Jump to content

Ojú tí Ifá fi n Wọ́ Obìnrin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Oju ti Ifa fi n Wo Obinrin)

Ifá jẹ òrìṣà kan pàtàkì láàárín àwọn Yorùbá àwọn Yorúbà gbàgbọ́ wípé Olodumare lo ran ifá wa láti Ode Ọrun láti wa fi Ọgbọ́n rẹ̀ tún ilé ayé se. Ọgbọ́n ìmọ̀ àti Òye tí Olódùmarè fi fún ifá ló fun ifá ní ipò ńlá láàárín àwọn ìbọ ilẹ Yorùbá ….”a kéré-finú-sọgbọ́n”ni oríki ifá. Eleyi lo fi han wa gẹ́gẹ́ bí Abimbọla (1969) ti gbe kala.

Nínú isẹ́ àgbékalẹ̀ Ilesanmi ó wa jẹ ki a mọ wípé ifá ni alárínà fún gbogbo ọmọ Oodua oun ni ó dabi agbenuṣọ fún gbogbo àwọn òrìṣà àti Olódùmarè ohùn ṣì la kà ṣí ẹni to ń ṣe àjèwò fún gbogbo mùtúmùwà. Èyí wa fún ni ibò asojú fún gbogbo àwọn Irúnmọlẹ̀ yòókù. Aroko leti ọpọn ifa 1998.

Ifa jẹ ẹwi tí ó máà ń lọ láti ilú kan ṣì èkejì láti dífá. Èyí lo ṣe okùnfa bíbá ọ̀pọ̀ obìnrin pàdé ó ṣI fun ni àǹfáàní láti fẹ ìyàwó púpọ̀ torí irúfẹ́ isé ti ifá ń ṣe. Èyí sí lo fa to fi ṣeṣe fún ifá láti mọ ìwà wọn ó wú oniruuru ìwà yìí jáde torí àjọsepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Obìnrin. Ó maa ń ṣawo kiri ní. Gbogbo ibi tí ifá ba ti dé lo ti ń yan ìyàwó, èyí lo mu ifá rí àríṣá àwọn Obìnrín.

Obìnrín ní a le pè ni ìdàkejì Ọkùnrin tí a ba wo Tíórì Àbùdá onibeji fún àgbéyèwò lítíréṣọ̀ ifá tí Ilésamí pàjúbà rẹ Tíórì yìí nì ó jẹ kí á mọ pé laisi ọ̀tún osi ko le dádúró.

Erongba opilẹkọ yìí ni láti tàn ìmọ́lẹ̀ ṣí ipò tí ifá fi àwọn Obìnrin ṣi Àkíyèsí àwọn ipò wọ̀nyí si han nínú àwọn ẹsẹ ifá. Ojú méjì Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ifá fi wo àwọn Obìnrin

(i) Ó rí wọn gẹ́gẹ́ bi ẹni réré ti ko ṣe maniyen to lẹ́wà.

(ii) Ifá rì àwọn obìnrin ní ìdàkejì gẹ́gẹ́ bi èsù tàbí olubi ẹ̀dá.

Ṣebí tibi tirẹ la dálé ayé. Bẹ́ẹ̀ ṣI ni a kìí dára ka ma kù ṣíbì kan. Àwọn òbinrin la ba máà pè ní ejò gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ ifá. Nítorí ìdí èyí ifá rọ àwọn ọkùnrin láti gbọ́n nínú gbọ́n lode tí ọ̀rọ̀ ba ti di ọ̀rọ̀ obìnrin.

OBÌNRIN GẸ́GẸ́ BÌÍ KÒṢÉÉMÀNÍ TÀBÍ ẸNI RERE

Nínú ìpín yìí ifá bẹ̀rẹ̀ ṣí ni ṣe àfihàn wọ́n láti òde pé wọ́n tẹwà ó ṣi rí obìnrin gẹ́gẹ́ bi ẹni rere. Ẹwà wọn ṣI maa ń jẹyọ nínú àwọ̀ tí Olódùmarè fit a wọn lọ́rẹ àto ọmu ti ó fi ṣe àfikún ẹwà wọn. Omú tàbí ọyàn obìnrin ní iyì rẹ̀ ohun ṣi ni onfa to ń fa àwọn ọkùnrin to si ààbí èmú to ń mu wọn mọ́lè lára obìnrin òdí méjì, ìjìnlẹ̀ ohun Eleu ifá Apa kinni pg 54-1-3 fìdí èyí mílẹ̀ pé

