẹ̀ Bauchi.
Ìròyìn kan ní 2013 sọ pé ó lé igba èèyàn ti oró ejò ti pá ní ẹ̀kùn yìí. Iléwòsàn ìjọba ní Kaltungo, Ìpínlẹ̀ Gombe ní Nàìjíríà ní ibùdó ìtọ́jú tó súnmọ́ jù. "Ẹni tí orí bá kó yọ tí ó dé Kaltungo fún ìtọ́jú yóò padà láàárin sílé ọjọ́ méjì.
[convert: needs a number]i 2,500 cubic metres per second (88,000 cu ft/s)
-
Awọn ile kekere Benoue
-
Benoue wiwo lati drone
-
Kọja Odò Benue lati Lagdo pẹlu Canoe kan
Awọn itọkasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]