Orílẹ̀-edeé Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìtumọ̀ àwọn Orúkọ Àdúgbò

1 ÌJÈBÚ-RÉMO[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ADÚGBÒ [Ìkénné]

  1. Ìtunmò: Koríko ìkólé ti a ń pè ní ìken nì èdè Rémo ni ó wópò púpò ní agbegbe kan nì ayé ojoún. Nìgbà ti ó wà dì wí pé awoòn ènìyàn ń gbé agbègbè yìí bí ìlú ni won bá n so wí pé a tun ni ni ikèn néè o. èyí ti a wa se ìsúnkì gbólohùn náà sí ìkènné.


[Sònyìndo]

  1. Ìtunmò: Òkunrìn jagunjagun kan ni àdúgbò yìí ni ó ka ení rè kan mo ibi ti ó tí n kínrin aya re ken leyin nigbati aránbìnrin náà ń wè ní ile iwe. Inu bi okunrin yìí pàápàá nitori pe erúbinrin náà kò sá nìgbà ti é rí ì. Èyí mu kì ó bínu pa ìyàwó rè àti erúbìnrin náà Nìgbà ti won sì bì í ìdí ti ó fi se béè o sàlàyé pé ń se ni erú yìí sànyín-dó. Lati ìgbà náà ni a ti ń pe adugbo ohun ní sànyìndó.

[Ajíno]

  1. Ìtunmò: Nì ayé àtijó, òwúrò kùtùkùtù ni won máa ń ná ojà agbègbè kan báyìí ni ìlè Remo. Kèrèkèrè, awon ènìyàn bèrè sí ìlé ní í ko sí ibi ofà yii, wón sì ń gbé ibe. Bayìí ni won se so ojà náà ní Ajino ti àwon ènìyàn sì so adugbo náà nì Ajìwo titi di ìsìnsìnyí.


[Ìmóbìdo]

  1. Ìtunmò: Agbègbè ti a fi igi Obì pààlà tàbí sàmì sí. Àwon méjì ti ó ń jà du ààlà ilè ni o fa orúko yìí jáde nítorí awon tì ó nì ìlè salàyé wí pé ìgi obì ni àwon fì dó: ìlè àwon láti fi se idámo sí ilè elòmìíràn.

[Ìdótun]

  1. Ìtunmò: Ní asìko ogun ti awon Yorùbá ń ti ibi kan dé ibì kan ni àwon kan ko ara won jò láti te ìlú tìtun dó. Léyin ti awon ènìyàn ti n pò níbe ni wòn wa so ìbùdó won yìí ní ‘Ìdótùn’ èyí ti ó túmò sí ibùdó tìtun.

[Ìdómolè]

  1. Ìtunmò: Nítorí àgbára àti ìwa ìpàǹle tàbí ìwà jàgídíjàgan okunrin kan báyìí ti a pe orùko rè ní Ìdó ni àsìkò Ojoun ni a se so oruko adugbo yìí ní Ìdómolè léyìn ikù okunrin yìí ni awon ènìyàn bérè sì fi okunrin yìí júwè adúgbò ré. Won a ní awon n lo sí Ìdó akínkayú nì tàbí okùnrin imolè nì. Báyìí ni a kuku so adúgbà di Ìdómolè.

[Ìròlù]

  1. Ìtunmò: Léyìn ìgbà ti awon Yorùbá ken ti gbà latí parapò máa gbe pèlu ìrépò ni agbègbè kémo, yìí ni won kùkú wá pè è ní Ìrolù. Èyí túmo sì pé awon jo kò ó lù ni kí àwón tó ‘péjo síbè.

[Sáàpàdé]

  1. Ìtunmò: Àwon ìlu méta ni ó parapò sí ojú kan. Nígbà tí ó wà di wì pé okan kò yòǹda oruko tirè oún èkèjì ni wón wà yo nínú oruko awon meteeta; làti yo sàaàpàde

Ìsarà – láti ibi ni wón ti yo ‘sá’ Ìparà – láti ibi ni wón ti yo oá’ Odè – láti ibi ni wón ti yo dé’ Àpaofò sá- pà-dé ni ó wá di sápadè.

[Ìsarà]

  1. Ìtunmò: Òde nì awon tí ó parapò te ìlú ìsara dó. Kaluku awon ènìyàn wònyi ni won sì wá láti agbègbè òtòòtó. Nígbà ti ó wá dì wí pè ènìkan fé so ara re di olorí ‘àpàpàndodo ni won bá làá yée pe n se nì awon sa ara awon jo sibe! Ti won sì ‘sun orúkò náà kì di Isarà.


