Orin apala

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ORIN ÀPÀLÀ

Bí irun ṣe súnmọ́ orí ní orin sí àwùjọ Yorùbá, pẹ́kí-pẹ́kí ni wọ́n súnmọ́ ara wọn. Yorùbá fẹ́ràn orin púpọ̀ tó fí jásí pe kò sí ìgbà, àkókò tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí Yorùbá kò lè ti kọrin àyààfi ìgbà tí wọ́n bá ń sùn tàbí tí wọ́n bá ń jẹ́un. Bi Yorùbá ṣe fẹ́ràn orin tó yìí, a rí pé orin wọn kò dúró sí ojú kan, bí ìdàgbàsókè ṣe ń bá àwùjọ wọn náà ni ìyípadà ń dé bá orin Yorùbá. Ní ìgbà kan rí, àwọn orin bíi rárà, olele, obitun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni Yorùbá ń lò fún ìdárayá kí ọpọ́n tó sún kan orin àpàlà tí a ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀ yìí, ìgbà tí ó yá ni ayé tún sún kan juju. Lẹ́yìn èyí ni fújì kí ó tó wà kan tàkasúfèé tí ayé ń jó lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Gbogbo èyí fi hàn pé orin Yorùbá kò dúró sí ojú kan. Lóòótọ́ a kò leè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé àwọn orin tí a dárúkọ wọ̀nyí ti di ohun ìgbàgbé ṣùgbọ́n ayé kò gbọ́ wọ́n bí i ti tẹ́lẹ̀ mọ́, kí ọ̀rọ̀ àwọn orin yìí má baà di àfìṣẹ́yìn tí eégún fiṣọ ni mo fi yàn láti sọ̀rọ̀ lórí orin àpàlà.

Orin àpàlà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin Yorùbá ti wọ́n jẹ́ gbájúmọ̀ ni agbègbè ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Ọ̀yọ̀, Ọ̀sun àti Ìgbóminà. Orin ayẹyẹ ni orin àpàlà, orin ìgbàlóde ni pẹ̀lú. Orin àpàlà kò ní nǹkan án se pẹ̀lú ẹ̀sìn, òrìsà tàbí ìbọ kan tí a mọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá. Orin ìgbàfẹ́ ni orin àpàlà....

Olóògbé Haruna Iṣọla ni a gbà pé ó dá orin àpàlà sílẹ̀, àjogúnbá sì ni isẹ́ orin jẹ́ fún-un nítorí pé àwọn Baba baba rẹ̀ ti ń kọrin tẹ́lẹ̀. Olórin ní Bello tíì ṣe baba Haruna Ishola gan an bẹ́ẹ̀ olórin ní Egungunjọbi tíí ṣe Bàbá Bello náà sùgbọ́n orin tí wọ́n ń kọ nígbà náà kìí ṣe Àpàlà, Sẹnwẹlẹ ni orúkọ tí wọ́n pe orin tiwọn nígbà náà, àwọn kìí sì lu ìlù sí orin tiwọn, àdákọ orin lásán ni, kí olóògbé Haruna Ishola tó bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù sí orin tirẹ̀ èyí tí ó di orin Àpàlà yìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyapa ẹnu pọ̀ lórí èyí, síbẹ̀ ipa Olóògbé Haruna Iṣọla lórí bí orin àpàlà ṣe bẹ̀rẹ̀ kò mọ níwọ̀n.

Àwọn mìíran tó tún kọrin àpàlà ni Olóògbé Ayinla ọmọwura, Adegeto, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.


fún ẹ̀kúnrẹ́ré̩ àlàyé lórí orin àpàlà, pe ÀÀRẸ OKIKI 08109204112/08128827372