Smuggling of migrants in Nigeria

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ṣíṣe fàyàwó àwọn ènìyàn láti ìlú Nàìjíríà sí òmíràn kì í ṣe ohun àjòjì ní àgbáyé, kọ́dà, kò yọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílẹ̀. Àwọn obìnrin, ọmọbìnrin, ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ ni wọ́n máa farakaáṣá ìwà ìgbéni lọ sí ìlú mìíràn ní ọ̀nà àìtọ́ àti òwò títa ènìyàn. Kì í ṣe òkè òkun nìkan ni wọ́n ń kó àwọn ènìyàn wọ̀ lọ́nà àìtọ́, ìwà ìbàjẹ́ yìí náà máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]

Ṣíṣẹ Fàyàwó àwọn ẹ̀nìyàn láti ibìkan lọ sí ibòmíràn: Ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn ènìyàn láti ibìkan lọ sí ibòmíràn jẹ́ ọ̀nà àìtọ́ tí àwọn ènìyàn ń gbà wá owó ní pa gbígbé àwọn ènìyàn wọ ìlú tí kì í ṣe ìlú wọn lọ́nà àìtọ́. Lára àwọn òfin tí ó de ṣíṣị́ kúrò láti ìlú kan sí òmíràn kò fi àyè gba kí ẹ̀nìyàn wọ ìlú ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu tàbí kí ènìyàn máa gbe nínú ìlú láìní ìwé ìgbé ìlú.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àjọ United Nations (UN) gbogbo orílẹ̀-èdè ni àwọn àmòòkùn-ṣèkà yìí ń kó àwọn èniyàn wọ̀ ní ọ̀nà àìtọ́. Wọ́n tẹ́sìwájú láti jẹ́kí amọ̀ pé àwọn tí wọ́n ń lọ sí ìlú mìíràn ní ọ̀nà àìtọ́ ṣí sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu. Ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn ní wọ́n tí kú sí aṣálẹ̀, àwọn mìíràn sí rì sí inú omi nípa sẹ̀ pé wọ́n fẹ́ wọ ìlú onílùú ní ọ̀nà àìtọ́. Ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló ti pàdánù èmí wọn láti pasẹ̀ àìnímọ̀ tàbí mímọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ wọ ìlú ònílùú ní ọ̀nà àìtọ́. 

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àjọ (UNODC) United Nations Office on Drugs and crimes sọ, wọ́n kò dátà tó tó láti lè mo iyẹ àwọn ènìyàn tí wọn wọ ìlú ní ọ̀nà àìtọ́ àti ọ̀nà tí àwọn tí ó ń ko wọ́n wọlé ń gbà[2].

Ìgbésẹ̀ tí Nàìjíríà ń gbé láti kojú ìwà gbígbé àwọn ènìyàn láti ìlú kan sí òmíràn lónà àìtọ́.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nítorí bí ewu tó wà nínú kíkó àwọn ènìyàn wọ ìlú mìíràn lọ́nà àìtọ́ ló mú kí àwọn aláṣẹ orílè-èdè Nàìjíríà ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn UNODC láti ara iṣé àkànṣe STARSOM.

“ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ní àwọn ohun to tọ́ láti kojú ìjà sí ìkóni-wọ-ìlú lọ́nà àìtọ́ pẹ̀lú àtìlẹ́yì NAPTIP."

“Àwọn amọ̀fin àti ọlọ́pàá ń bójútó àwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń mójútó ọ̀nà wíwọ inú ìlú àti gbígbé inú ìlú ní àwọn ààlà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àwọn ìlú tó jẹ́ ibùgbé fún àwọn akóní-wọ-ìlú lọ́nà àìtọ́ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ghana.[3]

Àjọ UNODC ìwádìí fihàn pé àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ yìí máa ń ní ètò tí ó pé. Láti kọjá sí Niger, ọkọ̀ ìrìnsẹ̀ ojoojúmó ní wọ́n ń lò láti kó wọ́n lọ sí apá àríwá, kí wọ́n to fi ẹsẹ̀ wọ Niger, kí ọ̀kan lára agbẹ́ni-wọ̀lú lọ́nà àìtọ́ tó wá bá wọn lára.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Preventing Human Trafficking and Smuggling of Migrants in Nigeria". A-TIPSOM Nigeria. 2020-04-06. Retrieved 2022-03-30. 
  2. "Smuggling of migrants". United Nations Office on Drugs and Crime. 2010-06-08. Archived from the original on 2022-03-30. Retrieved 2022-03-30. 
  3. "Nigeria Takes Steps to Stop Migrant Smuggling". United Nations : Office on Drugs and Crime. 2021-12-16. Retrieved 2022-03-30.