Jump to content

Wikipedia:The Wikipedia Library/About

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Iyàrá ìkàwé Wikipédìà.

Nípa iyàrá ikàwé Wikipédíà\ Kà nípa iyàrá Ìkàwé Wikipédíà

Iyàrá Ìkàwé Wikipedia jẹ́ gbùn gbùn tí iṣẹ́ ìwádí ìmọ̀ ti ń wáyé, àyè tí àwọn oníṣẹ Wikipédíà ti lè ní ẹ̀tọ́ àti ànfàní sí àwọn orísun pàtàkì tí ó sì tún fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti fi ṣe iṣẹ́ wọn lọ́fẹ̀ẹ́, àti láti ṣèrànwọ́ nìpa lílo àwọn àǹfàní ńlá ǹlà náà láti gbòòrò ìwé ìmọ̀ ọ̀gẹ́ síwájú si. A dàníyàn láti sọ àwọn orísun náà di lọ́fẹ̀ẹ́, sọ́ di ìrọ̀rùn, láti fi mú ìbáṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn wá sáàrín àwùjọ lọ́nà tó bójúmu.

Àwọ tí ó ǹ ṣàmójútó Iyàrá ìkàwé Wikipedia ni: Jake Orlowitz, Nikkimaria, Sam Walton, Aaron Vasanth, àti Felix Nartey, pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ CoordinatorsWikimedia Foundation sì jẹ́ alágbàátẹrù rẹ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2013 gẹ́gẹ́ bí Individual Engagement Grant. A ń ṣiṣẹ́ lórí ṣàlàkalẹ̀ tó dá lórí àgbékalẹ̀-àwùjọ tó jẹ́ ojútáyé: a ń bójútó àwọn iṣẹ́ àkànṣe jàkè jádò gbogbo àgbáyé, tí a sì ń albójútó Wikipédíà lẹsẹ̀ kùkú láti ri wípé à wọn ìlú kọ̀ọ̀kan náà ní iyàrá ìkàwé lẹ́sẹ̀ kùkú tiwọn bákan náà. Ẹ lè kàn síwa lónìí bí ẹ bá fẹ́ dá iyàrá ìkàwé kakẹ̀ lédè abínibí tiyín náà tàbí bí ẹ bá fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ lórí ǹ kan kan!


Ẹ fi lẹ́tà yí ránṣẹ́ sí: wikipedialibrary@wikimedia.org Twitter: @WikiLibrary Facebook: The Wikipedia Library mailing list: Wikipedia-Library


O jẹ́ ìwúrí fún wa láti dajúkọ ìṣoro tó ga jùló tó n pagi dínà iṣẹ́ ìwádí àkọsílẹ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lónìí níbi: ìṣípayá àti ìmọ̀ ọ̀fẹ́. Ìṣòro tí ó dojú kọọ àwọn oníyàrá ìkàwé àti atẹ̀wéjáde ní báwo nivàwọn ẹnìyàn àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóọ́ ṣe ní ànfànì làti ṣàmúlọ̀ àwọn iṣẹ́ ìwádí tí wọ́n ti ṣe. Àmọ́ lọ́nìní, ó ti di ohun ìtàn nítorí ànfàní aláìlẹ́gbẹ́ tí àwọn ènìyàn nì sí iṣẹ́ ìwádìí lórí Wikipédíà lórí ayélujára. Èyí ni ó fiwá sí àyè ọ̀tọ̀ níbibtí ìbáṣepọ̀ ti mọ́yanlórí. Fúndí èyí, àwùjọ tí yóò tàkìtì lágbegbe yìí lójúde Wkioédíà yóò múra.

A fibàsìkò yí sọ fún àwọn òǹkàwé tí kò ní àǹfàní sí iṣẹ́ ìwádí tí kìí ṣọ̀fẹ́, Wikioédíàbtí mú ìrọ̀rùn dé bà ìpọ́njú yì. Lóọ́tọ́ gbogbo iṣẹ́ ìwádí kọ́ ló ṣẹérí lọ́fẹ̀ẹ́, àmọ́ ọ̀pọọ̀lọpọ̀ rẹ̀ ni a lè rí (tí a sì nígbàgbọ́ pé gbogbo rẹ̀ yóò dìrọ̀rùn láìpẹ́) bí kò bá wá jẹ́ gbogbo rẹ̀ ,díẹ̀ yóọ́ farahàn lórí Wikioédíà. Ìlàkàkà Wikipédíà ni yóò mú kí ìgbìyànjú àwọn iyàrá ìkàwé àti àwọn òntẹ̀wé jáde ó túbọ̀ farahàn tí yóò sì tún mú kí iṣẹ́ wọn gbòòrò síwájú si lọ́nà ọ̀tun.

