Òmuò-Òkè-Èkìtì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Omuo-Oke-Ekiti)
Jump to navigation Jump to search
Òmùò-òkè
Country Flag of Nigeria.svg Nigeria
Ipinle Ipinle Ekiti

Omuo-Oke-Ekiti

I.A. Owolabi

I.A. Owólabí (2005), ‘Òmuò-Òkè-Èkìtì’, láti inú ‘fọnọ́lọ́jì Ẹ̀ka-èdè Òmìò-Òkè-Èkìtì’,. Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè, ojú-ìwé 1-3.

1.0. Ìfáárà

Àwọn ohun tí a gbé yẹ̀wò nínú orí kìn-ín-ní yìí ni àlàyé lórí ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ìlú Òmùò-òkè Èkìtì. A mẹ́nuba oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí a gbà ṣe ìwádìí àti iṣẹ́ tí àwọn onímọ̀ ti ṣe lórí ẹ̀ka èdè, ni àgbéyẹ̀wò lítírésọ̀. Ohun ti a fi kásẹ̀ àlàyé wa ní orí yìí nib í iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ṣe fẹ̀ tó àti tíọ́rì ti a ṣe àmúlò rẹ̀.

1.1. ÌLÚ ÒMÙÒ-ÒKÈ-ÈKÌTÌ

Ìlà oòrùn Èkìtì ni Òmùò òkè wà. Ìjọba ìbílẹ̀ ìlà Oòrùn ni ìpínlẹ̀ Èkìtì ni Òmùò-òkè tẹ̀dó sí. Òmùò-òkè tó kìlómítà méjìlélọ́gọ́ọ̀rin sí Adó-Èkìtì tí ó jé olú-ìlú ìpínlẹ̀ Èkìtì. Òmùò-òkè ni ìpínlẹ̀ Èkìtì parí sí kí a tó máa- lọ sí ìpìnlẹ̀ Kogi. Ìdí nìyí tí ó fi bá àwọn ìlú bí i, Yàgbà, Ìjùmú, Ìyàmoyè pààlà. Bákan náà ni ó tún bá Erítí Àkókó pààlà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìwádìí fihàn wí pé àwọn ìlú bí Ejurín, Ìlíṣà, Ìṣàyà, Ìgbèṣí, Àhàn, Ìlúdọ̀fin, Orújú, Ìwòrò, Ìráfún ni ó parapọ̀ di Òmùò òkè, Ọláitan àti Ọládiípò (2002:3) Iṣẹ́ òòjọ́ wọn ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò ṣíṣe. Ìdí ti wọn fi ń ṣe iṣẹ́ òwò ni wí pé, Òmùò òkè ni wọn ti máa ń kò ẹrù lọ sí òkè ọya. Ẹ̀ka èdè Òmùò-òkè yàtọ̀ sí Òmùò kọta Òmùò Ọbádóore. Òmùò Èkìtì jẹ́ àpapọ̀ ìlú mẹ́ta.

(i) Òmùò-òkè Èkìtì

(ii) Òmùò kọta

(iii) Òmùò Ọbádóore

Èdè Òmùò-òkè farapẹ́ èdè Kàbbà, Ìgbàgún àti Yàgbàgún ni ìpinlẹ̀ Kogi. O ṣe é ṣe kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí Òmùò-òkè ló bá ìpínlẹ̀ Kogí pààlà. Bákan náà ni àwọn ènìyàn Òmùò-òkè máa ń sọ olórí ẹ̀ka èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ni pàápàá àwọn tó mọ̀ọ̀kọ̀-mọ̀ọ́kà.

1.2. ÌTÀN ÌSẸ̀DÁLẸ̀ ÒMÙÒ ÒKÈ

Ìtàn àgbọ́sọ ni ó rọ̀ mọ́ ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀ ìlú Òmùò-òkè gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ni àwọn ilẹ̀ Yorùbá káàkiri. Ilé-Ifẹ̀ ni orírun gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí ní Òmùò-òkè. Olúmoyà pinnu láti sá kúró ni Ifẹ̀ nítorí kò faramọ́ ìyà ti wọn fi ń jẹ́ ẹ́ ni Ifẹ̀. Kí ó tó kúró ni Ilé-Ifẹ̀, ó lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Ifá. Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe yìí fihàn wí pé yóò rí àwọn àmì mẹ́ta pàtàkì kan ni ibi ti ó máa tẹ̀dó sí. Ibi tí ó ti rí àwọn àmì mẹ́ta yìí ni kí ó tẹ̀dó síbẹ̀. Àwọn àmì àmì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni

a. ibi tí erin fi ẹsẹ̀ tẹ̀

b. igbó ńlá

c. Odò

Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rìn títítí ni ó wà dé ibi ti ifá ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un. Nígbà ti ó rí odò, ó kígba pé “Omi o” ibi ni orúkọ ìlú náà “Òmùwò” ti jáde. Òmùwò yìí ni ó di Òmùò-òkè títí di òní. Olúmoyà rìn síwájú díẹ̀ kúró níbí odó yìí pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó dé ibìkan, ibi yìí ni òun àti àwọn tí ó ń tẹ̀le kọ́ ilé si. Ibi ti ó kọ́ ilé sí yìí ni ó pè ni “Ìlẹ́mọ” Orúkọ ilé yìí “Ìlẹ́mọ” wà ni Òmùò òkè títí di òní. Olúmoyà gbọ́rọ̀ sí ifá lẹ́nu, ó sọ odò náà ni “Odò-Igbó” àti ibi ti ó ti rí ẹsẹ̀ erin ni “Erínjó” Akíkanjú àti alágbára ọkùnrin ni Olúmoyà ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ. ó kọ ilẹ òrìṣà kan tí ó pè orúkọ òrìṣà yìí ni “Ipara ẹ̀rà”. Ibi yìí ni wọn ti máa ń jáwé oyè lé ọba ìlú náà. Báyìí ni Olúmoyà di olómùwò àkọ́kọ́ ti ìlú Òmùwò tí a mọ̀ sí Òmùò-òkè ní òní.