Orúkọ Ìnagijẹ
Orúkọ Ìnagijẹ tàbí àlàjẹ́ jẹ́ èyí tí kì í ṣe orúkọ tí òbí ọmọ sọ ọmọ rẹ̀ lọ́jọ́ ìkómọjáde. Yorùbá gbà pé orúkọ á máa ro ni, ìdí nìyí tí àwọn Yòrùbá ò kì í sọ ọmọ lórúkọ tí wọ́n bá rí. Bí ènìyàn bá sọ ọmọ rẹ̀ ní Ìbíkúnlé, àwọn ènìyàn á máa ṣàdúrà pe "Kí Ọlọ́run jẹ́ kí ọmọ tó olórúkọ rẹ̀". Nítorí pé akọni Ìbàdàn ni Ibikunle yìí jẹ́ nígbà ayé rẹ̀. Àpẹẹrẹ àwọn orúkọ Ìnagijẹ rẹ̀ ni Ògèdèǹgbé àti Gbógungbórò. Láti inú orúkọ tí a bá sọ ọmọ ni ìnagijẹ rẹ̀ á ti jáde. Ọmọ á máa ní ìnagijẹ nítorí pé ẹni tí ó ti kọ́kọ́ jẹ́ orúkọ náà rí já sí akíkanjú, olówó, olókìkí, alágbára tàbí onínúrere, afínjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Orúkọ ìnagijẹ á sì máa hàn ju orúkọ gidi lọ. Nígbà mìíràn, ẹlòmíràn kò tilẹ̀ ní mọ̀ pé àlàjẹ́ ni òun ń lò bí i orúkọ.
Àpẹẹrẹ àwọn orúkọ Ìnagijẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Aróbíodu Àdùbí Ajíríbi Eléètú Ìdíìlẹ̀kẹ̀ Ládùbọ Olódòdó