Ìbéèrè kán tó ń kọ wá lóminú ní "báwni a ṣr lè rí àwọn àkọsílẹ̀ tó gbá múṣé kójọ sórí Wikioédíà tí yóò sì lè jékí àwọọn olùkàwé wa ó kè ma waá lóọ́rè kóòrè. Nígbà tó jẹ́ pé Wikipédì kìí ṣe ibùdó òpin iṣé ìwádí fún oníwàdí bí kò ṣe ìbẹ̀rẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tó lọ́ọ̀rìn rẹ̀. A fẹ̀ kí Wikipédìà ó jẹ́ àwùjọ pàtàkì kan tí yóọ́ jẹ́ àmù fún iṣẹ́ ìwádì àti títàn kálẹ̀ irúfẹ́ iṣẹ́ ìwádìí bẹ́ẹ̀ ní bi tí àwọnoníṣẹ́ iyàrá ìkàwé, akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́, àti àwọn òǹtẹ̀wé jáde yóò ti ma dá sí nípa fífi orísun àti ẹ̀bùn ọpọlọ wọn; Oẹ̀lú bí Wikioédíà ṣe ń léwájú pẹ̀lú ìwọlé-wọ̀de àwọn òǹkàwé lórí Wikipésía tí ó lé ní àádọ́ta mílíọ́nù ènìyàn lójúmọ́.

Ohun tí a gbé lọ́wọ́

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn àfojúsùn

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A ń fọwọ́sowọ́pọ̀ láti mú àwọn àfojúsùn márùún (5) yìí ṣẹ:

  1. Láti so àwọn oníṣẹ́ àti iyàrá ìkàwé agbègbè wọn pọ̀ kí wọ́n le ní àǹfàní sí orísun láì ní ìnira.
  2. Ìbá àwọn ilé ìwé ńlà ńlá dòwòpọ̀ làti lè jẹ́ kí àwọn oníṣẹ́ ní ẹ̀tọ́ sí iṣẹ́ àtẹ̀jáde olówó ńlá, àká(database), àti iyàrá ìkàwé.
  3. Láti fi ìbáṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn lélẹ̀ láàrín àwùjọ wa tó fi mọ́ àwọn oníṣẹ, iyàrá ìkàwé, alámòójútó iyàrá ìkàwé.
  4. Láti lè jẹ́ kí iṣẹ́ ìwádí àwọn oníṣẹ́ àti kí àwọn orísun ó lè rọrùn láti lò.
  5. Láti mú ìlọsíwájú tó gbòòrò bá ìmọ̀ ọ̀fẹ́ nínú ìmọ̀ ìwádí àti iṣẹ́ àtẹ̀jáde.


Àlàkalẹ̀ Ètò

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iyàrá ìkàwé Wikipedia fara mọ́ kí àwọn oníṣẹ́ ó ṣàwàrí orísun tí ó ti wà ní kíkọ tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ti nìfọwọ́-sowọ́pọ̀, wòn le loorísun tí ó gbówó lórí. Báyìí ni a ṣe ṣàlàkalẹ̀ rẹ̀:

Ọlọ́ka-ò-jọ̀kan àwọn olùtẹ̀wé yóò forúkọ sílẹ̀ opẹ̀lú wa.

A ó lo ọ̀nà ìwádí àká(database) làti fi iṣẹ́ ìwádí múlẹ̀ tí a ó sì bèèrè fún ọrẹ làti ọ̀dọ̀ wọn. A ó pèsè àyè tí ó lé lọgọ́ta(60) olùbádòwò lọ́fẹ̀ẹ́. HighBeam, EBSCO, Elsevier, JSTOR, and Cochrane, àti àwọn mìíràn. Elẹéyìí yóò mú ànfàní tààrà wá tí ó lè jẹ́ kí ìbádòwòpọ̀ olùbádòwòpọọ̀ kọọ̀ọ̀kan ó tó àìmọye mílíọ́nù Dọ́là.

