Ugbo Kingdom
Ìlú Ùgbò jẹ́ ìlú ní ìjọba ìbílè Ìlàjẹ ní Ìpìnlẹ̀ Oǹdó, gúúsù-Iwọ̀-Oòrùn Nàìjíríà. Àwọn apẹja ló pọ̀ jù lára àwọn ará Ìjọba Ùgbò. [1]
Ìṣàkóso
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìjọba Ùgbò ní àwọn ìdámẹ́rin mẹ́rìndínlógún ó sì ní olórí nípasẹ̀ àwọn olóyè tí a yàn gẹ́gẹ́ bíi àṣà àti ìṣe wọn. Ọkàn lára àwọn olórí ilé ẹgbẹ́ náà tí wọn ń pè ní Olóyè Gbógunró ló ń gbé èwe oyé náà sórí Ọba tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ́jọ́ ìjoyè.
Geography
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ilẹ̀ Ùgbò wà ní etí i òkun àti Gúúsù-Iwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ládùúgbò àwọn ọmọ Ugbo ni awon Ikales, Itshekiris, Ijaws, Apois, Ijebus, and Edos. Ìlú Ùgbò wà ní etí òkun ti ẹkún Iwọ̀-òórùn Gúúsù ti Nàìjíríà ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó lọ́wọ́lọ́wọ́. Gbogbo agbègbè náà ni àwọn àmì-ilẹ̀ etí òkun, àwọn ṣiṣan, àwọn odò àti àwọn adágún omi. Ó wà láàárín agbègbè ìwọ-oòrùn ti Niger Delta bẹ̀rẹ̀ láti Bight of Benin ní Ìlà-oòrùn, àti gbogbo ọ̀nà láti Oghoye nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ṣiṣan ilẹ̀ Ùgbò sí Abetobo.
Ilẹ̀ Ùgbò wà lórí gíga tí ó wà láàárín àwọn mítà 1.0 ati 1.5 lókè ìpele òkun. Ó wà ní gbangba bí kò ṣe sí òkè kankan ní àyíká.