Jump to content

Tosin Jegede

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Tosin Jegede tí wọ́n bí lọ́dún 1980 [1] jẹ́ gbajúmọ̀ ọ̀dọ́mọdé obìnrin olórin ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìgbésí ayé rẹ̀ àti iṣẹ́ orin rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lọ́dún 1986 ló gbé àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde ti o pè ní Children Arise. Ọmọ ọdún márùn-ún ló wà ní àkókò náà. Lẹ́yìn náà ó gbé àwo orin méjì mìíràn jáde, tí ó pè ní: Leaders of Africa àti Children of Africa lọ́dún 1989 àti 1992.[2] Lẹ́yìn èyí, ó gbọ̀nà òkè òkun lọ láti lọ kàwé sì í. Ó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ Business Decision and Analysis láti University of Bristol, ní London, ó ṣíṣe fún ìgbà díẹ̀ ni United Kingdom kí ó tó padà sí Nàìjíríà lọ́dún 2008.[3][4][5][6][7]

Ìyá Tósìn kú lọ́dún 2012. Lẹ́yìn náà, ó dá ilé isẹ afowóṣàánú silẹ tí ó pè ní One Book One Child, ó ń fi èyí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọdé Nàìjíríà.[2]

Àṣàyàn àwo àwo orin rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Children Arise (1985)
  • Leaders of Africa (1989)
  • Children of Africa (1992)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]