Jump to content

Olanrewaju Adepoju

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Olóyè Moshood Ọláńrewájú Adépọ̀jù, olóyè Alásà ti ilú Ìbàdàn jẹ́ akéwì, òǹkọ̀wé eré oniṣe, ewì àti gbajúmọ̀ tí ó ń lọ ẹ̀bùn ewì rẹ̀ láti ní ipa tí ó lè yí àwọn ìgbésẹ̀ ìjọba tí ò dára padà. Bákan náà òun ló kọ ìwé ìtàn "Sàgbà Dèwe, Ìrònú Akéwì, Orírun Yorùbá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní àsìkò ìjọba ológun, Àdépọ̀jù máa ń fi orin ewì rẹ̀ ṣe ìkìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ fún àwọn ọ̀bàyéjẹ́ àti ìgbésẹ̀ ìjọba tí kò wúlò fún ará ìlú. Irúfẹ́ orin ewì rẹ̀ yìí máa ń kìlọ̀ ìwà, fífi àléébù hàn àti fún ìgbádùn àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

Ògbóǹtagìrì akéwì yìí jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pàdánù ojú rẹ̀ látàrí ọjọ́ ogbó ní ọ̀dún díẹ̀ ṣẹ́yìn, kótó di pé ó ta térù ní ìpá.

Erè èrò àti àfojúsùn rẹ̀ lórí ewì mú ìdàgbàsókè bá iṣẹ́ ọnà rẹ̀ ti wà nínú ìwé àti fọ́nrán fún ọjọ́ iwájú bí Ẹ̀ṣọ́ ti gbe kalẹ̀ nínú orin ìdárò rẹ̀.Ògbóǹtagìrì akéwì Yorùbá, òǹkọ̀tàn eré-oníṣe àti òǹkọ̀tàn. Ọlárewájú Adépọ̀jù relé ogbó nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́talélọ́gọ́rin.