Jump to content

Sámúẹ́lì Tunde Bajah

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Samuel Tunde Bajah)

Samuel Olatunde Emiko Bajah' (ọjọ́ kẹrinlélógún oṣù kẹrin, ọdún 1934 sí ọjọ́ kẹtalélógún oṣù kejì, ọdún 2008) jẹ́ olùkọ́ sáyẹ́ǹsì àti onkòwé. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onkòwé tí ó kọ ìwé Chemistry: A New Certificate Approach pẹ̀lú Arthur Godman.[1][2][3]

Ìgbésí Ayé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Bajah ní ọjọ́ kẹrinlélógún oṣù kẹrin, ọdún 1934 ní Ìlú Warri, Ìpínlẹ̀ Delta, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà [1] sí Joseph Bajah, kílákì kan pẹ̀lú ilé iṣẹ́ United Africa (UAC) ní Burutu, àti ìyàwó rẹ̀.

Bajah fẹ́ ìyàwó rẹ̀, Ebun Agatha Bajah (née Olomu) ní ọjọ́ kẹẹ́dóógún oṣù kẹfà ni ọdún 1963, àwọn méjèèjì si bí ọmọkùnrin méjì àti ọmọbìnrin márùn-ún.

Samuel Tunde Bajah bẹ̀rẹ̀ ìwé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ilé ìwé C.M.S. St. Andrews, Warri, Ìpínlẹ̀ Delta. Láàárín ọdún 1949 sí ọdún 1954, ó lọ sí ilé ìwé gíga fún àwọn olùkọ́ ti Hussey, ní ìlú Warri níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí fún ìjáde ilé ẹ̀kọ́ gírámà (WAEC). Bajah wà ní ẹgbẹ́ àwọn tí ń sáré ti Ilé Ìwé rẹ̀ tí wọ́n sì gba ife ẹ̀yẹ tí Grier ni ọdún 1954.

Bajah tẹ̀síwájú sí Yunifásítì Ìlú Ibadan, Ìpínlẹ̀ Oyo, Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí nínú ẹ̀kọ́ kẹ́mísítirì tí ó sì ṣe tán ní ọdún 1962. Ní Yunifásítì Ìlú Ibadan, ó gbá eré afẹ̀sẹ̀gbá, wọn sì yán gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹ́ agbá bóòlù ti Yunifásítì ní ọdún 1962. Láàárín ọdún 1963 sí ọdún 1964,ó wà ní Yunifásítì Oxford fún ẹ̀kọ́ gíga ti Post-graduate nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Ó lọ sí Yunifásítì ti South Dakota United States fún M.A rẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ PhD.

Iṣẹ́ Olùkọ́ Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bajah bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kẹ́mísítirì ni ilé ìwé tí ó ti kàwé jáde, Ilé Ìwé Gíga fún àwọn olùkọ́ ti Hussey ní ọdún 1962. Ó gòkè sí ipò Olùdarí sáyẹ́ǹsì ti Ilé Ìwé náà ní ọdún 1965, ó si di ipò ọ̀hún títí di ọdún 1967. Ó dara pọ̀ mọ́ International School, Yunifásítì Ibadan ni ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 1967, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ títí di ọdún 1972.[4] Ó tẹ̀síwájú sí Yunifásítì ti South Dakota ní United States fún ẹ̀kọ́ ọmọ̀wé rẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì ní ọdún 1969. Ní ọdún 1972, ó padà sí Nàìjíríà pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí ti akẹ́kọ̀ọ́ másítà àti ọmọ̀wé.

Ó padà sí ilé ìwé ti Ẹ̀kọ́, Yunifásítì ti Ìbàdàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwádìí ti ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ní ilé ìwé tí ẹ̀kọ́, ó kúrò ní ipò ẹni tí ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwádìí ti ìmọ̀ ẹ̀rọ lọ sí ipò Ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ràn ní ọdún 1984.[5][3]

Yunifásítì ti Ìbàdàn, a yàn án sípò àwọn olóòtú tí orílè èdè àti ti àgbáyé. A yàn án gẹ́gẹ́ bí olóòtú ìwé ìhà Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà fún ẹ̀kọ́ láàárín ọdún 1974 àti ọdún 1980. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùdarí ilé ìwé ẹ̀kọ́ láti ọdún 1983 sí ọdún 1985 àti ní ọdún 1989,a yàn án gẹ́gẹ́ bí díínì ti ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Ó ṣiṣẹ́ ní kíkún gẹ́gẹ́ bí olùdarí ti Ilé Ìwé náà láti ọdún 1996,ó si fi ipò náà sílẹ̀ ní ọdún 1999.

Bajah jẹ́ olùdarí ẹ̀kọ́ ní Commonwealth olúlùú, London (ọdún 1991 sí ọdún 1994). Ó jẹyọ gẹ́gẹ́ bí olùkópa tàbí ọ̀kan lára àwọn dáhùn ìbéèrè nínú àwọn ìpàdé ni Áfríkà, Éúrópù, Amẹ́ríkà àti Australia àti sí àwọn ilé iṣẹ́ tí àgbáyé, lára wọn ni World Bank, UNESCO, UNICEF, SIDA àti DSE.

Ó dá ilé iṣẹ́ tí kìí ṣe ti ijoba tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àpapọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti sáyẹ́ǹsì.

Ìwé tí ó tẹ̀ jáde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bajah jẹ́ onkòwé àwọn ìwé sáyẹ́ǹsì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Chemistry for Secondary Schools (A New Certificate Approach) tí òhun àti Arthur Godman jọ kọ, tí à si ti ṣe ògbífò rẹ̀ sí èdè mẹ́fà tí èdè Faránsẹ́ àti Spanish sì pẹ̀lú. Àwọn ìwé sáyẹ́ǹsì tí ó kọ ni Laboratory Exercise in Volumetric Analysis (Chemistry), Primary Science for Nigerian Schools, àti African Science: Facts or Fiction.[6]

Àwọn Àmì Ẹ̀yẹ àti Ọlá tí a fun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Refimprove section Ní ọdún 1982, ó di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti ẹgbẹ́ olùkọ́ sáyẹ́ǹsì ti orílè èdè Nàìjíríà (FSTAN). Ó di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti àwọn Chemical Society of Nigeria (FCSN) ní ọdún 1998. Ní ọdún 1992, a bu ọlá fún pẹ̀lú àmì ẹ̀yẹ ti àwọn Distinguished Service to Science Education káàkiri àgbáyé ní ọdún 1996. A bu ọlá fún pẹ̀lú Distinguished Chemical Society ti Nàìjíríà. Bajah tún jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ Royal Institute tí Chemistry, United Kingdom; àti ọmọ ẹgbẹ́ ẹgbẹ́ ti ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì, United States.[1]

Bajah kú ni ọjọ́ kẹtalélógún oṣù kejì ní ọdún 2008 ní ọmọ ọdún 73.

Àwọn Ìtọ́kási

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control