Èdè Abínibí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ede Abinibi

  1. N ò réni tó fèdè elédè ronú rí
  2. Àfi ti wa
  3. E wo gbogbo àwon ìlú ńlá
  4. Àwon ìlú kàǹkà-kàǹkà
  5. Ní gbogb ayé yíká kódà tée délèe Kùsà 5
  6. Irú èdè wo ni wón fi ń kómo?̣
  7. Èdèè-bílèe wón ni wón ń lo
  8. Wón sì ti digi osè, wón ti dàràbà
  9. E wAmerika, e wo Rósíà, ké e wáá wòlú Èèbó
  10. E ó ri pédèe won ni won fi ń ronú 10
  11. Ni wón fi tóbi
  12. Sùgbón bíi tèmi tìre kó
  13. Ká tóó pèrò ní Yoòbá
  14. Ká tóó yí i sÉèbó
  15. Gbogbo tepotiyọ̀ inú ọ̀rọ̀ 15
  16. Ti gbákúla
  17. Bóo la se lé fèdè elédè ronú jinlè
  18. Wón fomo odún méta sílé èkó
  19. Pé ó máa ko Faransé, ó máa kÉèbó
  20. Ó se, omó gbó Faransé díè, ó gbÉèbó díè 20
  21. Torí pó jómo-on Yoòbà
  22. Ó fi Yoòbá sàbùlàa won
  23. Òró di sákálá sokolo sòkòlò sákálá
  24. Ó ń relé kò délé
  25. Ó ń roko kò délé 25
  26. Àfóòfótán ojú a sì dásòólè
  27. Àdàlú èdè a fa hówùhówù dání
  28. Omo ò ní í lè dánú olóódoó rò
  29. Ohun a bá so fún un náà ní ó so padà bí ayékòótó
  30. Omo a délé 30
  31. A ní ‘Dádì, Yò bíládù fuù’
  32. Kò kúkú gbó, kò yé e páà
  33. Wón ti ní bí wón se ń so
  34. Séni tó se un tí ò dáa nù un
  35. Omo o sì mò péyìí yo bàbá òun sílè 35
  36. Bákan náà ni gbogbo èèyàn sorí lójúu won
  37. Won a kéyelé pò mádìye bó se wu wón
  38. Won a kó terú tomo tìwòfà pò
  39. Sé kò kúkú sówò nílúu won
  40. Ko sagba lómo ajá, àkóbí ajá, abíkéyìn béè 40
  41. N náà ni awon omo naa yoo se
  42. Ajísebí Èkó, Èkó ní í kúú sí
  43. Èyí tí ò yé won
  44. Po jèyí tó yé won lo
  45. N ò kúkú ráwon omo báwí ní tiwon 45
  46. Ohun a fi kó won ni wón gbà
  47. Wón ní amúkùn-ún, erù ré wó
  48. Ó ni e ò wòsàlè
  49. Mo ń bá ògá ilé ìwé pàtàkì kan
  50. Fòrò jomitoro òrò ńjó kan 50
  51. Ògá yìí kàwé a ò rírú e rì
  52. Ìwé tó kà tó bàmbà bamba
  53. Mo ní ‘Ògá, e bá n parí òwe yìí
  54. Edákun e fiyè dénú’
  55. Mo ní 55
  56. ‘Òní, àgbé pokó mó
  57. Òla, àgbé pokó mo’