Funfun niyì eyin

Egun gadaaga niyi orun

Omu sìkì siki niyi obinrin

Omu sikisiki niyi obinrin pg 54 1-4

Ohun iyi àti àmúyẹra ní fún ọkọ rẹ bi èyin odi meji Obinrin ba funfun. Bakannaa ni ifá tún fi ye wa pe ki obinrin lómú kọ lopin ẹwa. Ṣùgbọ́n ìmọ́tótó náà tún se pàtàkì láti le e perí ọkùnrin wale ìjìnlẹ̀ ohùn enu ifá láti ọwọ Wade Abimbọla Apa kini pg 51-25-26.

Síyínka Súnyinka

Baláfúnjú ba ji a sìnyìnká sóko pg. 51 25-26.

A ko gbọ́dọ̀ gbàgbé wipe ara ẹwà ita ti òrúnmìlà ri lára Àwòrán ní ó fig be e ni ìyàwó. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pe bi àwòrán tí jọju to ko ìwà àrokò ti ifa ń fi èyí pa ní pe ẹwà kii se ogbo nìkan. Bi a ti ń wo ẹwà ifa ni ó yẹ ki a naa wo ti inú.

Ifá wo ẹwà inú àwọn obìnrin ni oríṣìírìṣí ọ̀nà Aabo jẹ ìrànlọ́wọ́ fún òrúnmìlà nigba to lalèjo mẹta Iku, Àrùn àti Èsù. Ààbò lo ko nǹkan ìlò ọkọ rẹ lo ta ni ọjà Ejigbomekan ní owó pọ́ọ́kú ó ra ounjẹ wọn ṣi tójú àwọn àlejò wọn. Ìwa ti Ààbò wù yìí mu kí àwọn àlejò mẹ́ẹ́tẹ̀ta wọ̀nyí fì ifá sílẹ̀ laipa. Wọn fún Ọ̀rúnmìlà ní ẹ̀bùn ki wọn ó to fí ilé rẹ̀ ṣílẹ̀. Inú Ọ̀rúnmìlà dun nítorí ìwà Ààbò àti ori re tí ó ko ran-an. Èyí ṣi mu kì Òrùnmìlà fẹran Ààbò.

Òdá Owo awo kóro

Ààbò Obìnrin rẹ̀ - pg 20 1-2

Ifá ó ṣI ní Oọkan a a yọ na

Ní Òrúnmìlà ba pé Ààbò obìnrin rẹ̀ pé kí ó kó àwọn nǹkan ìní òun lọ sọ́jà lọ tà. Ìjìnlẹ̀ ohun Ẹnu ifa iwe kinni

Ifa fẹ ìwà náà gẹ́gẹ́ bí aya Ọ̀lẹ àti ọ̀bùn ayé ní ìwà jẹ. Èyí mí ki ọ̀rúnmìlà le e lọ ki lọ ṣi nǹkan ò ba gún régé mọ́ àwọn ènìyàn ṣá lọ́dọ̀ rẹ. Àpọ́nlé kò si fún ọ̀rúnmìlà mọ bìí ti tẹ́lẹ̀ ṣebi ko kuku ṣí àpọ́nlé fún ọba tí kò ní olorì.

