Owo sise

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ise de omo alaseje Owo de omo alasela

    Owo sise ti a tun mo si kara-kata je okan pataki ni ara ise aje awon Yoruba. Erongba ontaja ni lati Jere, nitori 'Ere ni omo oloja n je'. Eni ti o ta oja lai jere tabi pa oju owo 'sowo sooti ni'.
    Pataki owo sise ni ile Yoruba
   Owo sise je awon Yoruba logun, nitori awon idi wonyi:

1. O je ise aje ti n mu ki a nise eni lowo. 2. Owo sise n le ise ati osi danu, a si so ni di olowo. 3. O n mu ni i tepa mose, ki a ma sole. 4. O n mu ki ire oko wolu lopo yanturu 5. O sokunfa ajosepo laaarin eya Yoruba ati eya miiran.

  Orisirisi owo ti Yoruba n se 

1. Arobo tabi Agbata 2. Ajapa 3. Ounje tita 4. Worobo tabi Wosiwosi 5. Eran Osin: Awon onisowo miiran wa ti won n ta eran osin. Irufe eran osin bii: Ewure Maluu Ooya Aguntan Adie Igbin Agbo Pepeye Eja Odo Elede Tolotolo Ehoro.