Orimolade

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

'''Mósè Orímọládé Túnọlàṣe''' (1875–1933) jẹ́ olùdásílẹ̀ ìjọ ẹ̀mí àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Áfíríkà, ó ṣàgbékalẹ̀ ìjọ́ mímọ́ ayérayé ti sérúfù àti séráfù ní ọdún 1925. Ìjọ yìí jáde láti ara ìjọ àpéjọpọ̀ àwọn áńgẹ́lì ní ilè Yorùbá ní ìlà Òòrùn Áfíríkà.

Ìtàn Ìgbésé-ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Mósè Orímọládé Túnọlàṣe sínú ìdílé ọba Ayíbírí ní ìlú Okorun ní Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Òǹdó ní ọdún 1879. Mósè ò lè dìde dúró tàbí rìn títí ó fi pé ọmọ ọdún márùn-ún. Lára ìgbìyànjú láti lẹ̀ mú ìmúláradá bá ní ó ṣokùnfà bí bàbá ẹ̀ ṣe gbe de ìjọ ọ̀run ti St. Stephen, èyí tí ó wà ní ìlú Ìkàré lábẹ́ ìjọba ìwọ̀ Òòrùn lásìkò ìgbà náà. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn òbí rẹ̀ máa fi í lẹ̀ pẹ̀lú olùṣọ́ àgùntàn ìjọ náà, tí Mósè yóò sì sọ àwọn onírúurú iṣẹ́ ìyanu tí ó ti ṣẹlẹ̀ láyé rẹ̀ láti ojú ààlà fún àwọn òbí rẹ̀ bí wọ́n bá ríra.

Orímọládé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere ní ìlú tí a ti gbé bí (Ìkàré), làì kẹ́kọ̀ọ́ ìwé, àwọn tí ó sì máa ń wàásù fún ni àwọn oníṣẹ̀ṣe.

Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

. A. Omojuwa, Iwe Itan Igbesi aiye Moses Orimolade Tunolase, n.d., pp. 16- 17.