[Ògèrè]

  1. Ìtunmò: Áwon tí ó ń gbé òkèèrè ni won ti kèrèkèrè só dì ògèrè. Láyé àtijó bì ó bà ti dì wí pé awon ènìyàn Remo bà fé lo sí ibi ti awon are ‘Ògèrè wá won a so wí pè awon fe ló sí agbègbè awon ara òkèèrè. Awon ènìyàn wònyí búrú púpò jù, won sì taari won sìwaju. Won á ni Okeere ni ó ye won. Nígbà ti ójú ń là nì wón bà so oruko ìlú yìí di Ògèrè.

[Ajítaádùn]

  1. Ìtunmò: Ìyá kan wà tí ó ń gbe àdúgbò yìí ni ayé ojoun. Kó sì ìgbà ti àwon ènìyàn dé òdò rè tí kìí ni oúnje àdi`dùn. Nìgbà ti ò dì wí pe gbogbo ènìyàn bere si fi ounje ìyà yìí júwè adúgbò naa ni wòn kúkú wa n pe adugbo yìí ní Ajítáádùn (Ají-ta-dídùn).


ABEOKUTA[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ADÚGBÒ [Ìlúgùn] Ìtunmò: Ni ìgbà láéláé, ìtàn so fún wa pé omo kan sonù tí kiri títí, léyìn tí wón ti wáa kiri títí ni wón ríini ìlú ken tí ó jìnà. Nítorí pé ibi tí wón ti rí omo náà jìnà, ni wón se ń pè ní ìlúgùn.

[Àgó Òkò]: Òkúta ni wón ń pè ní òkò nì èka èdè ègbá. Ní ìgbà ogun, awon ará àdúgbò yìí ko ni ohun elo ìjà kankan ayàfi òkúta. Òkò ni wón má a ń so fún àwon ota won. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wòn ní Àgó Òkò

Ojà Àgbò: Eran àgbò ni wón ń tà níbè kí ó tó di ìbi tí awon ènìyàn ń gbé

Ìtokò: Adágbà je omo ìrówò ìbàràpá òun ní ó kókó dé Abéòkúta, Ogun lé won dé orí dímo (Àwon ìbàràpá) wón bá Adágbà tí ó ń se isé ode ní orí olúmo. Adágbà fi àwon ìbàràpá tí ogun lé dé ori olúmo yìí sí ìdi igi ìto kan. Àwon náà bèrè sí í se ode. Ní ojó kan wón ro oko yí ìdi igi ìto yìí ká, wón gbá pàǹtí sí abé igí ìto yìí, wón fi iná sí i. Nígbà tí Adágbà rí i, ó pariwo lé won lórì pé: Ah! Èyin ènìyàn yìí ìto le kò (Kò túmò sí kí á pa igi). Bí a se rí ìtokò nì yí. Ìjemò: Ìjemò túmò sí Àjumò. Ohun tí a fìjo mò nípa rè

Kémta: Kémta tumo sì kèeta, Àsòjóró, òtè. Wón máa ń se keèta ara won ìdí èyí ni wón fi ń pe wòn ni kémta.

Ìjeùn: Ìtumo re ni “èjì ohùn” áwon olórò méjì héun

Àgó òwu: Àwon ará àdúgbò yìí jé àwon tí ó ń jowú, owú jíje won ló mú won sokún gba adé àwon omo ìkijà. Ìdí nìyí tí wón se ń ki won pé “Ara òwu, omo asunkún gbadé

Arégbà: Àdúgbò tí àwon ìbàràpá tèdó sí. Nígbà tí wón dífá pé kí wón mú Ègbá wá. Wón ní ati-re-gbà ó. Bí ó se dí arégbà nìyí.

Kúgbà: Ikú-gba-èyí. Odò ńlá kan tí ó gbé omo lo ní Arégbà ní àwon ènìyàn ìgbà náà fi ń so pé íkú gba èyí lówó wa. Kúgbà.

Òkè Èfòn: Àwon ará Efòn Alàyè láti ìpínlè Òǹdó ni wón ń gbé àdúgbò yìí. ìdí nìyí tí a fi ń pè àdúgbò náà ní òkè èfòn.

