Pneumococcal vaccine

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àjẹsára ìlòdìsí kòkòrò inú jẹ́ àjẹsára alòdìsí kòkòrò Streptococcus pneumoniae.[1] Ìlò wọn lè dẹ́kun àwọn irúfẹ́ àrùn ẹ̀dọ̀fóró, àrùn wíwú ọpọlọ tàbi ́egungun ẹhìn, àti àrùn ìṣàkóbára ara-ẹni. Irúfẹ́ àjẹsára ìlòdìsí kòkòrò inú méjì lówà: àjẹsára àjùmọ̀ṣe àti àjẹsára ọ̀pọ̀ ṣúgà. Wọ́n maa ń fúnni bóyá nípa abẹ́rẹ́ ninú iṣan tàbí lábẹ́ àwọ̀ lásán.[1]

Àjọ Ìlera Àgbáyé gbaninímọ̀ràn ilo abẹ́rẹ́ ninú iṣan niti ìfúnni lábẹ́rẹ́ àjẹsára ìlànà iṣẹ́ tí a ń fún àwọn ọmọdé. Lára rẹ̀ ni HIV/AIDS. Àwọn ìlo mẹ́ta tàbí mẹ́rin tí a gbaninímọ̀ràn jẹ́ láàrín ìdá 71 àti 93 tí ó jáfáfá ní dídẹ́kun àrùn líle. À̀jẹsára ọ̀pọ̀ ṣúgà, bí o ti jáfáfá láàrin àwọn àgbà, kò jáfáfá láàrin àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn dín ní ọdún méjì tàbí àwọn tí ó lè yára kó àìsàn.[1]  

Àjẹsára náà kò léwu rárá. Pẹ̀lú àjẹsára àjùmọ̀ṣe, ìdá 10 àwọn ọmọ ọwọ́ sábà maa ń ní ojú pípọ́n níbi ìgba-abẹ́rẹ́, ibà, tàbí àyípadà orun. Ìbà náà lè wáyé. Ọ̀pọ̀ ìhún-ara kò wọ́pọ̀.[1]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]