Ovy's Voice

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Ovy's Voice (Ohun Ovy) je fiimu ti a gbe jade ni odun 2017 ni orile-ede Naijiria, fiimu na je ere itage ti o da lori oro ife. Biodun Stephen ni o ko itan naa ti o si gbe jade. Oludari fiimu naa ni Dimeji Ajibola. Fiimu naa so nipa asaraloso kan ti o ya odi, ti o wa ni ife si omo onibara re kan. O si tun fi idi re mu'le bi ona ti a gba to o dagba se ni'pa lori ibasepo re pelu awon eniyan. Ni kete ti fiimu na ti jade ni o ti gba opolopo agbeyewo ti o wu ni lori jojo.

Àwọn tí ó kó'pa ní'bẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Bisola Aiyeola gege bi Ovy
  • Uche Ogbodo
  • Shaffy Bello
  • Mofe Duncan

Ìtẹ́wọ́gbà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Talk African Movies, ajo ti o ma n se agbeyewo fiimu, boya o dara tabi ko dara fun wiwo, fonrere fiimu yi wipe ohun ti o ja geere ni a fi se ati wipe awon osere inu re ko ipa won ni ona ti o ni itumo ti o ye kooro. Ajo yi tun se afikun wipe itumo ede ti a lo ninu fiimu naa ye ni kedere o si dara.[1] Ajo miran, Nollywood Reinvented tun fonrere fiimu na nipa fifun ni ida meta ninu marun wipe o pegede. Ayo yii yin fiimu na wipe eni ti o ko ipa olori osere ninu fiimu naa se daradara ati wipe orin ti a lo ninu re dara jojo ati ni pataki julo wipe itan naa ko ni l'ogbon. Ni soki, a se akosile re wipe itan yi, "Ohun Ovy, yo ti ma dun mo eni ti o ba wo lo ki o to di wipe yo wa mu ni da'ro nigba ti a ko lero."[2] Ajo miran ti a n pe ni tns.ng ninu agbeyewo fiimu yi ni tire so wipe erongba fiimu yi lati fi ye wa wipe awon abarapa ti o wa lawujo wa naa le gbe igbe aye ti o ni itumo, lai si idiwo dara sugbon ni ero tiwon, iba dara ti a ba yo abala ifiyajeni kuro ninu fiimu naa.  tns.ng wa fonrere re wipe fiimu yi pegede nitipe ko si osere pupo ju ti o ko'pa ninu re ati wipe eleyi je ki itumo erongba fiimu naa ki o yeni yekeyeke. Ipa ti awon olu osere ko ninu fiimu naa, ati amulo orin ti o fi itumo kikun fun fiimu naa, awon orin lati enu Johnny Drille, Di'Ja ati Gabriel Afolayan ni a se alaye re wipe o papo lati fi itumo ti o ye kooro fun fiimu naa ti o si mu ko o je ise ti o wu ni lori jojo.  A se alaye fiimu naa lakotan wipe o je "akojopo itan ti o dara, awon osere ti o gbamuse ati idari ti o lo geere".[3]

Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Ovy's voice". Talk African Movies. January 29, 2018. 
  2. "Ovy's voice". Nollywood Reinvented. April 1, 2017. 
  3. "Review: “Ovy’s Voice” Featuring #BBNaija’s Bisola Is A Very Fine Blend". True Nollywood Stories.