Àdátán: Ogun àti oko ríro, léyìn tí wón tí ja ogun tán, wón fé roko àyíká àdúgbò náà ní a so fún òkunrìn kan pé kí ó lo mú Àdá láti fi sisé wá. Òle ènìyàn nì okùnrin yìí, ó dáhún, ó ní Àdá ti tán. Bayìí ni a se ń pe ibè ní Àdátá.

Sábó: Sábó wá láti inú Sábánímó. Àdúgbò tí àwon Hausa tèdó si ni. Òrò yìí kì í se òrò Yorùbá tàbí ti Ègbá.

Odédá: Àdúgbò tí àwon ode má a ń fàbò sí lèyìn tí wón bá ti sode lo tán ni ibè ní won yóò péjo sí tí won yóò sì dá àwon eran tí wón bá pa jo sí ibè.

Òkè Agbède: Àdúgbò yìí ni àwon ìbàdàn tí wón wá sí Abéòkúta tèdó sí ní igbà tí wón wòlú Egbá. Won kò gba ará ìlú mìíràn móra níbè àfi omo ìbàdàn.

Àgó Ìjèsà: Àdúgbò àti ìbìdó àwon ará ilésà nínú ìlú ègbá

Ìsàle Jagun: Ìsàlè (AJAGUN) – Àdúgbò tí wón ti ń ja ogun ní ìlú Ègbá ní ìgbà àtijo. Kòtò wà ní ibè nì wón fi ń pè é ní ìsàlè jagun.

Àgó Tápà: Ibùdó àwon Tápà nígbà tí wón dé sí Ègbá

Eléwéran: Ewé iran tí a fi ń pón èbà tàbí àmàlà ní o hù àyíká yìí ni ìgbà tó tip é láé. Ibè nì àgó olópàá wà ní Abéòkúta.

Àdúgbò: Panséké Ìtumò: Igì ken wa ti èso rè máa ń dún bì ìgbà ti ènìyàn bá ń mi beere. Ibì tì igi yìí wà gan-an ní gbogbo ènìyàn si máa n lo lati mú u fún lìlò ni awón ara ìlú fún ni orúko ti ó jò mo dídún tie so inu rè màa ń dun. – Pasiséké Adúgbò: Mókóla Ìtùmò: Àwon ará Òkè-Ìdó ni Abéòkúta nìkan ni ó mo awo ti ó wà nínú àgbùdo gbíngbìn. Odò won sì ni gbogbo awon ènìyàn ti máa ǹ ra àgbàdo. Nítorí ìyànje yìí nì Oba Aláké se fun Olórí àdúgbò yìí ni Omobìnrin re kan lati fi se aya. Obinrin yìí ni o ridìí àsiri ìkòkò yìí tì ó sì sàlàyé fún awon ènìyàn rè. Ibì ti arabinrin yìí wà pàdà nì Oko si ni a fùn ni orunko yìí. Mókólà – Omo ko olá wá sílé.

Adúgbò: Fàjé Ìtùmò: Iyá ken ni ò ń dààmú awon ara àdùgbò ìbi ti ó n gbé. Nìgba ti idààmú yìí wá pòju tí awon ènìyàn si mú ejo rè to Oba lo ni ìyá yìí wá sàlàyé wì pé lóòótò ni òún jé àjé ati wì pé ení ti ó bat ó òun ni òún ń da sèrìyà oún. Kábiyèbi bà so pé àsàjemátèe ni obìnrin yìí o. Bi wòn se ń fi ìyá yìí fúwe àdùgbò tì ó ń gbé nìyèn. Won a ní àwón ń lo sí sàje:

Adúgbò: Quarry Ìtùmò: Àdugbò yìí ni awon òyìnbó tédò sí làtí máa fo òkútà si wéwé oún ilé kíko tàbi òná sise. Awon Òyìnbó yìí ni wón n pè ni Òyìnbó Quarry nítori Orúko òyìnbo ti ó koko gbé àdùgbò yen. Won ní àwon ń lo sí agbègbè Qùarry.