Ká mú rágbá

Ká fi ta rágbá

Ka mu ràgbà

Ka fit a ràgbà

Iwa la n wa o, ìwà

Alara ó ri ìwà fun mi

Ìwà la ń wa o ìwà…

Ìwà ni o jẹ gẹ́gẹ́ bí orison áàsikí fún Ọ̀rùnmìlà ṣùgbọ́n ko mọ iyì ìwà àfi ìgbà tí ìwà fi ilé Ọ̀rúnmìlà sílẹ̀. Ẹ̀mí náà jẹ ọkan lára obìnrin ọ̀rúnmìlà. Ifá fi ẹ̀mí hàn gẹ́gẹ́ bi ọ̀pọ́múléró. Ìdí nìyí tí Ọ̀rúnmìlà fí gbé ẹ̀mí ni ìyàwó ko ba le ṣe rere láyé. Á gbọ́dọ̀ mò wípé ẹmi ní ó gbé ìwá ró. LaiṣI èmí ko si àrà tí ènìyàn le da láyé. Aadogun, aadogbọn, ọwọ́ èmí ni gbogbo rẹ wa. Àwọn Yorùbá ṣì gbàgbọ́ wípé ẹ̀mí gígún ni ṣan ìyà Ọ̀rúnmìlà ko le gbàgbé ẹmí nítorí ohun rere ti ẹ̀mí fún Ọ̀rúnmìlà ní ànfààní láti ṣe. Ire gbogbo tí ẹ̀dá ń wa kiri ọwọ́ èmí ní gbogbo rẹ wa. Fun àpẹẹrẹ:-

A dia fun Ọ̀rúnmìlà

Níjọ́ to ń lọ r’ẹmi ọmọ Olódùmarè s’Obinrin

Ó ní àṣé bẹmi ò ba bọ́

Owo ń bẹ

Hin hin owo ni bẹ

Àṣà bemi o ba bọ̣

Aya ń bẹ

Hin hin aya ń bẹ

Àsé bẹmi ò bá bọ́

Ọmọ n bẹ

Hin hin ọmọ ń bẹ

Aṣe bẹmi ò bá bọ̀

Ire gbogbo ń bẹ

Hin hin ire gbogbo n bẹ …


Wande Abimbọla Ìjìnlẹ̀ ohùn ẹnu ifá Pg 16 (Eji ogbè). Apa kinni

Odù náà jẹ ọken nínú àwọn ìyàwó ọ̀rúnmìlà tí o ko orire ràn án. Alátìlẹyìn ni odù jẹ fún Ọ̀rúnmìlà. O dìgbà tọmọ èkọ́sẹ́ ifa ba to fojú ba odù ko to dẹni ara rẹ. Èyí túmọ̀ ṣi pé babaláwo tí kò ba fojú bodù kò tii dangajia.

Ẹni bá fojú bodù

Yoo ṣi dawo

A fojú bodù a rire


OBÌNRIN GẸ́GẸ́ BI OLUBI

Àbùdá kejì yìí ní yóò tu tìfun tèdọ̀ ihà kejì tí ifá kọ ṣi àwọn obinrin. Ifá ri àwọn Obinrin gẹ́gẹ́ bi ẹni ibi, alásejù, òjòwú àti àjẹ́. Ó fi ìhà yìí hàn tori pe a kìí dara ka ma kù ṣibi kan.

Ifá fi wọn wé aláigbọràn ewúrẹ́ tí wọ́n máà ń ṣe àtojúbọ̀ àwọn ohùn tí ko kàn wọ́n. Bi àpẹẹrẹ Yemòó fẹ mọ ìdí agbára Óòsáála ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú èdó tí ó fi ń pa ẹran ohun tójú tíle-túle alaigbọran ń ri ní ojú rẹ rí lọjọ yìí. Òrúnmìlà ṣọ fún àwọn ìyàwó yòókù láti mase yojú wo ọ̀rọ̀mòdìmọ̀dì obìnrin rẹ̀ tuntun.

Ìyáálé pé àwọn yòókù láti lọ yojú wo ìyàwó tuntun yìí inú bí ìyàwó tuntu, o si jade. Ó sì fi wọn rẹ́ bayí ni Àjàkálẹ̀ àrùn ṣi wọle tọ wọn. A ko le fí gbogbo ara da ìyaálé àti àwọn ìyàwó yòókù lẹ́bi torí Ọ̀rúnmìlà ti yẹ kì ó fi ìyàwó tuntun han àwọn to ba ní ilé ṣùgbọ́n ó kọ̀ ko ṣe èyí nípa ojú tí ọ̀rúnmìlà fí wo Obìnrin tí a le ṣọ pe Ọ̀rúnmìlà lo fí owọ́ ara rẹ da ilé ara rẹ̀ ru. Ẹni ba wa wàhálà dandan ni ki ori i.

