Ogun Ndondakusuka
Ogun Ndondakusuka | |||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|
Part of Ìjà abẹ́lé Zulu | |||||||
Cetshwayo-c1875.jpg Cetshwayo, the battle's victor | |||||||
| |||||||
Àwọn agbógun tira wọn | |||||||
Cetshwayo faction (uSuthu) | Mbuyazi faction (iziGqoza) | ||||||
Àwọn apàṣẹ | |||||||
Cetshwayo | Mbuyazi John Robert Dunn | ||||||
Agbára | |||||||
c. 20,000 | c. 7,000 | ||||||
Òfò àti ìfarapa | |||||||
unknown | over 20,000 (including non-combatants) |
Ogun Ndondakusuka (ọjọ́ kejì oṣù Kejìlá ọdún 1856) jẹ́ ogun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Ìjọba Zulu láàrin Cetshwayo àti Mbuyazi, àwọn ọmọ méjì àkọ́kọ́ ọba Mpande, àwọn ènìyàn ma ń pe ogun yìí ní Ogun abẹ́lé Zulu kejì. Cetshwayo pa Mbuyazi ní ogún, èyí sì mú kí ìjọba Zulu wà ní ìṣàkóso Cetshwayo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé bàbá rẹ̀ ló sì wà lórí oyè. Wọ́n pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Mbuyazi ní ojú ogun, àti àwọn ọmọ márùn-ún ọba Mpande tó kù.
Àwọn tí ó ja ogun náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mbuyazi ò ní àwọn àtìlẹ́yìn tó Cetshwayo. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí bàbá rẹ̀ gbà á níyànjú, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn òyìnbó agbègbè Natal lábẹ́ ìdarí John Dunn láti ràn án lọ́wọ́. Dunn kó àwọn ọlọ́pá márùnlélọ́gbọ̀n àti àwọn ọdẹ ọgọ́rùn-ún. Àwọn ọmọ ogun Mbuyazi tó ẹgbẹ̀rún méje. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wòye pé Cetshwayo ni ó yẹ kí ó di ọba, nítorí èyí, àwọn ọmọ ogun tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yi ká láti jà fún. Àwọn òyìnbó lo ìbon ṣùgbọ́n iye àwọn ọmọ ogun Cetshwayo pò.