Ẹni tó jẹ́ olùbẹ̀wò olóye tàbí onímọ̀ Wkipedia. Gẹ́gẹ́ bí Peter Suber níbi iṣẹ́ àkànṣe (Harvard Open Access project) ṣe dábàá, awa bá àwọn ilé ìwé Fásitì sọ̀rọ̀ tàbí àwón ilé ẹ̀kọ́ kéréje kéréje láti pè wọ́n kí yan àwọn oníṣẹ́ Wikipédíà, olùbẹ̀wò olóye tàbí onímọ̀ tí wọn kìí sanwó fún,àwọn ará nínú iṣẹ́ ìwádí tí wọn ní òye kíkún nípa iyàrá ìkàwé. Èyí ni yóò sọ ìṣòro ìbáṣepọ̀ wá láàrín àwà àti àwọ̀n iyàrá ìkàwé fásitì di fúfúyẹ́. Ṣebí ó yẹ kí gbogbo fásitì kọ̀ọ̀kan lágbáyé ó ní olùbẹ̀wò olóye tàbí onímọ̀ tí yóò jẹ́ òṣìṣẹ́?Wikipédíà tí yóò ma ṣojú wọn ní?
Ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn FásitìA ń fojúsun oríṣiríṣi àyè ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó sì so àwọn iyàrá ìkàwé Wikipédíà pọ̀ tààrà mọ́ à ní iyàrá ìkàwé wọn; bí àpẹẹrẹ a ti wọ kùúnkùdun pẹ̀lú àjọṣepọ̀ MIT. Eléyìí jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì láti gbé orísun wọ̀n wò bóyá ó gbéwọ̀n, bì ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó làwá lóògùn púpọ̀ láti gbe gbọ̀nọ̀ tó bófin mu.
Àtúnṣe kójọpọ̀ iyàrá ìkàwé. Kí á lè so pọ̀ mọ́ ogunlọ́gọ̀ àwọn orísun àti àká(database) tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ kí ó le ran àwọn oníṣẹ́ wikipédíà lọ́wọ́ láti jẹ́ kí iṣẹ́ ìwádí wọ́n le wà lójú kan náà. Ìdí nìyí tí a fi dòwòpọ̀ mọ́ OCLC, a fọwọ́-sowọ́pọ̀ pẹ̀lú iyàrá ìkàwé tí ó tóbi jùlọ ní gbogbo àgbáyé óláti lè jẹ́ kí iṣẹ́ àkànṣe iyàrá ìkàwé ó rọrùn láti ṣàwárí onírúurú ìwé, ìwé ìjábọ̀ ìwádí ìmọ̀(journals) àti àwọn ákójọpọ̀ ìwé orí ayélu-jára tí wọn jẹ́ ọ́fẹ́ àtièyí tí kìí ṣe ọ̀fẹ́ nírọ̀rùn.
Kíkún àwọn oníṣẹ́ ìwádí Wikipédíà lápá. A ní àwọn akínkanjú àti ọlọ́pọlọ pípé tí wọ́n ń ṣàkójọ ìwádí ìmọ̀, ań kún wọn lápá nípa ìtọ́ka sí, ìṣe pàṣípàrọ̀ orísun, àti iṣẹ́ àkànṣe iyàrá ìkàwé Wikipédíà. Ẹ́ jẹ́ kí á túbọ̀ fọwọsowọ́pọ̀ kí á sì kún wọn lọ́wọ̀ láti kí á lè jẹ́ àǹfàní wọn nípa gbígbé Gbòǹgbò Ìwádík, Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbéèrè tàbí Ọ́nà ìtọ pinpin. Kí ló dé tí àwọn ògbóǹtagì nínú ìkàwé ya wákàtí kan sọ́tọ̀ nínú ọ̀sẹ̀ láti fi ran oníṣẹ́ Wikioédíà lọ́wọ́ kí ìwé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ó lè gbòòrò siwájú si nípa iṣẹ́ ìwádìí?
Ṣíṣẹ̀dá àwọn irinṣẹ́ tó lè ranṣẹ́ ìwádí lọ́wọ́.