Ifá tun fí àwọn obinrin hàn gẹ́gẹ́ bí òjòwú, ti wọn kìí fẹ ki ọkọ wọn fẹ ìyàwó mìíràn le wọn àfi àwọn nìkan. Fún àpẹẹrẹ:

Ọ̀kan ṣoṣo péré lobìnrin

Dùn mọ lọ́wọ́ ọkọ

Bí wọn ba di méjì wọn a dòjòwú

Bí wọn ba di mẹta

Wọn a dẹta ń túlé

Bí wọn bad è mẹrin

Wọn a dí iwọ̀ lo rín mi ni mo rin ọ

Bi wọn ba dí marun

Wọn a di lágbájá ni ó run ọkọ

Wa tan lóhùn ṣuṣuusu

Bì wọ́n ba dí mẹ́fà

Wọn a dìkà

Bi wọ́n ba de meje

Wọn a d’àjẹ́

Bí wọ́n ba di mẹjọ

Wọ́n a di ìyá alátàrí bàmbà…

Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá Apá Kìínní pg 29-43 (Òyèkú meji) Wande Abimbọla

Ohun tí o jẹ ìjọjú ní wípé Ifá gan-an mọ pé ó sàn fún ọkùnrin láti fẹ ìyàwó kan. Ẹ̀sẹ̀ amọmọda ni èyí ko yẹ ki Ifá maa fẹ ìyàwó lórí ara wọn.

Eke àti Ọ̀dàlẹ̀ ni Ifá tún pe àwọn obìnrin. Ohùn tí Ifa ń ṣọ níbí ni pe Obìnrin ko ṣe fi inú hàn ṣùgbọ́n ibeere tí a ba bi Ifá ni pe ṣe ọkúnrin ni o se fi inú hàn. Bi o ti wa ni lìkì ni ó wa ni gbanja

Obinrin leke

Obinrin lodalẹ

Keniyan se pẹlẹ

Ki o ma finu han f’oobinrin (CL Adeoye pg 243 ẹsẹ ifá kan nínú Obara meji)

Ifá tẹ síwájú nìpa pipe àwọn obìnrin ni dọ́kodọ́kọ àti alágbèrè. Èro ifá ni pé àlè yiyan yìí kii jẹ ki wọn tonu lọpọ igba pe ẹni to ba keré sọkọ ni wọn maa ń ba dálè.

Àgbìgbọ̀niwọ̀nràn, The unfaithful Ifá priest

You have been seeing bad things,

Worse things are yet to come;

Worse things the father of bad things

Ifa divination was performed for Agbigboniworan

Who was going to the house of Onkoromebi to perform divination

Onikoromebi, husband of an adulterous wife

It was because of the incessant adultery

Of his wife that oniworonebi

Performed divination

Igba ti o fìyà jẹ obinrin naa tan

O gbe ju, agbala

O ṣi de e lokun mọ́lẹ̀

Ni àgbàlá ni onikoromebi fi ìyàwó rẹ ṣI

Ti o fì lọ bìfa léèrè

Àgbìgbò ní ki Onikoromebi o ṣe ṣùúrù

O ní ẹni tí o torii rẹ bi ifa léèré

Mbẹ loride nínú àgbàlá

Igba ti onikoromebi gbọ

Oju ti i

Ko lee lo tu ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ mọ

Ó ní ki Àgbìgbò o lọ ba òun tu u sílẹ̀

Ìgbà tí Agbìgbo débẹ̀

Dípò ki o tu obìnrin náà sílẹ̀

fefẹ ni ń fẹ ẹ….

