Jump to content

Oníṣe:Shuga

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Shuga, tí a tún pé ní MTV Shuga, jẹ́ eré tẹlifíṣọ̀nù kan tí a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní Oṣù Kọkànlá ọdún 2009 lórí MTV Base gẹ́gẹ́bí apákan ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a pè ní "MTV Staying Alive Ignite!". Àwọn apá méjì àkọ́kọ́ rẹ̀ ni aṣẹ nípasẹ̀ MTV Networks Africa pẹ̀lú àjọṣepò The MTV Staying Alive Foundation, PEPFAR (The US President's Emergency Fund for Aids Relief),tí ó jẹ́ Àjọṣepọ́ fún Ìran kan tí kò ní HIV (HFG) àti Ìjọba ti Kenya, gẹ́gẹ́ bi ara ìpolongo multimedia láti tan ìmò nípa ìhùwàsí ìbálópọ́ àti ìfaradà . Lẹhinna ó di olókìkí tí ó tú tà ní àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà 40 oriṣiriṣi ṣáájú kí wón tò tá káríayé ní àwọn ibùdó tẹlifíṣọ̀nù 70 pẹ̀lú. Àwọn àgbà Kenyarrò pé ó jẹ́ ère aláríyànjiyàn púpọ̀ nítoríoó ní àwọn ìran nítoríoó ní àwọn ìran ìbálòpọ̀ tí kò yẹ ní gbangba. Ó gba Ẹ̀bùn wúrà kan ní Oṣù Kàrún ọdún 2010 ní World Media Festival ní Hamburg, Germany ní ẹ̀yà Ìlera fún ìdojúkọ rẹ̀ lórí ìfẹ́, àwọn ẹ̀dùn àti ìhùwàsí ìbálòpọ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ Kenya.