Adúgbò: Àgo Òwu Ìtùmò: Ní àsìkò Ogun nígbà ti ogun tú awon ènìyàn Owu ti onìkàlùkù won sì fónká. Awon ti ó tédó sí àdúgbò yìí ni o kúkú fé se ìdámò ara won si awon Ègbà yookù. Ìdí nìyìí ti won fí so Ibùdó won nì Àgó Òwù Àgò ti a tì ilè rí awon ara Owù

Adúgbò: Ita-eko Ìtùmò: Ní àtijó àdúgbò kookan ni ó ní ise ìdamo won. ‘Sùgbón nì tí awon ara àdúgbò yìí eko nì gbogbo awaon obìnrin won màá ń tà. Bí ó bà sì dì ale gbogbo won a pate eko won sì ojú kan. Bì a bá wà rí ení ti o bá fe lo sí ojúde yìí onítòhùn yòó sò pé òun lo si Ìtà-eko. Orúko yìí nì ò sì mo àdúgbò náà lòrí dì onì yìí ni pàtàkí fún ìdamò ìta-eko ojóun.


Adúgbò: Ita Ìyálòde. Ìtùmò: Akínkanjú obinrin kan wa ni Ègbá ni ayé ojóun. Efúnróyè Tínubú nì orúko rè. ‘Nítorí ibe ìdàgbàsòkè re sù ìlú Ègbá ni oba Àláké se fí jè Ìjatóde ìlù. Oún ni ìyálódè Ègbá àkòkó. Ibì ti Ìyá yìí wá kólé sí ní àdúgbò rè ni won so di ‘Ita ìyálódè.


Adúgbò: Kútò Ìtùmò: Nì àyé àtíjó àbikú ń da bàbá kan láàmu. Nigbà ti ó dáfá, won ni ki ó fe síwáju bì ó bà ń fé kì àbìkú dúró. Bàbá yìí wá dó sí ìbi ti a mo sí Kútò lónìí. Sùgbon léyìn odún díè omo ti ó bà tún kú nì o bá bérè ariwo pé ikú tun to òun léyìn dé ibí yìí. Báyìí ni awon elégbe rè se ge orúko kéré di`kútò tí ó sì wà dòní yìí

Adúgbò: Ìdí àbà Ìtùmò: Nígbà tì kò tíì sí ònà móto bí àwon ti a ní lònìí yìí àwon ènìyàn ti wón jè yálà ode tàbí àgbè a máa fi adúgbò Ìdí Àbà se ìpàdé won. Igi àbà po ni àdúgbò yìí nìgbà náà. Awon ènìyàn wonyi a sì maa sinmi ni àbe àwon Ìgi yìí yàlà ní àlo tabì ní àbò. Báyìí nì won se kúkú so agbégbè yìí ni Idí àbà. Bì ó file jè pé olàjú ti dé báyìí èyí kò yí oruko adugbo náà páde dì báyìí.

Àdúgbò: Ajítaádùn Itùmò: Ìyá kan wà tí ó ń gbe àdúgbò yìí ni ayé ojoun. Kó sì ìgbà ti àwon ènìyàn dé òdò rè tí kìí ni oúnje àdi`dùn. Nìgbà ti ò dì wí pe gbogbo ènìyàn bere si fi ounje ìyà yìí júwè adúgbò naa ni wòn kúkú wa n pe adugbo yìí ní Ajítáádùn (Ají-ta-dídùn).


ILA[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-Àwòrò-òsé: ìtàn ti a gbo nipa adugbo tabi agbo-ile yì so fun wa pe ilé. Àwòrò-òsé je ibi pàtàkì ti won ti ma n se orò, ò sì tun je ile-Olorisa.

Ìlé-Olúóde: A gbó pe ode ni ìran àwon wònyí n se láti ìgbà ìwásà. Ibe sì nì Olórí àwon ode n gbe.

Ile-Olutojokun: Àwon ìdílé yi ni o ma ń joba ni ìlú-ìlá-òràngún.

Ile-Olorirawo: Adugbo ati Agbo-ile ni eyi je. Ìtan ti a si gbo nipa won núpé ìbè ni Olori awon awo tedo sì.

Ìjímògòdò: Akoni èdá kan ni o je, jagunjagun sin i pelu, oun lo te àdúgbò yì dó.

Ìgbonnìbí: jé òkan nínú àwon oba akíkanjú ti o wolè ni ìlá. Níbi ti o wolè sin i a n pe ni Ìgbonnìbí loni yìí.

Ajagúnlá: Ode ni ajagunle nigba aye re, o si je jagunjagun O si bínú wolè lo ni.

Ògbún Ìperin: Nibi ti a pa Erin sin i a n pe ni ìperin

Òkè-Èdè: túmò si ibi ti a pa elédè si

Ògbún ìsèdó: Eyi tumò si ibi ti isé sodo si. Agbègbè yin i ìlú ma n lo gégé bi ojúbo isé.