  58. Wéré, Ogá ti kó sí mi lénu
  59. Ó lóun ti mò yóókù
  60. Kí n máà déènà penu 60
  61. Ó ní
  62. ‘Lótùn-ún-ùn-la, àgbè á gbókó ńbi ó fi pamó sí
  63. À bé è réèmò, èyàn èèyàn-àn mi
  64. Èèmò lu kutu pébé tan
  65. Ó tún lu pèbé pèlú è 65
  66. Àgbàlagbà ló se báun parí òwe
  67. Ta ni ò mò péparí òwe ùn ni pé
  68. Ojo tókó ó pàgbè mó ń bò
  69. Táriwó á so
  70. E jòwó, e má se fojú òpè wògá 70
  71. Òpò ló ń pòwè Láwúwo
  72. Tó se bí gidi làwón ń se
  73. Ení jìn sí kòtò
  74. Ló dá lésè
  75. Ení forí tì í dópìn-in 75
  76. Àfàìmò kó mó daláàrúù
  77. Nnkan àrà gbáà
  78. Omo Oòdùa ò fálà fédèe rè mó
  79. Èdè tó ládùn tó yìí
  80. Le fowó òsì tì dànù 80
  81. Níbi orirí ti ń sunkún ilé
  82. Tówìwí ń sunkún àtibò oko
  83. Ibè le ti ta won-nle
  84. Tèdè elédè
  85. A wí tán 85
  86. Wón lédèe wa ò kún tó
  87. Wón lósàn tó wò tí ò dùn
  88. Bí ò kúkú wò, ó tó
  89. Kí làǹfààni olówó tí kò níyì?
  90. E sé, a dúpé 90
  91. Ó tán n bó kù?
  92. E máa pónró ńbíbà
  93. E máa so tiyín di sáré pegbé
  94. Ilé eni lèmí mò pónà pèkun sí
  95. Wón ní sòkòtòo Yoòbà ò balè 95
  96. Wón ní bá a gbá a létí
  97. Tá a kàn án ńkòó
  98. Tinú è ni yóò se
  99. E kú isé
  100. Èyin ologbón, èyin òmòràn 100
  101. ‘Òmòràn tí í mo tinú ìgbín nínú ìkarahun’
