Wòlíì Àgbà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Wòlíì Àgbà (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Ayọ̀ Ajéwọlé) jẹ́ òṣèré apanilẹ́rìn-ín àti olórin. Wọ́n bi ní ogúnjọ́ oṣù kọkànlá ní ìlú Ìbàdàn, ibẹ̀ ni ó sì ti ṣe ìgbà èwe rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.[1]

Ìgbà Èwe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ijeda ní ìlú Ìjẹ̀sà ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni ó ti wá, àmọ́ ìlú Ìbàdàn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ó dàgbà sí. Ìlú Ìbàdàn yìí náà ni ó ti lọ ilé-ìwé alákòóbẹ̀rẹ̀ àti onípele kejì. Ó tẹ̀ síwájú láti lọ ilẹ́-ẹ̀kọ́ gíga, Leed City University ní ìlú Ìbàdàn ni ó ti gboyè nínú Economics.

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2002 ni arákùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe eré apanilẹ́rìn-ín, nígbà náà kò tíì sí ẹ̀rọ ayárabíàṣá. Eré orí ìtàgé tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Fẹ́mi Ajéwọlé ṣe tí a mọ̀ sí Alfa Sule ni ó sọ wòlíì àgbà di ìlúmọ̀ọ́ká. Wọ́n sì jọ máa ń ṣe eré orí ìtàgé lóríṣirísi bí i ó ti gan pa, Orúkọ ńlá, Amos 3:3,Alfa Sule àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tí ẹ̀rọ ayárabíàṣá dé, wòlíì àgbà bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àwọn eré apanilẹ́rìn-ín pẹ̀lú Délé sórí Instagram And Facebook. Èyí sì mú kí òkìkí rẹ̀ kàn si. Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tí ó sì jẹ́ àwọn ẹ̀dá ìtàn bí í Pastor Johnson, ọmọ Ìbàdàn, bàbá Ìjọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. MemoNaija. "(Ayo Ajewole) Woli Agba Biography: Age, Background, Family, Awards And More". Memo Naija. Archived from the original on 2019-12-31. Retrieved 2019-12-31.