Ilé- Olóòsà! A gbo pe wón ma n ko òrìsà pamó sì adugbó yií.

Òkè-Alóyin: Odò kan ti o n san ni àdúgbò yì, wón ma n lo omi yì láti fi se ìmúláradá àwon omo wéwé.

Ilé-Agbérùkóó: A gbó pe ìdílé yì ma n gbe èrúkó tà, ni won fi ma n pé wón ni agbérùkóó.

Ilé-Alápìnni: Ìtàn so pe idile Oloje tabi eleegun ni won je. Àwon sin i Olórí gbogbo àwon eégún.

Ilé-Ìyálóde: Obìnrin ni o te idile yi do, O gbé fáàrí O sit un je akikanju obinrin láàrin ìlú.

Ilé-Akogun: Jagunjagun naa ni o te adugbo yi do Akogun sit un je Oloye pàtàkì ni ìlú

Ilé-Òjá-bèbè: Isé abèbè ni wón yàn láàyò ni àdúgbò yì.

Ìlé-Agbèdègbede: Àwon ìdílé Alágbède ni àwon wonyi n se.

Ilé-Òdú: Èfó òdú ni won ma ngbin ni akoko ti won so orúko ile yii.

Ilé-Ajengbe: Isé Ìsègùn ni won ma n se ni ìdílé yi. Won sit un je akoni èdá kan.

Ilé-Obajisun: Ìdílé oba ni won jé won sì tun je Olóyè ìlú. Èfó òsùn pò púpò nì àdúgbò yìí

Ilé-Onílù: Àwon àyàn ni o te ile yìí do, ìdílé onilu ni àwon wonyi je

Ilé-Awúgbo: àwon ìdílé yi saba ma n gbìn erè kan ti a n pen i awúje, èyítí o ti gbilè ti won fi n pe won lórúko loni.

Ile-Èelemukan : Èkan po ni àdúgbò yìí

Ìle-Obajoko: Idile yin i won ti ma n sábà fi Oba je, eyìti a mo si kingmaker.

Òkè-Ògbún: Nígbàtí ìlú ko ti làjú àdúgbò yin i wón ma sábà ko gbogbo àwon òhun ìdòtí pamó si, o si je ògbun eyìti wòn so di oke-ògbún lòni yì.

Ilé-Àtèéré

Ilé-Àbálágemo:

Ilé-Asóyòò:

Ilé-odogun: Ìdílé àwon jagunjagun ni won.

ÌLÚ PÀMÒ-ISIS[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òkè-Àgó: Gégé bí ìwádìí tí mo se, àdúgbò yìí ni àwon tí ó kókó tèdó sí ìlú yìí dé sí. Láyé ìgbà náà, kò ì tí ì sí ilé-búlókù, àgó ni wón ma ń pa, ibi tí wón rook pàgó sí ni wón wó ń pè ní òkè-àgó ní oorí pé, ó bó sí ibi tí òké wà.

Ilé-Ita: Gégé bí ìtàn se so, ní orí ilè yí nì àwon ará ìlú pàápàá jùlo àwon àgbàgbà lókìnrin ti ma ń ta ayò bí wón bá ti took dé láyé ìgbà náà. Ilè-ìtayò nì wón ń kókó pè é kó tó di wí pé, wón kó ilé síbè gan-gan. Ilè-ìtayò ni ó wá yí padà sí ilé-ìtayò, ìgbà tí ó yá, wón so ó di ilé-ita. Eyí ni, ibi tí a ti ń ta ayò.

Ilé-Okógbà: Àdúgbò yìí gba orúko rè nípa sè Baba kan tí ó fé ràn isé oko púpò. wón ní Bàbá yìí ma ń fi àyíká ilé e rè gbin orisirisi nǹkan lódodún sùgbón wón wí pé, àwon eran òsìn bíi ewúré ma ń yo ó lénu púpò. Nígbà tí ó yá, ó wá bèrè sí ní pa àwon erúré tó bá ti won ú ogbà a rè. Eléyìí ló wá fà á tí ìjà fi wà láàárín òun àti àwon ènìyàn, ni wón bá fim ni orúko wí pé, Baba ológbà. Léhùn tí bàbá yìí kú tán, ni wón bá ń pe àdúgbò ibè ní ilé-Ológbà.

