Simon Deng
Simon Aban Deng jẹ́ ajàfẹ́tọ́ ènìyàn ọmọ orílẹ̀ èdè Sudan tí United States. Wọ́n jí Simon gbé nígbà tí ó wà ní èwe. Ó jẹ́ ọmọ bíbí ìjọba Shilluk ní gúúsù Sudan, Deng lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bi ẹrú ní gúúsù Sudan.[1]
Ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n kó Simon lẹ́rú nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn[2] nígbà tí aládùúgbò rẹ̀ kan sọ pé kó tẹ̀lẹ́ òun lọ ìrìn-àjò kan. Deng tẹ̀le, ó sì fi Deng gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ìdílé rẹ̀. Láti ìgbà tí ó yọbọ́ tí ó sì lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, ó ti ń rìnrìn àjò káàkiri orílẹ̀ èdè láti kọ́ nípa ẹ̀kọ́ àti láti kó lòdì sí Ìsìnrú.
Nínú ìwé rẹ̀, Deng sọ pé: "... Mo fìgbà kan jẹ́ ẹrú. ... Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, àwọn ọmọ ogun Arab ya bo abúlé mi. Tí mo ṣe ń sáwọ igbó ni mò rí tí wọ́n yin àwọn ọ̀rẹ́ mi kan, wọ́n sì dáná sun àwọn àgbàlagbà tí kò le sáré nínú ilé wọn. Wọ́n jí mi gbé wọ́n sì fi mí fún ìdílé Arab kan gẹ́gẹ́ bí "ẹ̀bùn"."[2]
Nígbà tí Deng jẹ́ ẹrú, ojú rẹ̀ rí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ní òun rántí bí wọn ṣe nà òun nítorí kò pariwo tó, bí àwọn ọmọdé tó kù ṣe náà. Wọ́n fi ipá mu láti sọ bẹ́ẹ̀ni sí oun gbogbo, pẹ̀lú ìyà. Ó ní pé "nǹkan eyokan tí mo le bèrè fún nígbà mìíràn ni àánú... Àánú kìí sì fi gbogbo ìgbà sí."
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Simon Deng". Speaking Matters. 2011. Archived from the original on October 7, 2018. Retrieved November 1, 2011.
- ↑ 2.0 2.1 "Simon Deng, Former Sudanese Slave, Human Rights Activist". International Humanist and Ethical Union. June 21, 2005. Retrieved November 1, 2011.