Jump to content

Pernilla August

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Pernilla August
Pernilla August ní ibi Guldbagge Award ti ọdún 2013
Ọjọ́ìbíMia Pernilla Hertzman-Ericson
13 Oṣù Kejì 1958 (1958-02-13) (ọmọ ọdún 66)
Stockholm, Sweden
Orúkọ mírànPernilla Östergren
Iṣẹ́Actress, film director
Ìgbà iṣẹ́1975–present
Olólùfẹ́
Àwọn ọmọ3, including Alba
Àwọn olùbátanAnders August (former stepson)

Pernilla August (Àdàkọ:IPA-sv; orúkọ tí àwọn òbí rẹ̀ fun ni Mia Pernilla Hertzman-Ericson; tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdun 1958)[1] jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orilẹ̀-èdè Sweden. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣèrébìnrin tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní Sweden, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú Ingmar Bergman, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Best Actress ní ayẹyẹ Cannes Film ti ọdún 1992 fún ipa rẹ̀ nínú The Best Intentions. Ó gbajúmọ̀ káàkiri àgbáyé fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Shmi Skywalker nínú eré Star Wars: Episode I – The Phantom Menace àti Star Wars: Episode II – Attack of the Clones.

Àwọn àmì ẹyẹ tí ó ti gbà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Díè nínú àwọn àmì ẹyẹ tí Pernilla ti gbà ni Best Actress ní ayẹyẹ Cannes Film ní ọdún 1992, fún ipa rẹ̀ nínú eré Bille August tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ The Best Intentions.[2] Fún eré kan náà, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Best Actress28th Guldbagge Awards.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Pernilla August". sfi.se. Retrieved 2 January 2017. 
  2. "Festival de Cannes: The Best Intentions". festival-cannes.com. Retrieved 14 August 2009. 
  3. "Den goda viljan (1992)". Swedish Film Institute. 22 March 2014.