Àwùjọ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Society)
Àwùjo àtijó

Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Kò sí ẹ̀dá alààyè tó dá wà láì ní Olùbátan tàbí alájogbé. Orísirísi ènìyàn ló parapọ̀ di àwùjọ-bàbá, ìyá, ará, ọ̀rẹ́, olùbátan ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ìyá ṣe ń bí ọmọ, tí bàbá ń wo ọmọ àti bí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ṣe ń báni gbé, bẹ́ẹ̀ ni ìbá gbépọ̀ ẹ̀dá n gbòòrò si. Gbogbo àwọn wọ̀nyí náà ló parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá. Àti ẹ̀ni tí a bá tan, àti ẹni tí a kò tan mọ́, gbogbo wa náà la parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá.

Ní ilẹ̀ Yorùbá ati níbi gbogbo ti ẹ̀dá ènìyàn ń gbé, ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ṣe pàtàkì púpọ̀. Bí ẹnìkan bá ní òun ò bá ẹnikẹ́ni gbé, tí kò bá gbé nígbó, yóó wábi gbàlọ. Ṣùgbọ́n, àwa ènìyàn lápapọ̀ mọ ìwúlò ìbágbépọ̀. Orísirísi àǹfàní ni ó wà nínú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá.

Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn bá n gbé papọ̀, ó rọrùn lati jọ parapọ̀ dojú kọ ogun tàbí ọ̀tẹ́ tí ó bá fẹ́ wá láti ibikíbi. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àjòjì ọwọ́ kan ò gbẹ́rù dórí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló ṣe rí fún àwùjọ-ẹ̀dá. Gbígbé papọ̀ yìí máa ń mú ìdádúró láì sí ìbẹ̀rù dání nítorí bí òṣùṣù ọwọ̀ ṣe le láti ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwùjọ tó fohùn ṣọ̀kan. Èyí jẹ́ oun pàtàkì lára ànfàní tó wa nínú ìṣọ̀kan nínú àwùjọ-ẹ̀dá. Nídà kejì, bí ọ̀rọ̀ àwùjọ-ẹ̀dá ba jẹ́ kónkó-jabele, ẹ̀tẹ́ àti wàhálà ni ojú ọmọ ènìyàn yóó máa rí. Nítorí náà, ó dára kí ìṣọ̀kan jọba ni àwujọ-ẹ̀dá.

Ìdàgbàsókè tí ó máa ń wà nínú àwùjọ kò sẹ̀yìn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bí àti ránmú un gángan ò ti sẹ̀yìn èékánná. Ó yẹ kí á mò pé nítorí ìdàgbàsókè ni ẹ̀dá fi ń gbé papọ̀. Bí igi kan ò ṣe lè dágbó ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnìkan ò lè dálùúgbé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló máa ń dá Ọgbọ́n jọ fún ìdàgbàsókè ìlú. Bí Ọgbọ́n kan kò bá parí iṣẹ́, Ọgbọ́n mìíràn yóó gbè é lẹ́yìn. Níbi tí orísirísi ọgbọ́n bá ti parapọ̀, ìlọsíwájú kò ní jìnnà si irú agbègbè bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ànfàní tó wà ní àwùjọ-ẹ̀dá tí kò sì ṣe é fi sílẹ̀ láì mẹ́nu bà.

Nínú ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá, a tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìsòro tó ń kojú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. Kò ṣe é ṣe kó máa sì wàhálà láwùjọ ènìyàn. A kò lè ronú lọ́nà kan ṣoṣo, nítorí náà, ìjà àti asọ̀ máa ń jẹ́ àwọn nǹkan tí a kò lè ṣàì má rì í níbi ti àwọn ènìyàn bá ń gbé. Wàhálà máa ń fa ọ̀tẹ̀, ọ̀tẹ̀ ń di ogun, ogun sì ń fa ikú àti fífi dúkàá sòfò. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ara àwọn ìṣòro tó n kojú àwùjọ-ẹ̀dá. Kò sí bí ìlú tàbí orílè-èdè kan kò se ní ní ọ̀kan nínú àwọn àwọn ìṣòro wọ̀nyí.

Ṣùgbọ́n, a gbódò mọ̀ wí pé awọn ànfàní àti awọn ìṣòro wọ̀nyí ti wà láti ìgbà pípé wá. Tí a bá wo àwọn ìtàn àtijọ gbogbo, a ó ri pé gbogbo àwọn nǹkan wònyí kò jẹ́ tuntun. Ọgbọ́n ọmọ ènìyàn ni ó fi ṣe ọkọ̀ orí-ìlẹ, ti orí-omi àti ti òfúrifú fún ìrìnkèrindò tí ó rọrùn. Àwùjọ-ẹ̀dá ti ṣe àwọn nǹkan dáradára báyìí náà ni wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí ó lè pa ènìyàn lára. Fún àpẹẹrẹ, ìbọn àti àdó-olóró. Àwọn ohun ìjà wọ̀nyí ni wọ́n lò ní ogun àgbájé kìnní tí o wáyé ní Odun 1914 sí 1918 àti ti èkejì ní odún 1939 sí 1945. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ti wà tí ó sì tún wà síbè di òní.

Lákòótán, ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ tó lárinrin. Ohun kan tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ nip é, kò ṣe é ṣe kí ẹ̀dá máa gbe ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Ìdí ni pé gbígbé papọ̀ pẹ̀lú ìsọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló lè mú ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbà-sókè wá