Mímú ìdàgbà-sókè bá ìmọ̀ ẹ̀rọ láti sopọ̀ lọ́gán pẹ̀lú àwọn orísun tó ti wà nílẹ̀ lórí pèpéle ìwádí iyàrá iìkàwé, àwọn àtòjọ orúkọ, àti àwọn websites tí a fòǹtẹ̀ lù yóò mú kí ṣíṣàwárí ìmọ̀ ìwádí ó rọrùn.

Síṣàfih àǹfàní ọ́fẹ́. Dídarí àwọn ètò tí ó Piloting programs that ṣàfihàn nígbà tí àwọn irísun bá ṣé ṣàwárí lọ́fẹ̀ẹ́, tí ó sì ṣàkójọpọ̀ àwọn orísun sójú kan gẹ́gẹ́ bí àmù tàbí àká kan tí a lè tọ́jú àwọn àtẹ̀jáde iṣẹ́ ìwádí sí.
Sísopọ̀ mọ́ àwọn iyàrá ìkàwé: Níoa àwọn ètò bí:Wikipedia fẹ́ràn àwọn iyàrá ìkàwé àti àgbékalẹ̀ GLAM , ẹ jẹ́ ká ran ilé ẹ̀kọ́ lóriṣirísi lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàgbékalẹ̀ àwọn ètò àtibkí wọ́n lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn àkòrí tí yóò so àwọn oníṣẹ́ pọ̀ mọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́, mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ náà àti iṣẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà.


A fẹ́ kí o dara pọ̀ láti kópa nínú iṣẹ́ àkànṣe tí ó ń lọ! Wá fọwọ́-sowọ́pọ̀ mọ́ àwọn oníṣẹ́ (Wikipedians) láti lè ṣe iṣẹ́ ìwádìí ìmọ̀. Ogunlọ́gọ̀ ọ̀nà ni o lè gbà láti kópa bí: Ṣíṣàbójútó iṣẹ́ àknàṣe, ìfilọ̀ tàbí ìkọ́ni níké ìwé gbogbo, jíjé amùgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ onímọ̀ ìwádìí, elétò àwùjọ, ṣíṣèràlọ́wọ́ fún iyàrá ìkàwé, onímọ̀ àmúṣe-múlò ìmọ̀ ẹ̀rọ, oníṣẹ́ àwòrán-- a óò wá ipò tí ó ṣe dédé rẹ́ fún ọ, Dara pọ̀ lónìí.

Dara pọ̀ fún àǹfàní tó péye

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀pọ̀ ọrẹ àtinúwá la ti rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn olùbá-dòwòpọ̀ wa, tí ó fún wa ní ẹgbẹgbẹ̀rún àǹfàní láti lówó lápò. Ọ̀pọ̀ ṣì ìrànwọ́ sì tún bọ̀ lẹ́yìn. Dara pọ̀ láti yan èyí tí o bá fẹ́ nínún Àṣàyàn iyàrá ìkàwé!


Ka àwọn Àtẹ̀jíṣẹ́ Oníròyìn

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Máa gba àwọn ìkéde nípa ètò ẹ̀dáwó ọ̀fẹ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nípa ìfijíṣẹ́ àwọn ìwé àti ẹ̀rún(Books and Bytes).


Di olùbẹ̀wò onímọ̀ Wikioédíà

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sé o fẹ́ ní ẹ̀tọ́ sí gbogbo àkójọpọ̀ ìwé ìwádí ìmọ̀ Fásitì?


Di Alámójútó iyàrá Ìkàwé

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn TWL ń ṣiṣẹ́ gidi nítorí àwọn olùfarajì àtàtà tí ọn wà nínú àwùjọ wa. Olè ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú ṣiṣàmójútó àwọn iṣẹ́ àkàṣe àwùọ wa:

Dara pọ̀ láti lè bójútó iyàrá ìkàwé, àpò,ìdòwòpọ̀,ìwádí ìmọ̀,mẹ́tríkì,fásitì, tàbí a lábójútó ìmọ̀ ẹ̀rọ


Àwọn ènìyàn iyàrá ìkàwé Wikipédíà

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wikipedia:TWL/Ṣàfihàn

Wikipedia:Iyàrá ìkàwé Wikipédíà/Àwọn ènìyàn

Àwọn ọ̀rọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n

[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Quote Àdàkọ:Rquote Àdàkọ:Rquote Àdàkọ:Rquote Àdàkọ:Quote