Pete Edochie

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Pete Edochie
Pete-edochie.jpg
Iṣẹ́Actor

Oloye Pete Edochie, MON (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ keje oṣù kẹta ọdún 1947) jẹ́ àgbà-ọ̀jẹ̀, gbajúmọ̀ àti ìlúmọ̀ọ́kà òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ ẹ̀yà Ìgbò láti ìpínlẹ̀ Anambra, lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Sinimá àgbéléwò lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Ìgbò ló ti ń kópa. Wọ́n kà á sí àgbà òṣèré sinimá-àgbéléwò tó lẹ́bùn eré sinimá ṣíṣe jùlọ nílẹ̀ adúláwọ̀ Áfíríkà.[2] Èyí hànde látàrí onírúurú àmìn ẹ̀yẹ tí ó ti gbà gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò, pàápàá jùlọ àmìn ẹ̀yẹ láti ọwọ́ African Magic àti Africa Film Academy. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé akọ̀ṣẹ́mọṣẹ́ olùṣàkóso àti gbajúgbajà agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni, ó di ìlúmọ̀ọ́kà òṣèré lọ́dún 1980 nígbà tí ó kópa gẹ́gẹ́ bí olú-ẹ̀dá ìtàn tí wọ́n pè ní Okonkwo nínú ìwé ìtàn àròsọ kan, Things Fall Apart tí àgbà-ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé, Chinua Achebe kọ, tí wọ́n sọ di eré àgbéléwò orí ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n NTA tó gbajúmọ̀ jùlọ nígbà náà. Gbajúmọ̀ Edochie pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ààrẹ àná, Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ fi dá a lọlá pẹ̀lú àmìn ẹ̀yẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Member of the Order of the Niger, MON lọ́dún 2003. Pete Edochie jẹ́ ọmọ ìjọ àgùdà.[3] [4]

Ìgbà èwe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n bí Pete Edochie ní Ọjọ́ keje oṣù kẹta ọdún 1947. Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Anambra ni ṣùgbọ́n Zaria, ní ìpínlẹ̀ Kaduna ló ti ṣe kékeré rẹ̀ dàgbà. Ó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé ní St. Patrick and James Primary School, Zaria, kí ó tó tẹ̀ síwájú ní St. John's College fún Ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀, lẹ́yìn èyí ló sí orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó sìn kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìwé-ìròyìn àti ìgbóhùnsáfẹ̀fẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ó ṣíṣe ní ilé iṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ọkọ̀ ojú-irin kí ó tó dára pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ Nigeria Television Authority, NTA lọ́dún 1967 nígbà tó wà lọ́mọ ogún ọdún. Kò pẹ́ nídìí iṣẹ́ púpọ̀ kí ó tó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ tíátà.[5]

Àtòjọ àwọn sinimá àgbéléwò tó ti kópa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 • Lionheart (2018)
 • Mummy Why (2016)
 • Heavy Battle (2008)
 • Test Your Heart (2008)
 • Greatest Harvest (2007)
 • Secret Pain (2007)
 • Fair Game (2006)
 • Holy Cross (2006)
 • Lacrima (2006)
 • Living with Death (2006) .... Mr. Harrison
 • Passage of Kings (2006)
 • Simple Baby (2006)
 • Zoza (2006)
 • Azima (2005)
 • Baby Girl (2005)
 • End of Money (2005)
 • Living in Tears (2005)
 • Never End (2005)
 • No More War (2005)
 • Ola... the Morning Sun (2005)
 • Price of Ignorance (2005)
 • The Price of Love: Life Is Beautiful (2005)
 • Sacred Tradition (2005)
 • The Tyrant (2005)
 • Across the Niger (2004)
 • Coronation (2004)
 • Dogs Meeting (2004) .... Anacho
 • Dons in Abuja (2004)
 • The Heart of Man (2004)
 • King of the Jungle (2004)
 • Love from Above (2004)
 • My Desire (2004)
 • Negative Influence (2004)
 • The Staff of Odo (2004)
 • St. Michael (2004)
 • Above Death: In God We Trust (2003)
 • Arrows (2003)
 • Billionaire Club (2003)
 • Egg of Life (2003)
 • Honey (2003)
 • Love & Politics (2003)
 • Miserable Wealth (2003)
 • The Omega (2003)
 • Onunaeyi: Seeds of Bondage (2003)
 • Rejected Son (2003)
 • Selfish Desire (2003)
 • Super Love (2003)
 • Tears in the Sun (2003)
 • Tunnel of Love (2003)
 • When God Says Yes (2003)
 • Battle Line (2002)
 • My Love (2002)
 • Tears & Sorrows (2002)
 • Greedy Genius (2001)
 • Holy Ghost Fire (2001)
 • Terrible Sin (2001)
 • Oduduwa (2000)
 • Set-Up (2000)
 • Chain Reaction (1999)
 • Lost Kingdom (1999)
 • Narrow Escape (1999)
 • Living in Darkness (1999)
 • Rituals (1997)
 • Things Fall Apart (1987), TV series
 • Last Ofalla
 • Lion throne
 • Lion of Africa
 • Igodo
 • Evil men
 • Monkey chop banana
 • Idemili
 • 50 days with Christ
 • The Egg

[6]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Pete Edochie, Actor, Producer, Nigeria Personality Profiles". Nigeria. 1947-03-07. Retrieved 2019-11-29. 
 2. "All You Need To Know About Veteran Actor Pete Edochie". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2019-03-07. Retrieved 2019-11-29. 
 3. Vkenya, Dr. (2019-07-13). "Pete Edochie Biography: Wife, Sons, Daughter, Family, Proverbs & Quotes". Vkenya. Retrieved 2019-11-29. 
 4. "10 Real Facts About Pete Edochie You Probably Didn't Know - Austine Media". Austine Media. 2019-10-08. Retrieved 2019-11-29. 
 5. "Pete Edochie (Ebubedike) (Actor) - Filmography". INSIDENOLLY. 1947-03-07. Retrieved 2019-11-29. 
 6. "Pete Edochie Biography – Net Worth, Age, Wife, Children & Movies". BioNetworth. 1947-03-07. Retrieved 2019-11-29.