Ìdí-Isin : Gégé bí ìwádìí, won ni igi ńlá kan wa níbè nígbà náà tí a ń pè ní igi-isin. wón wí pé, lábé rè ni wón ti ma ń gba aféfé nítorí pé igi-ńlá ni, wón sì tún ma ń je èso ara rè. Bí ó tilè jé pé, èyìn ìlú ni igi-isin yìí wà, sùgbón ní gbà tí wón kó ilé de ibè, ni wón bá ń pè é ní ìdí-isin

Ilé-Lódò: wón ní àdúgbò yìí jé ibi ilè àkèrò nígbà náà. Odò kékeré kan sì wà níbè nígbà náà tí wón ń pon mu. Orúko Odò yìí ni a ń pè ní Odò-àwéré, Ibí yìí ni àdúgbò yìí tí gba orúko rè.

Ilé- ńlá: Wón wí pé láàti àdúgbò kan tí a ń pè ní ilé-ńlá nilu ilé-ifè ni àwon àdúgbò yìí ti sè wá nípa sè ogun Ìdí nìyìí tí wón fi ń pè é ni ilé-ńlá.

Òkè-Ganmo Àdúgbò yìí gba oríko jè láà ti ìlú kan tí ó wà ní tòsí ìlorin tí a ń pè ní Gunmo. Lati ìlú yìí ni wón ní àwon ènìyàn tó kókó tèdó sí sórí ilè náà o wá. Ìdí nìyìí tí wón fi ń pè é ní àdúgbò ara ganmo títí ó fid i wí pé, wón ń pè rí òkè-Ganmo.

Òkè-Abà Àdúgbò yìí náà jé òkan lára àwon àdúgbò tó tí pé jù nilu yìí. wón wí pé, nígbà tí ìlú kò ì tíì pò rárá, bí ènìyàn dúrói ní àdúgbò yìí, yóó máa wo gbogbo ìlú tókù ketekete, ìdí nìyìí tí wón kúkú fi ń pe ibè ní òkè-abà.

Ilé- alágbè Àdúgbò yìí gba orúko nípasè igi-tòròmogbè tí wón ma ń gbìn sí àyíká ilé ní agbègbè náà. Wón ní àdúgbò á wón ti ń kókó gbin igi yìí ní ìlú yìí náà ni wón so di ilé-alágbè títí di òní yìí.

Ìsàlè-ojà Àdúgbò yìí ni àdúgbò tí ó wa ní ojúde-ojà gan-an tí wón ti ń ná jà di òní-olónú. Àdúgbò yìí kò jìnnà sí ilé-Oba.

Oníbàtá Láyé ojóun, wón ní, Olórí àdúgbò yìí ni wón fi je olórí àwon alubàbá àti igangan ní ìlú yìí. Láàti ìgbà tí wón ti fi je é, ni wón ti ń pè é ní baba-oníbàbá, tí wón sì ń pe ilé e jè ní ilé Baba-oníbàtá. Lati ibí yìí ni wón ti so àdúgbò ibè ní àdúgbò oníbàtá èyí ni àdúgbò ilé Baba oníbàtá.

Olú-ìpo Orúko oyè kan pàtàkì ni orúko àdúgbò yìí. Ìwádìí fihàn wí pé, eni tí ó je oyè yìí nígbà ìkéjì jé akíkanjú ènìyàn tí ó lágbára tí ó sì tún jé ode. Oyè yìí ti di àsómodómo.

Ìlálè Wón wí pé, nígbà kan tí àwon ará ìlú-òbà wá sígun bá àwon ìlú pàmò wón wí pé nígbà tí wón dé lojiji, ni enìkan nínú àwon asájú tàbí olóyè ìlú pàmò bá fowó fa ìlà tàbí fowó la ilè wí pé àwon ará ìlú-òbà kò gbodò kojá ilà yen kí won tó pa dà séhìn sùgbón wón dá ilà náà kojá tí ó sì fa ìjà ńlá. Ibi tí wón ti ja ìjà tí ó wá di ìlálè lónìí.

Aráròmí Ìtàn fi yé wa wí pé, ogun ló lé àwon tí ó tèdó sí àdúgbò yí wá. Nígbà tí wón dé, ìlú pàmò gbà wón láàyè láàti dúró tì wón. Ìdí nì yìí tí wón fi ń pe ibè ní aráròmí.

