Susovan Sonu Roy
Susovan Sonu Roy tí wọ́n bí lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù keje ọdún 1994 jẹ́ ọ̀ṣèré àti oníjó ìgbàlódé ilẹ̀-òkèrè ọmọ India. Àwọn ènìyàn mọ̀ ọ́n nípa ipa tó kó nínú ètò orí tẹlifíṣàn bí i Anandamoyee Maa lọ́dún (2019) fún pẹpẹ ètò Aakash Aath channel, Mohor (2019), Korapakhi (2020), Titli (2020) fún pẹpẹ tẹlifíṣàn Star Jalsha, àti àwọn ètò mìíràn lórí pẹpẹ Zee Bangla. Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣ'eré, ijó ni ó kọ́kọ́ máa ń jó.[1]
Susovan Sonu Rou | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 19 Oṣù Keje 1994 Howrah |
Orílẹ̀-èdè | Imdia |
Iṣẹ́ | Òṣèré |
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìlú Howrah ni wọ́n bí Susovan sí l'órílẹ̀-èdè Indian ṣùgbọ́n ní Kolkata ló gbé dàgbà. Ó kàwé ní Kolkata ní ilé-ẹ̀kọ́ Dum Dum Mothijheel Rabindra Mahavidyalaya lọ́dún 2016.[1][2]
Ọmọ ọdún márùn-ún ló wà tí bàbá rẹ̀ fi kú nínú ìjàm̀bá ọkọ̀. Lásìkò yìí ni wàhálà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láyé, òun àti ìyá rẹ̀ dojú kọ ọpọ̀lọ̀pọ̀ ìṣòro. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn fẹ́ràn Susovan, nítorí tirẹ̀, wọ́n féràn màmá rẹ̀ bákan náà, ó sì nífẹ̀ẹ́ ni èyí púpọ̀.[1][3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 "Susovan Sonu Roy - Biography". IMDb. Retrieved 2024-05-03.
- ↑ "Bengali Actor Susovan Sonu Roy started his career as a dancer". Kashmir Age. 2022-01-25. Retrieved 2024-05-03.
- ↑ "Roy starts career as dancer, becomes popular face of Bengali TV series". Meghalaya Monitor. Retrieved 2024-05-03.