(Ifa Divination Poetry pg 87-88)

Nígba tí ìyàwó onikoromebi náà yan babalawo ti wọn ni ko ba wọn wo aiṣan agbere lara rẹ. Ṣùgbọ́n ojọ yìí ní ibi wọn wolẹ nítorí bibẹ ní oníkòròmebi bẹ àwọn mejeeji. Babalawo tì wọn ni ko wo aya onikoromebi ko ni ètọ́ lati ṣe èyí. Bí wọ́n ba pe obìnrin ni dokọdọkọ. Obìnrin ko le da ọkọ dó laì ri ọkunrin. Fi obìnrin é yálẹ̀ yàlè alainisuru a ri eleyi nínú Sixteen great poems of Ifa Not long again. They sent for Ọ̀rúnmìlà in the abode of Olokun when Ọ̀rúnmìlà was going he did not take Ọ̀rọ̀ his wife along he promised to return on the seventeenth day. He gave sixteen ọ̀ké measures of cowries to ọ̀rọ̀. He also gave her clothes and plenty of food in the third month that Ọ̀rúmìlà had stayed away. For Example:

Ọ̀rọ̀ met Ońdàáró

They agreed to be Concubines

Ondaaro gave her five oke measures

Of cowries He cohabited with her,

And he became pregnant.


Ọ̀rọ̀ met onigoosun

After they had talked together

Onìgoosun gave her ten Okẹ measures

Of cowries

And cohabited with her

And again she became pregnant

Not long again ọ̀rọ̀ met a man named Olúùkọ́ọlọ́ He gave har tiventy okẹ measures of cowries after they hed fun with each other ọ̀rọ̀ became pregnant again. All together the children of Ọ̀rọ̀ thus became six and they were all boys out of the six children three were children of Concubines.

Nínú ẹsẹ̀ Ifá yìí fi hàn wá wípé Owo l’obinrin mọ̀ gbogbo àwọn mẹtẹẹta to ba dálè yìí owó ní wọn fi hàn ọ̀rọ̀.

Aritẹnimọọ wi, a fi apadi fẹnfẹ bo tirẹ̀ mọ́lẹ̀ ni Ifá ibeere ti a ba bi ọ̀rúnmìlà nip e ṣe ko ba obinrin kankan ni àjọsepọ̀ ni ìrìn àjò rẹ. Ko ṣi ẹni to mọ iye ọmọ ti o`hun na bi si àjò. The Sixteen Great Poems of Ifa pg 216-221 Wande Abimbọla

Ifá rí obinrin han gẹ́gẹ́ bi àjẹ́

Fun àpẹẹrẹ:

Bẹ́ẹ̀ ba gbolagbalagba epo òun ewùso

Ẹ lo lee ko fún ìyàmi Òsòròngà

Apa nimawaagun, Olokiki Orù

Ajẹdọ-tútù-mọ-bi

Obinrin kukuru regiregi

(The 16 Great Poems of Ifa pg 242 Wande Abimbọla)


Àwọn obìnrin náà ni Ifá tún fihàn bí aforesunu se. Wọn fore ṣu Ọ̀rúnmìlà nílé ayé pé àwọn o ni sọ̀kalẹ̀ ní ikùn rẹ mọ́ àfìgbà to ba rúbọ.

Wọn ní kí ní ń jẹ sisọ kale

Wọn ni a tun ṣòkalẹ̀ mọ́

Ọ̀rúnmìlà ti mọ Oko ni oko ikun to gbin èpà síbẹ̀. O mọ pé ìhòhò ní àwọn ẹlẹyẹ wa ko to gbà láti ṣe wọn ní àánú. Kìí ṣe Ọ̀rúnmìlà nikan ní àwọn ẹlẹyẹ bẹ. Ọ̀rúnmìlà tí gbàgbé pe bí ojo oore ba pé asiwèrè a gbàgbé àti pé ìwọ̀n ní oore.

Aláwomọ́ àti alakooba ní wọn gẹ́gẹ́ bi ìwà ti ìyá arúgbó tí a fi se àpẹẹrẹ nínú òyèkú méjì wù. Nígbà to fọ̀rọ̀ isú lọ ẹnikan ti ko gba a jẹ o fi ọwọ epo sàmì sìi lára. Ebi kii ṣe ebi ẹni to fi ọwọ́ epo to ọ ni lẹkẹ ẹni to rin ìrìn ìwàsà o di dandan kan fi èkùrọ́ lọ o Fun àpẹẹrẹ:

