Ronald Chagoury
Ìrísí
Ronald Chagoury (tí a bí ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kìíní ọdún 1949) jẹ́ oníṣòwò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Chagoury Group pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Gilbert Chagoury.
Ìgbésíayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Ronald Chagoury sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kìíní, ọdún 1949. Ó sì jẹ́ ọmọ Ramez àti Alice Chagoury tí ó kúrò ní ìlú Lebanon ní ọdún 1940. Ó kàwé ní College des Frères Chrétiens ní ìlú Lebanon, ó sì tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa òwò ní California State University, tí ó wà ní Long Beach, ní US.[1]
Chagoury fẹ́ Berthe, wọ́n bí ní ọmọ méjì papọ̀.[1]
Chagoury ti yọ nínú ìwé Panama.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "Executive Team". Chagoury Group. Archived from the original on 2016-05-22. Retrieved 2016-05-20.
- ↑ Leaf, Aaron. "Nigeria's Chagoury Group Named In Latest Panama Papers Revelation Okayafrica". Okayafrica.com. Retrieved 2016-05-20.