  102. Wón ní bá a bá ń fi Yoòbá kékòó
  103. A ó ti se pògòrò òrò tí ń be ní sáyéǹsì?
  104. A ó ti se pojíbírà àti joméńtìrì?
  105. A ó ti se poósínjìn? 105
  106. A ó ti pe kábóńdàosàìdì?
  107. Ti pai-áárú-sukuàdì ń kó?
  108. Sùgbón gégé bí mo se so sáájú
  109. Èyí tí ò yée yín
  110. Pò jèyí tó yée yín lo 110
  111. Tá ni ò mobi tóbìn-in fi ń tò?
  112. Tée ní ó kòdí sígbó
  113. Ó joun pé ò mohun tédè ń jé
  114. Ló jé e móon sò yú-ùn
  115. Àìmòkan, àìmòkàn 115
  116. Ló kúkú n báayín-ín jà, o jàre
  117. E kò mò pé
  118. Bí gbogbo omo káàárò o ò jíbí?
  119. Bá pé báyìí la ó máa pé nǹkan-an wa
  120. Òyìyè tí ń yè é ò sí 120
  121. Báyìí là ń se ńlèe wa
  122. Èèwò ibòmín-ìn
  123. Bá a bá so pé
  124. Báyìí la ó mó on poósínjìn
  125. Tá a sì fún kábó-ńdà-osàìdì lóóko 125
  126. Tá ni yóò ya sùtì ètè
  127. Tí ó so pé Sàngó ò ponmo-on re?
  128. E tilè so pé Yoòbá ò kún tó
  129. Ǹjé èyín mò pé
  130. Se lèdèé mó-on ń dàgbàá sí i 130
  131. Ó dàbí aso
  132. Tokan gbó tá a mú mí-ìn
  133. Èyin ti lo sápótí ìsúra
  134. Ké e wá à won èdè té e ti pa tì
  135. Ké e mú nínú-un won 135
  136. E fi fáwon nǹkan wònyí lóóko tuntun
  137. Bá a tilè sì ta á bó tì
  138. Kì ló so pé á mó lo sédè mí-ìn
  139. Loo yá oóko tá a ó máa pohun tuntun
  140. Púpò nínú Èèbó té è ń wò un 140
  141. Ara èdèe won kúkú kó nísèǹbáyé
  142. Mímú ni wọ́n mú láti ara èdèe Látín-ìn-nì, Gíríìkì àti Hébéérù
  143. Kò sóròò Matimátíìkì kankan ni Èèbó
  144. Tí kì í sèdèe Lárúbáwá ló ti wa 145
  145. Tá ni Lárúbáwá wáá sun mó jù nínú àwa àti Èèbó?
  146. Bóo ni tèmi tìre ti wáá jé
  147. Omo ìyáà mi?
  148. Ohun tí ò sì yée yín ni pé 150
  149. Òpò èdè ló sáà ti wo tiwa
  150. Tí kò sì se wá ni háà!
  151. Bóyá o ti gbàgbé àwon òrò
  152. Bí ‘àlàáfíà’, ‘àlùbáríkà’ àti ‘Dàńsíkí’
  153. Tí wón tinú Haúsá di ti wa 155
  154. N ò sèsè lè so tÈèbó
  155. Ìyún-ùn pò bíi kàasíǹkan
  156. Kí ló dé tá a tepele mó yìí
  157. Ká fóhun gbogbo lórúko
  158. Kó di ti wa?
  159. Bóya ògòrò èdè
  160. Tó wà ńlèe wa
  161. Ló ń ko yín lóminú
  162. Pé bí Haúsá bá ń fi ti è kómo
  163. Tí Íbò ń se bákan náà 165
  164. Ìgbà wo lòròo wa
  165. Ò ní í dàbí ilé gígaa Bábéélì?
  166. Ìdáhùn síyún-ùn-ùn ò le, òrée wa
  167. Bóko ò jìnà, ilá kó tì
  168. Orin tí kò sòro í dá 170
  169. Kì í sòro í gbè
  170. Bá a bá so pé ìsá ǹsalùbó
  171. Peerepe sì lègbèe rè
  172. Ìjà ò sí ńsóòṣì
  173. Sàdúrà n sàmín ni 175
  174. Bí Íbò bá ń fèdè abínibí kómo
  175. A ó tún rò ó kó dákun fiyè dénú
  176. Kó fòkan nínú Haúsá tàbí Yoòbá
  177. Kómo náà pèlú
  178. Bí Yoòbá bá ń lo tirè 180
  179. A óò ní kó fi òkan
  180. Nínú Haúsá tàbí Íbò kún un
  181. Bá Haúsá náà sì ni
  182. Yóò fi òkan nínúun
  183. Yoòbá tàbí Íbò tì í 185
  184. Kò ní í pé, kò ní í jìnà
  185. Tá a ó fi máa gbóraa wa
  186. Lágbòóyé
  187. Ìyún-un ni pé
  188. A fewé àdúgbò kàgbo omo 190
  189. Gbogbo rè a sì kú dùn-ún-ùn
  190. Bí ojú tó ti kékeé fọ
  191. Sé tójú bá ti kékeé fó
  192. Se ní í kú mòràn-ìn moran-in
  193. Òròo wa a sì dayò 195
  194. À sì fopé fÓlúwa
  195. A kúkú mọ̀ pédèe wa è é jé béè
  196. Àwa la tajà eèpè
  197. Tá a ń gbowó òkúta
  198. A ko fìlà fún wèrè 200
  199. Wèrè sì féé lo fìlà gbó
  200. N ò kúkú bá won wí
  201. Àbí ta ni a ó gbókó fún
  202. Tí ò ní í roko sódò ara è
  203. Àsá ló sì ń mádìyee wa sòle 205
  204. Òjò ló sì ń pàyèrèpè lówó
  205. Tó fi deni àkolù
  206. Kì í sì í règà títí
  207. Kómó inú rè má gbòn lebelebe
  208. Yóò balè yóò balè 210
  209. Ni labalaba fi ń wogbóó lo
  210. Bí wón se ń dìrò mápáá tó
  211. Apáa won ò kúkú ní í kápá
  212. Bí wón dìrò mọ́gi osè
  213. Apáa won ò ní í kósè 215
  214. Òjò iwájú ì í pahun
  215. Gbogbo epe tí a bá se lu Onítibí
  216. Ara ní í fi í san
  217. Ológbò o ní í fìgbà kan kúkú ìwò sílè
  218. Ìjímèrè ò ní í bá won kúkú òwòowòó 220
  219. Èdèe Yorùbá ò ní í kú mó wa lójú
  220. E dákun, e sàmín è.