Pataki oruko ninu ede Yoruba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

PATAKI ORUKO NINU EDE YORUBA.

   Awon Yoruba ka oruko si pupopupo. Eranje l' o je fun won lati maa ro itumo oruko ti won ba gbo tabi ti won ba n lo. Oruko, ti eniyan tabi oja tabi ilu tabi adugbo ba n je, kun fun itumo pataki ti awon eniyan maa n ranti nigbakuugba. Ti isedale awon Yoruba la n wi yi o, ki i se ti aye d'aye oyinbo ti ede Geesi n so opolopo omo Yoruba di alaimokan nipa asa atayebaye ile wa. Eyin e yara wo awon oruko wonyi, oruko eniyan: Ayodele, Morenike, Ogundipe, Omiyale. Oruko abiso ni awon oruko wonyi, nipa won la si n powe pe; "ile l'a a wo  k'a too s'omo loruko".
  Orisi oruko miran wa ti Yoruba n so omo won, eyi ni awon oruko amutorunwa to je pe itumo won dalori irufe ohun to sele nigba ti omo wa ninu oyun tabi nigba tomo naa jade lati inu iya a re. Bi apeere: Tayewo (eyi to saaju ninu awon ibeji); Ajayi (omo to doju dele nigba ti a bii gan-an); Ojo (omo to. we iwo morun nigba ti a bii); Jimoon (omo ti a bi lojo jimoon) ati bee bee lo.
   Orisi oruko keta ni awon oriki soki ja si gan-an, sugbon o wopo ka paala laarin oruko gidi ati oriki. Idi eyi ni pe oro ajuwe ni oriki soki, oro t'o juwe iwa ati ise ati ara oloriki naa. Bi apeere: Akunyun-un (alakitiyan eniyan), Abeke (obinrin daradara ti a tile n be na ka too ke e), Ajeibon (ode atamatase).