Rachel Bakam
Rachel Bakam | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Kaduna, Naijiria |
Ẹ̀kọ́ | Ahmadu Bello University |
Iṣẹ́ | Olootu eto, Oludari, osere, alamoran, olusakoso ere idaraya |
Ìgbà iṣẹ́ | 2000–lowolowo |
Gbajúmọ̀ fún | Iranlowo omo eyan, oge sisw, itako gbigbe eniyan fi sise, gbigbimo alafia, ere idaraya |
Notable work | Trends & Rachel, Stylecode, Rachel the Piper, Yanayin Zamani |
Website | pipersdynasty.com |
Rachel Bakam jẹ́ òṣèré ará orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ònkọ̀wé, olóòtú ètò ori tẹlifíṣọ̀nù, àti alátakò gbígbé ènìyàn fi ṣiṣẹ́. Òun ni alákòso àti adarí Rayzeds Media Ltd;[1] olùdásílẹ̀ ati alákòso tí Nigerian Water Ski And Wakeboard Federation (NWWF); àti alámọ̀ràn fún Performing Musician Employers Association (PMAN) pẹ̀lú African Fashion Reception Paris.[2] Bakam jẹ́ aṣojú fún àwọn arìnrìnàjò àti ìgbé ayé àláfíà. Bakam ti fìgbàkan jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ níbi èto ìṣàkóso tí Amẹ́ríkà kan fún àwọn àlejò káríayé.[3][4] Ó ma ń ṣe olóòtú èto Trends & Rachel, [5] ìfihàn tẹlifíṣọ̀nù kan tí ó gbajúmọ̀, tí ó ma ń jẹ́ gbígbé sóri afẹ́fẹ́ ní ìkànnì tẹlifíṣọ̀nù NTA, AIT, DSTV, àti Startimes. Ó tún ṣe àgbéjáde àti àgbékalẹ̀ èto "Rachel the PIPER" àti ẹ̀ya Hausa rẹ̀ "RACHEL MAI KAKAAKI"; èto tẹlifíṣọ̀nù tí eré ìdárayá ṣùgbọ́n tí ó tún wà fún ìféràn ọmọ ènìyàn.[6]
Ìgbé ayé ìbẹ̀rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bakam lẹni táa bí tó sì dàgbà ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná sọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀, níbití ó ti ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ilé-ìwé girama, àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga.[7] Ó kẹ́kọ̀ọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti eré míràn ni Ahmadu Bello University[8] àti ṣíṣe fíìmù orí ẹ̀rọ ní New York Film Academy.[9] Ó pàdánù bàbá rẹ̀ ní ọmọ ọdún méjìlá. Ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, àkọ́kọ́ ní ilé-ìgbìmọ̀ àwọn ìtajà ńlá kan, léyìn náà ní ilé ìṣiṣẹ́ orin àti sinimá tó sì padà wá kó ipa asíwájú nínú eré Haúsá àtìgbàdégbà kan tí a mọ̀ ní Rayuwa.[10]
Iṣẹ́-ìṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó ṣe iṣẹ́ agùnbánirọ̀ rẹ̀ ní ilé iṣẹ́ Nigerian Television Authority International, níbití ó ti ṣe àgbéjáde àti àgbékalẹ̀ àwọn oríṣiríṣi ètò bíi Trends, Saturday Morning, and Style Code. Ó tẹ̀síwájú láti kẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣe fíìmù orí ẹ̀rọ ní New York Film Academy, lẹ́yìn náà ló ṣètò ìdásílẹ̀ Rayzed Media Ltd.[11] Bakam sòkùn fà ṣíṣe eré ìdárayá orí omi ní Nàìjíríà.[12] Ó jẹ́ alámọ̀ràn fún African Fashion Reception Paris.[13]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Aderibigbe, Tolulope (18 April 2015). "I Dropped A Business Deal Worth Millions Because Of Harassment– Rachel Bakam". Leadership Newspaper. http://leadership.ng/style/426480/i-dropped-a-business-deal-worth-millions-because-of-harassment-rachel-bakam. Retrieved 8 October 2016.
- ↑ "IMPRESSIVE: Amb. Rachel Bakam Lands more Mega Media Appointments". The Nigerian Voice. 26 April 2016. http://www.thenigerianvoice.com/news/214683/impressive-amb-rachel-bakam-lands-more-mega-media-appointm.html. Retrieved 8 October 2016.
- ↑ "TV Personality, Rachel Bakam Addresses Audience At White House Sponsored Event In Washington". Entertainment Express. 27 August 2015. Archived from the original on 9 October 2016. https://web.archive.org/web/20161009201758/http://expressng.com/2015/08/tv-personality-rachel-bakam-addresses-audience-at-white-house-sponsored-event-photos/. Retrieved 8 October 2016.
- ↑ "Ambassador Rachel Bakam Speaks At The International Visitors Leadership Programme In US". Oncova. 27 August 2015. http://uncova.com/ambassador-rachel-bakam-speaks-at-the-international-visitors-leadership-programme-in-us. Retrieved 8 October 2016.
- ↑ Nda, Solomon (19 September 2015). "Rachael Bakam: Financial Gratification Does Not Determine My Relationships". Leadership Newspaper. http://leadership.ng/entertainment/461779/rachael-bakam-financial-gratification-does-not-determine-my-relationships. Retrieved 8 October 2016.
- ↑ "Rachel Bakam Supports Southern Kaduna - Writing.Com". www.writing.com (writing.com). 2 February 2017. https://www.writing.com/main/view_item/item_id/2110851-Rachel-Bakam-Supports-Southern-Kaduna. Retrieved 2 February 2017.
- ↑ Aderibigbe, Tolulope (18 April 2015). "I Dropped A Business Deal Worth Millions Because Ogun Harassment– Rachel Bakam". Leaderships. http://leadership.ng/style/426480/i-dropped-a-business-deal-worth-millions-because-ouf-harassment-rachel-bakam. Retrieved 8 October 2016.
- ↑ Àdàkọ:Votes is news
- ↑ Difference, Maker (9 February 2017). "What You Need to Know About Rachel Bakam - Writing.Com". www.writing.com (wiriting.com). https://www.writing.com/main/view_item/item_id/2111619-What-You-Need-to-Know-About-Rachel-Bakam. Retrieved 9 February 2017.
- ↑ "What You Need to Know About Rachel Bakam - Writing.Com". www.writing.com (Writing.com). 9 February 2017. https://www.writing.com/main/view_item/item_id/2111619-What-You-Need-to-Know-About-Rachel-Bakam. Retrieved 9 February 2017.
- ↑ "What You Need to Know About Rachel Bakam - Writing.Com". www.writing.com (writing.com). 9 February 2017. https://www.writing.com/main/view_item/item_id/2111619-What-You-Need-to-Know-About-Rachel-Bakam. Retrieved 9 February 2017.
- ↑ "What You Need to Know About Rachel Bakam - Writing.Com". www.writing.com (writing.com). 9 February 2017. https://www.writing.com/main/view_item/item_id/2111619-What-You-Need-to-Know-About-Rachel-Bakam. Retrieved 9 February 2017.
- ↑ "What You Need to Know About Rachel Bakam - Writing.Com". www.writing.com (writing.com). 9 February 2017. https://www.writing.com/main/view_item/item_id/2111619-What-You-Need-to-Know-About-Rachel-Bakam. Retrieved 9 February 2017.