Wikipedia:Ẹ kú àbọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Ìkíni jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àṣà ìbílẹ̀ẹ Yorùbá. Ìwà ọmọlúwàbí ni kíkí' ni àti ìbọ̀wọ̀ f'ágbà. Ẹ̀wẹ̀wẹ̀, ọmọdé ní ń kọ́kọ́ kí àgbà nílẹ̀ yìí, àfojúdi ni fún ọmọdé tí ó rí àgbà tí kò k'ágbà.

Tótó ṣe bí òwe, àwọn àgbàlagbà ló ní wípé, "bí a bá ṣe ko 'ni; là á kí'ni, bí a bá ṣe kí' ni là á jẹ́'ni", èyí ń tọ́ka sí iha tí àwọn baba-ńláa wá kọ sí àṣà ìkíni ní ilẹ̀ẹ káàárọ̀-o-ò-jí-ire.

Báwo wá ni a ṣe ń kí'ni nílẹ̀ẹ Yoòbá?

"Kú" jẹ́ gbólóhùn tí ó pọn dandan bí a bá ń kí ènìyàn. Àmọ́, sàwáwù ẹni ni ẹni lè lo "kú" fún, "ẹ kú" ni ti àgbàlagbà tó ju'ni lọ. Bí a bá fẹ́ kí ìyá, bàbá tàbí ẹni tó ju' ni lọ, "ẹ kú..." ni a óò fi bẹ̀rẹ̀ ìkíni náà. Fún àpẹẹrẹ, "ẹ kú àbọ̀ bàbá", "ẹ kú iṣẹ́ ìyá ", ẹ káàbọ̀ ẹ̀gbọ́n". Bó ṣe ẹlẹgbẹ́ ẹni tàbí ẹni tí a jù lọ, "kú" ni atọ́ka, "kú àbọ̀ ", "kú àbọ̀ àbúrò" àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Alẹ́ = kú alẹ́ (káalẹ́). Oorun = kú oorun. --ỌMỌ YOÒBÁ (ọ̀rọ̀) 10:48, 29 Oṣù Kẹ̀sán 2018 (UTC)[reply]