Opele

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọ̀pẹ̀lẹ̀ (pípè rẹ̀ OPUELE tàbí OCUELE ní Látìnì-Amẹ́ríkà) ni okùn ìṣàyẹ̀wò tí wọ́n ń lò nínú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Adúláwọ̀ àti àwọn Akátá-Amẹ́ríkà, pàápàá jùlọ nínú Ifá àti ìsẹ̀ṣe Yorùbá. Babaláwo (oníyẹ̀míwò) máa ń lo ọ̀pẹ̀lẹ̀ láti lè sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú òòṣà ọgbọ́n/ìmọ̀ (Ọ̀rúnmìlà) nínú ìsẹ̀ṣe Yorùbá ẹni tí ó lè ṣe àfihàn okùnfà àti ojútùú sí ìsòri àdáni àti gbogbogbòòtí yóò sì fi mú ìrọ̀rùn padà wá sí ayé onítọ̀hún nípa títún ìpín àti/tàbí orí (òòṣà ẹnikọ̀ọ̀kan) ẹni ṣe. Ọ̀pẹ̀lẹ̀ jẹ́ ohun èlò àyẹ̀wo kékeré tí àwọn babaláwo ń lò; wọ́n gbàgbọ́ pé "olùrànlọ́wọ́" tàbí "ẹrú" Ọ̀rúnmìlà ni, ẹni tí ń ṣe alágbàsọ ìfẹ́ Ọ̀rúnmílà fún babaláwo tí ó sì tún ń mú láti ọ̀dọ̀ babaláwo padà fún Ọ̀rúnmìlà. Wọ́n máa ń lò ó fún púpọ̀ nínú àyẹ̀wò ojoojúmọ́. Fún àyẹ̀wò tí ó bá jẹmọ́ àyẹ̀wò ohun pàtàkì míràn tàbí ohun pàtàkì ọjọ́ iwájú nípa olùsàyẹ̀wò tàbí fún ìpinnu pàtàkì, babaláwo yóò lo ikin Ifá, èyí tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ olùrọ́pò Ọ̀rúnmìlà.