Orin Ìdárayá
Orin Ìdárayá jẹ́ orin kan tí àwọn Yorùbá máa ń kọ́ ọmọdé nígbà èwe, orin yìí a máa kún fún ọgbọ́n, òye, ìkìlọ̀, ìmọ̀ràn, ẹ̀kọ́, ìwà ọmọlúwàbí, abbl. Àwọn ọmọdé a máa kó ara jọ láti kọ orin yìí nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á wo díẹ̀ nínú àwọn orin tí àwọn ọmọdé sáábà má ń ṣe àmúlò.
Orin ọmọdé kan
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]ọmọ kékeré kan
ń kọjá lọ́jà
ó ń wọ̀tún wòsì
bí ẹni máa fò
ẹnìkan béèrè pé
kí ló ń ṣe ọ́
tó ń wọ̀tún wòsì
bí ẹni máa fò
ẹ jẹ́ ká jọ ṣe eré
eré ayọ̀, eré ire
eré ayọ̀, ráí títì ráí ráí ràì.
Orin oge ṣíṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ma jí ma wẹ̀ ma ṣoge
má jí ma wẹ̀ ma ṣoge
Àwẹ̀ró, èmi Akáwẹ̀ró ma wẹ̀tán
ọmọkùnrin ò leè lọ o
má jí ma wẹ̀ ma ṣoge.
Orin tó fi ìwà ọmọlúàbí hàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]ṣe mí l'ọ́mọ rere bí Sámúẹ́lì
ọmọ tó ń gbọ́ràn
tó ní ìtẹríba
ọmọ tí kì í bá òbí rẹ̀ jiyàn
ni kí O ṣemi Olúwa
ìwọ ńkọ́?
Ìyá ni wúrà iyebíye
tí a kò le f'owó rà
ó lóyún mi fún oṣù mẹ́sàn-án
ó pọ̀n mí f'ọ́dún mẹ́ta
ìyá ni wúrà iyebíye
tí a kò le f'owó rà.