Tèmíoire Gégé bí ìtàn ti so, eni tí ó kókó tèdó sí àdúgbò yìí wá láàti se àtìpó fún ìgbà díè ni sùgbón nígbà tí ó di wí pé ìwà sè dára, tí ó sì kó àwon ènìyàn móra, ni ó bá kúkú fi ibè se lé. Isé àgbè ni a gbó wí pé ó ma ń se, ó ń gbé ní òdò okùnnn kan kí ó tó di wí pé òun náà kó ilé ara rè. Ibi tí ó wá lo kó ilé ara rè sí ni ó pè ní tí èmí di ise ní ìlú pàmò.

ÌLÚ ÒBÀ-ÌSIN[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-tààrà Àdúgbò yìí ni wón ti kókó kó ilé pèlú búlókù ní ìlú yìí, ilé koríko ni ó pòjù láyé àtijó. Bí àwon ènìyàn bá ti wá ń sòrò, won yóò máa wí pé àwon ń lo sí ilé tààrà, èyí ni ilé-gidi, tí a kù fi koríko kó. Bí àdúgbò yìí se gba orúko nìyí.

Ìsawo Ìtàn fi yé wa wí pé, inú igbó ni àdúgbò yí télè kí ilé tí dé ibè. Igbó yìí ni wón ti ń se awo tàbí ńbo. Wón ma ń pe igbó yìí ni igbó-ìsawo sùgbón nígbà tí wón kó ilé ibè, wón wá ń pe ibè ní àdúgbò ìsawo.

Bàkókò Emi tí ó te àdígbò yìí dú ni wón wí pé, ó wá láàti ilu won tí a ń pè ní òkù lébgbè é òmù-àran. Ìtàn wí pé, àdúgbò yìí ni bàbá yìí pé sí tí ó sì dàgbà kí ó tó kú. Nígbà tí, ó wà láyé, Baboko ni wón ma ń pè é, Léhìn tí ó kú tán, ni wón bá ń pe àdúgbò yìí ní Babuko.

Ìsàlè-Òbà Ìdí tí wón fi ń pe àdúgbò yìí béè ni pé, àdúgbò yìí jé ibi tí kòtò wà, ó sì tún jé wí pé, ó tèdó sí ibi àbáwo ìlú.

Iwó-road: Àdúgbò yìí tèdó sí òpópó-ònà tí ó lo sí ìlú iwó-ìsin. Ìdí nì yìí tèdó sí òpópó-ònà tí ó lo sí ìlú iwó-ìsin. Ìdí nì yìí tí wón fi ń pe àdúgbò yí ní Iwó-road.

Imojì Gégé bí ìwádìí tí mo se, orí-ilè àdúgbò yí ni wón ma ń sin òkú sí láyé àtijo. Orí-ilè yìí kò jìnnà púpò sí àárín ìlú kí ó tó di wí pé, ìlú fè dé ibè, ni wón bá kúkú ń pè é ní àdúgbò imojì.

Odò-ilé Ìdí tí àdúgbò yí fi ń jé béè ni pé, ó wà nítòsí Odò kan tí àwon ará ìlú fi ń foso. Odò yìí kò tóbi púpò, kódà, ó ma ń yaw o àdúgbò yìí ní ìgbà òjò. Ilé-Odò ni wón ma ń pè é télè kí won tó so ó di odò-ilé báyìí.

Òkè-Àgbàá: Àdúgbò yìí wà láàárín gùn-gùn ìlú. Ìtàn wí pé, bí òjù bá ti ń rò, àgbàré òjò yíò kó ìdòtín láàti òkè yìí lo sí ìsàlè-òbà, àwon ará ìsàlè-òbà yóò wá a wí pé, àgbàrá òrè ló kó ìdòtí wá sí àdúgbò àwon. Kò pé púpò, ni wón bá ń pe àwon ará òkè yìí ní awon onílé ìdòtí àgbàrá-òkè. Àgbàrá-òkè yìí ni wón wá fi ń pe àdúgbò yìí kí ó tú di wí pé, ó ń jé òkè-àgbàrá tàbí òkè-àgbàá.

Gbádéyan Kì í se orúko yìí ni àdúgbò yí ń jé télè. Ayédùn ni orúko jè télè sùgbón nígbà tí ó di wí pé, enì kan tí ó tip é lénu isé-oba ní ìpínlè Èkó tí ó jé omo ìlú yìí kú, ni wón bá ń fi orúko rè pe àdúgbò yí nítorí pé, ó jé omo bíbí àdúgbò yí bákan náà. Wón sì gba ìwé-àse rè láàti òdò ìjoba ìbílè won.