Ó mú ọwọ epo

Ó fi to mi lẹ́ẹ̀kẹ́ẹ mi ọ̀tún itọrorọ itọrọrọ

Ó mú ọwọ epo

Ó fi to mi leẹkẹ mi òsì itọ̀rọ̀rọ̀ itọ̀rọ̀rọ̀

Ìjìnlẹ̀ ohùn ẹnú ifá pg 29-107-110 Òyèkú meji Wande Abimbọla

Ifá tún jẹ ka mọ pé ìkà àti òfinràn ni wọn. Nínú méjì Yemoo ìyàwó oriṣà ńlá lo ji omi àwọn ẹlẹyẹ pọn to ṣo tun fọ asọ òdé rẹ ṣínú odò náà


The witches asked, Did

She stab herself and Èlúlù

Replied she did not

Stab herself, the blood was

From her private part (The 16 Great poem ifá)

The witches therefore swallowed both the husband and the wife. Álásejù baba àsetẹ́ tún ní ifá fẹ wọn ohun ti wọn ṣe náà nìyí tí ó je ki nǹkan bọ́tí mọ wọn lọ́wọ́. Wọn kí àsejù bọ ọ̀rọ̀ wọn. Fun àpẹẹrẹ :

Igbó etílé t’oun tẹgbin

Adapọ owó toun tiyà

Iwo o ju mi

Ẹmi o ju ọ

Lara ile ẹni fi ń fojú di ni (Oladipọ Yemitan ati Olajide Ogundele Oju Osupa Apa kẹta)

Ifá jẹ ka mọ wípé Olódùmarè yan òrìṣà mẹrindinlogun ó fi òbìnrin kan ṣi wípé ki wọ́n maa lọ silẹ́ aye láti maa lọ rúbọ fún àwọn ẹ̀mí airí. Nígbà tí wọn dé ilé ayé ọsun tí ó jẹ obìnrin àárín wọn ní ó maa ń ṣe ìpèsè fún àwọn ẹ̀mí airi yìí.

Ní gbobgo ìgbà tí wọn bat i n lọ gbe ẹbọ yìí lọ fún àwọn ẹmí airi yìí oṣun kìí tẹ̀lẹ́ wọn, ti wọn ba ti de ibẹ̀ gbogbo àwọn òrìṣà wọ̀nyí lo maa ń ko gbogbo ìpèsè yìí jẹ, ṣùgbọ́n wọn ko mọ wípé Olódùmarè tí fun ọṣun ni agbára láàrín wọn nígbà to yá gbogbo nǹken kò gún régé mọ́ wọn ṣa ògùn títí kò jẹ mọ. Bayi ní wọn ṣe pínú láàrín ara wọ́n láti rán òrìṣà ńlá lọ sọdọ Olódùmarè ṣùgbọ́n òrìṣà ńlá kọ láti lọ. Ní ifá bá ní kí wọ́n ran ohùn lọ sọ́dọ̣̀ Olódùmarè nígbà tí Ifá de ibẹ̀ lo ba ṣọ fún Olódùmarè wípé nǹkan ko gún régé mọ̀ o. Olódùmarè ba ni ọṣun ń kọ o ni gbogbo nǹkan te ba ti n ṣe e fi t’obinrin ṣi.

Bayí ní gbogbo àwọn òrìṣà yòókù bu lọ ṣi ọ̀dọ̀ ọṣun láti bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀ṣun ko gba ẹ̀bẹ̀ bẹ́ẹ̀ lo bẹ̀rẹ̀ ṣi ni mu gbogbo wọn bu lẹyọ kọọkan láti orí Oosala, Ọ̀rúnmìlà Ṣungo, ọya obalùfọ̀n àti bebe lọ ó ní nǹkan tí wọn jọ ràn àwọn ń kọ? lo ba sọ fún wọn wípé ọmọ to wà ní ikùn ohùn tí ohun ba fi bí obinrin Olódùmarè yóò fí àwọn ẹlomíran dipo wọn. Ṣùgbọ́n to ba jẹ pe ọkunrin ní ohun fi bi o ni ohun yoo fi wọn silẹ́ wípé ohùn náà ti ni lara wọn niyẹ̀n ni ọṣun ba fi oyin rẹ bi ọkunrin láti ìgbà yìí tí wọn bat í ń lọ̀ ṣI igbó ẹmí airi láti lọ run wọn maa ń lọ gbé ọmọ ọ̀ṣun láti fi ọwọ́ tirẹ̀ náà ṣI gbogbo nǹkan ti wọn ba ń se tan ba se tan wọn à dá pada fún ìyá rẹ̀.

