Jump to content

Orin-ìyìn orílẹ̀-èdè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Orin orile-ede)

Èyí ni orin tí orílẹ̀-ède kan máa ń kọ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ. Wọ́n máa ń kọ ọ́ tí olórí orílẹ̀-èdè mìíràn bá wá bẹ̀ wọ́n wò. Wọ́n máa ń kọ ọ́ níbi tí àwọn ènìyàn bá pé jọ sí tàbí ibi òṣèlú tó bá ṣe pàtàkì. Ẹnìkan lè dá a kọ fún gbogbo ènìyàn tàbí kí gbogbo ènìyàn kópa nínu kíkọ rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ inú orin yìí máa ń yin orílẹ̀-èdè àti àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀. Orin yìí máa n sábàá sọ àwọn ohun ribiribi tí ilẹ̀ kan ti gbé ṣe. Bouget de I’Isle ni ó kọ orin ti ilẹ̀ Faranse ní àsìkò ogun ní 1792. Francis Scott Key ni o kọ ti ilẹ̀ Àmẹ́rìkà ní 1814. A kò mọ ẹni tí ó kọ ‘God save the Queen’ ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣùgbọ́n 1745 ni wọ́n kọ́kọ́ kọ ọ́. ‘Arise, O Compatriots’ ni ó bẹ̀rẹ̀ orin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí a ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.