Orin
Ìrísí
Orin ni a lè pè ní ẹ̀hun ọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó fani mọ́ra, atòpọ̀ àwọn Ìlú àti agogo ní ìbámu pẹ̀lú ìwọ́hùn tí a fẹ́ fi kọọ́ jáde. [1][2][3] Orin jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ tí ó sì gbajúmọ̀ láàrín gbogbo ẹ̀yà ènìyàn lágbàáyé.[4] [5] Lóòtọ́, kòsí oríkì kan tó gúnmọ́ fún orin láàrín àwọn onímọ̀ nipa orin, ṣùgbọ́n wọ́n gbà wípé ọ̀nà kan pàtàkì tí ọmọ ènìyàn ń gbà láti gbé èrò, àti ẹ̀bùn àdámọ́ àtinúdá wọn jáde ni orin jẹ́ [6]. Àw9n àgbékalẹ̀ ìgbésẹ̀ ni ó wà ní fún orin kíkọ, lára rẹ̀ ni: orin híhun tabí ẹ̀hun orin àti kíkọ orin gan an.[7] A lè kọ orin tàbí ṣeré ìta-gbangba pẹ̀lú lílo àwọn Ìlú tí yóò mú orin dùn létí nígbà tí ònkọrin bá ń lé orin rẹ̀ sílẹ̀ẹ̀ láwaawẹ́.
Àwọn ìtaọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ OED, § 1.
- ↑ AHD, § 1.
- ↑ Epperson 2022, § para. 1.
- ↑ Morley 2013, p. 5.
- ↑ Mithen 2005, pp. 26–27.
- ↑ Gardner 1983, p. 104.
- ↑ Nettl 2001, §III "3. Music among the arts".