Igba yìí lo ti ṣọ pé tó ba jẹ ọkunrin ko ma jẹ Akin osó. Ni ki a

Ka kúnlẹ̀

Kí Obìnrin

Òbìnrin lo bi wa

Ka to di ènìyàn …


Ifá jẹ ka mọ̀ wípé alagbará ni àwọn obìnrin Olodumare lọ pin wọn ile agbara yìí. Gbogbo bi àwọn òrìṣà yòókù se ń ko ípèsè yìí jẹ ọ̀ṣun mọ ṣi ṣùgbọ́n ó ṣe bi ènipe ohun ko mọ nǹkan to ń sẹlẹ̀.

Alagbara ní wọn bí wọn se le lo agbara wọn lati fi ṣe daradara ni wọn fi le ṣe búburú. (Olóyè Babalọla Fatoogun (Ifá Priest) Ilobu Oṣogbo.)

Ifá tún ṣọ ìtàn nipa àwọn obìnrin ajọ àti ìpàdé to maa ń ṣe o fi hàn bo fe lo agbara àwíṣẹ lati fig be ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ni gbogbo ìgbà tí wọn ba ti fẹ ṣe ìpàdé.

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà gbogbo agbara àwísẹ to ba sọ labẹ ge. Nitorí ó dúró gẹ́gẹ́ bi agbára ìtúsílẹ̀ àti agbara Hayese.

Bo ṣe dí ojo kan àwọn ọ̀fá wa ọ̀nà láti ji agbara náà gbe wọn ko ri bi wọn ṣe lọ ba ìyàwó ọ̀rúnmìlà pìyí pe to ba juwe ibi ti agbara òhún wa fun àwọn àwọn o fun lówó.

Ìyàwó Ọ̀rúnmìlà gba owo, o ṣi gbe agbára náà o lọ bo mọ inú eérú ojú àrò. Nígba tí Ọ̀rúnmìlà fẹ ṣe ìpàdé a kọkọ gbìyànjú làtí bi ifá léèrè lori bi ìpàdé yoo ṣe ri ni wọn ban i ko lọ bọ ṣango ojú eérú tori ke nǹkan ba le ṣenu ire àti pe kí àsírí to farasin le ba hàn sáyé.

Ìgbà tí Ọ̀rúnmìlà ti gbe eéru ojú aaro lati bọ Ṣango tan lo ba ri agbara rẹ̀ tí ọ̀tá to ń pè ni ìyàwó bo mọ inú eeru náà. Ìgbà tí ọ̀tá ri pé wọn ko ri Ọ̀rúnmìlà mú náà bá tún lọ ba ìyàwó rẹ láti tún ta ete mìíràn ìyàwó Ọ̀rúnmìlà pẹ̀lú àwọn ọ̀tá náà ba gbìmọ̀ láti lọ ju agbara rẹ sínú odò.

Ìgbà ti ọjọ́ àjò ń pe bọ̀ Ọ̀rúnmìlà lọ bi Ifa léèrè bí ọjọ́ àjọ yoo ṣe rí nítorí ó tí mọ bi obinrin se jẹ́. Ṣùgbọ́n ẹbọ to jade ṣí nip é ki o lọ ni eja abori ńlá kan, obi àbàtà, àti iyàn ìlèkẹ̀ ko fi bọ ẹlẹda rẹ. Lílà tí Ọ̀rúnmìlà la inú ẹja lo ba agbára rẹ̀ nínú ẹja. Ó gbà pe obinrin ni òdàlẹ̀ ni wọn. (Lati ẹnu Dro Agbájé ti wọn gba lẹnu Babalawo)

Ìtàn kan ti Ifa ṣọ fì Obìnrin hàn gẹ́gẹ́ bi ọ̀dèlè, afẹnimadenu olubi ènìyàn. Ifá ṣọ ìtàn nípa Ọ̀rúnmìlà ENI TÍ MỌ FỌ̀RỌ̀ WÁ LẸ́NU WÒ.

Oloye Babalọla Falogun Ifa Priest Ilobu Osogbo.