Toni Payne
Personal information | |||
---|---|---|---|
Orúkọ | Antionette Oyèdúpẹ́ Payne | ||
Ọjọ́ ìbí | 22 Oṣù Kẹrin 1995 | ||
Ibi ọjọ́ibí | Birmingham, Alabama | ||
Ìga | 5 ft 4 in (1.63 m) | ||
Playing position | Midfielder/Forward | ||
Club information | |||
Current club | Sevilla FC | ||
Number | 11 | ||
Senior career* | |||
Years | Team | Apps† | (Gls)† |
2017–2018 | AFC Ajax | 22 | (1) |
2018– | Ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin Sevilla FC | 48 | (11) |
National team | |||
2012 | Ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ obìnrin Amẹ́ríkà tí ọjọ́ orí wọn kò ju mẹ́tàdínlógún lọ | ||
2013 sí 2014 | Ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ obìnrin Amẹ́ríkà tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún lọ | ||
2016 sí 2018 | Ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ obìnrin Amẹ́ríkà tí ọjọ́ orí wọn kò ju mẹ́tàlélógún lọ | ||
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only. † Appearances (Goals). |
Toni Payne tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gan jẹ́ Antionette Oyèdúpẹ́ Payne, tí wọ́n bí lọ́dún 1995 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọmọ Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà. Ó máa ń gba bọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ agbáyòsáwọ̀n fún ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin Sevilla lórílẹ̀-èdè Italy. [1]
Ìgbésí-ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Toni Payne ní Birmingham, Alabama, lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sí ìdílé àwọn ọmọ Nàìjíríà tó fi Amẹ́ríkà ṣe ìbùgbé,[2] tí wọn sìn tọ́ ọ ni United States.[3]
Payne gba bọ́ọ̀lù fún Ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ obìnrin Amẹ́ríkà tí ọjọ́ orí wọn kò ju mẹ́tàlélógún lọ lọ́dún 2012. Lọ́dún 2016 sí 2018, ó gba bọ́ọ̀lù jẹun fún ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin tí Ajax. Lọ́dún 2018, ó dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin Sevilla. [1] lọ́dún 2019 fi èròǹgbà rẹ̀ hàn láti dára pọ̀ mọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin tí Nàìjíríà. [2][3]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Samuel Ahmadu, Sevilla hand Toni Payne contract extension until 2021, Goal, 18 June 2019. Accessed 16 May 2020.
- ↑ 2.0 2.1 Sevilla striker Toni Payne wants to dump USA and play for Super Falcons of Nigeria, 7 March 2019. Accessed 15 May 2020.
- ↑ 3.0 3.1 Samuel Ahmadu, American-born Toni Payne awaits Fifa's clearance, Goal, 5 April 2019. Accessed 16 May 2020.