Ugali ní Kenya
Ugali ní orílẹ̀-èdè Kenya
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nínú àṣà àwọn Luhya, ó jẹ́ oúnjẹ tó ṣe pàtàkì púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àṣà ìgbéyàwó àwọn Luhya; obusuma èyí tí a ṣe láti ara jéró (tí a mọ̀ sí obusuma bwo bule) wọ́n kà á kún oúnjẹ tó ṣe kókó tí ó gbọ́dọ̀ wà ní orí tábìlì ìyàwó. A tún le se Obusuma láti ara sorzghum tàbí ẹ̀gẹ́ (obusuma bwo 'muoko). Wọ́n sáábà máa ń jẹ Obusuma pẹ̀lú tsimboka, tàbí etsifwa, eliani (ẹ̀fọ́), inyama (ẹran), inyeni (ẹja), thimena (whitebait) tàbí omrere (jute leaves). Fún àwọn àlejò pàtàkì, wọ́n sáábà máa ń gbé e fún wọn pẹ̀lú ingokho (ẹran ṣíkíìnì).
Wọ́n máa ń pèsè Ugali láti ara àgbàdo funfun tí a lọ̀ tó fi ara jọ bí a ṣe máa ń se tamales láti ara àgbàdo aláwọ̀ yẹ́lò ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ní àwọn ilé kọ̀ọ̀kan ugali jẹ́ oúnjẹ tí ó wọ́pọ̀ jùlọ nínú àwọn oúnjẹ tí wọ́n máa ń jẹ pẹ̀lú ẹ̀fọ́ tàbí ẹran gẹ́gẹ́ bíi alábàárìn. Ní ilé àwọn gbajúmọ̀, tàbí níbi àwọn ayẹyẹ ọlọ́lá, ugali ti kó ipa pàtàki gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ tí wọ́n á jẹ pẹ̀lú ẹ̀fọ́, ẹran, àti àwọn oríṣi ọbẹ̀ mìíràn. Ó fi ara jọ ànàmọ́ gígé tí wọ́n máa ń jẹ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.