Òkè-Òbà: Àdúgbò yí wà ní òpópó-ònà tí ó lo sí ilu owó-kájolà. Ìwádìí kò fi ìdí rè mule. Ìdí tí wón fi ń pè é béè.

Elékùú: Àwon ènìyàn àdúgbò yí wí pé, ní ìgbà kan, tí àwon ènìyàn ma ń sepo, orí ni wón fi ma ń ru eyìn lo sí ìlú pàmò sùgbón nígbà tí ó yá, ìjá wà láàárín àwon ará ìlú méjèjì, ni àwon ará-òbà bá sòfin wípé enikéni nínú àwon Obìnrin kò gbódù lo se epo ní ìlú-pàmò mó. Àwon ará ìlú Òbà gba àwon Ègbìrà láàti bá won gbé ekùú ti won náà. Wón wá ilè sí èhìn odi ìlú, wón sì ń pe ibè ní ilè-ekùú. Sùgbón ní báyìí, wón ti kó ilé yí ni wón wá ń pè ní elékùú sùgbón èyí kò túmò sí wí pé, àwon àdúgbò yí ló ni èkùú náà. Àwon ekùú tí wón gbé nígbà náà wà níbè di ìsisìyí.

Òfé-Àrán Ìwádìí kù fi ìdírè mule pàtó bí àdúgbò yí se jé sùgbón àrí-gbámú ìtàn kan ni wí pé, àwon àdúgbò yí jé Ìbátan kan ni wí pé, àwon àdúgbò yí jé ìbátan kan ní ìlú òmù-Àrán nitorí pé, àdúgbò ń jé òfé-àrán.

Eésabà: Gégé bí ìtàn, oye ti won n je ní àdúgbò yí ni a ń pè ní eésabà. Ìdí nì yí tí wón fi ń pe ibè ní àdúgbò Eésabà .

Agbo ilé-Òbà: Gégé bí ìtàn, agbo ilé kan soso ni ó ma ń je oba ní ìlú yìí. Orúko tí àdúgbò yìí ń jé télè ni òkè-ìsolà, ìran won lú ma ń joba ni ìlú yìí kí ó tó di wí pé, ó di agbo ilé-jagboolé báyìí sùgbón nítorí pé àwon ìran òkè-ìsolà ti je é fún òpòlopò odún séhìn, ní àkókò tí wón ń je é yìí, ni wón ti ń pè wón ní agbo ilé-oba. Orúko yìí kò sì yí padà títí di òní yìí bí ó tilè jé wí pé, kì í se àwon nìkan ló ń joba báyìí.

Òkè-Ìdèra: Gégé bí ìtàn ìsèdálè àdúgbò yìí, àdúgbò imojì ni àwon wònyí ti wá. Wón wí pé, enì kan tí ó so wí pé, òun kò le kó ilé sí ibi tí wón ń sin òkú sí ni ó sí kúrò ní àdúgbò imojì lo sí ibòmíràn tí ó sì pe ibè ní ibè ní ibi-ìdèra fún òun. Láàti ibi-ìdèra ni wón ti so ibè di òkè-ìdèra. Omo àdúgbò imojì ni àwon ará òkè-Ìdèra jé.

IJÈBÚ IGBÓ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdúgbò: Òkè Àgbìgbò – Òkè Àgbò Ìtumò: Ní ayé atijo, àdúgbò yìí wà nínú igbó kìjikìji, àwon eye àgbìgbò ni o sì pò si ibè. Àwon eye wònyí a máa fò káàkiri orí igi t’osan t’òru, bákan náà ni òkè pò sí àdúgbò ti a ń so nipa rè yìí. Ní ìgbà tì o se, àwon ènìyàn bèrè sì tèdó sí àdúgbò yìí, wón ń kó ilé mole síbè àwon eye wònyí kò fi àdúgbò náà sílè. Obinrin kan lára àwon ti ó kókó te ìlú náà dó ti orúko rè ń jé “Bèje” akíkanjú obìnrin ni, òun ni ó pa àwon eye àgbìgbò náà run. Wón sì so àdúgbò náà di oke àgbìgbò, ti wón wá ń pè ni “Òkè Àgbò” ni òde òní. Won sì máa ń ki àwon omo àdúgbò náà báyìí; “Omo òkè àgbò Bèje” ìdí ni wí pé Òun (Bèje) ni o pa gbogbo àwon eye àgbìgbò náà run