Ositiro-Esiatiiki

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Ositiro-Esiatiiki

Austro-Asiatic

Àwon èdè tí ó wà nínú ebí èdè yìí tó àádósàn-án. Àwon tí ó ń so wón tó mílíònù márùndínlógórin. Gúsù ìlà-oòrùn Asia ní pàtàkì ní China àti Indonesia ni wón ti ń so wón jù. Àwon kan sì tún ń so wón ní apá ìwò-oòrùn àríwá India àti ní Erékùsù Nicobar (Nicobar Island). Àwon èyà méta ebí èdè yìí tí ó se pàtàkì ni Mon-Khmer (tí ó jé pé nínú rè ni àwon èdè pò sí jù), Munda àti nicobarese. Àwon méjèèjì tó gbèyìn yìí ni wón ń so ní ìwò-oòrùn àdúgbò Mon-khmer. Láti fi ìmò èdá èdè pín àwon èdè yìí sòro díè nítorí pé díè nínú àwon èdè yìí ni ó ní àkosílè àti pé ìbásepò tí ó wà ní àárín àwon ebí èdè yìí àti àwon ebí èdè mìíràn kò yé èèyàn tó.