Jump to content

Ìyanṣẹ́-lódì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Female tailors on strike, New York City, February 1910.

Ìyanṣẹ́-lódì,[1] tabí Ìfẹ̀hónú hàn àwọn òṣìṣẹ́ , tabí Ìdágunlá, jẹ́ ìyanṣẹ́ ní pọ̀sìn tabí ìdáṣẹ́ dúró àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjọ́ wọn. Ìyanṣẹ́-lódì sábà ma ń wáyé láti fi ṣe ìfẹ̀hónú-hàn àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ tako ìwà, ìgbésẹ̀ tàbí àṣẹ tí kò tẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ lọ́rùn tí àwọn aláṣẹ ilé-iṣẹ́ kan yálà ti Ìjọba tàbí àdáni gbé kalẹ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ láti tẹ̀lé láì mú ìtàpórógan dání.[2][3]

Ìgbésẹ̀ ìlo Ìyanṣẹ́-lódì bẹ̀rẹ̀ sí ní di irinṣẹ́ ìfẹ̀hónú-hàn lágbàyé nígbà tí ìdàgbà-sókè bẹ̀dẹ̀ sí ń dé sí àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá ńlá, pàá pàá jùlọ àwọn ilé-iṣẹ́ ìwakùsà. Lọ́pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè nígbà náá fòfin de Ìyanṣẹ́-lódì àwọn òṣìṣẹ́ nítorí wọ́n rí Ìyanṣẹ́-lódì yí gẹ́gẹ́ bi ohun àìtọ́ sí étò ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè wọn, àti nítorí wípé ìjọba tàbí àwọn onílé iṣẹ́ aládàáni ní agbára ju àwọn òṣìṣẹ́ lọ. Díẹ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ funfun ló fọ́wọ́ sí lílo Ìyanṣẹ́-lódì àwọn òṣìṣẹ́ láti fi jìjà-n-gbara lọ́wọ́ ìfipá múni ṣe iṣẹ́ àwọn oníṣẹ́ gbogbo ní ìparí ọ̀rùndú Mọ́kàndínlógún (19th or early 20th centuries).

Ìwúlò Ìyanṣẹ́-lódì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn òṣìṣẹ́ ma ń lo Ìyanṣẹ́-lódì láti fi yí àṣẹ àti ìpinu àwọn agbani-síṣẹ́ tabí ìjọba padà lórí ìgbésẹ̀ tàbí àṣẹ tí wọ́n bá pa tí kò sì bá àwọn òṣìṣẹ́ lára mu. Lópọ̀ ìgbà, wón ma ń lo Ìyanṣẹ́-lódì láti fi ba ìṣèjọba aláṣẹ tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú tó wà lórí àléfà lọ́wọ́ jẹ́, bí ìpinu àti ìgbésẹ̀ ìṣèjọba bẹ́ẹ̀ bá tako ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.

Àwọn àpẹẹrẹ Ìyanṣẹ́-lódì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Ìyanṣẹ́-lódì apapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ASSU[4][5]
  2. Ìyanṣẹ́-lódì apapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn oníṣẹ́-elépo rọ̀bìti NUPENG[6][7]
  3. Ìyanṣẹ́-lódì apapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn oníṣẹ́ elétò ìlera ti NMA àti àwọn mìíràn.[8][9]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Strikes—The Law and the Institutionalization of Labour Protest in Nigeria on JSTOR". JSTOR. Retrieved 2020-06-11. 
  2. "Nigeria workers strike fit no hold today". BBC News Pidgin. 2019-10-16. Retrieved 2020-06-11. 
  3. "Strike - industrial relations". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2020-06-11. 
  4. "ASUU Strike: Federal Government Threatens to Sue Lecturers". Nigerian Scholars. 2020-06-01. Retrieved 2020-06-11. 
  5. "ASUU strike: An endless phenomenon? (2) – Punch Newspapers". Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria. Retrieved 2020-06-11. 
  6. "Ẹda pamosi". The Pointer News Online. 2014-12-14. Archived from the original on 2020-06-11. Retrieved 2020-06-11.  Text ", NUPENG May Begin Strike Today" ignored (help)
  7. Young, Victor (2020-05-05). "NUPENG, PENGASSAN threaten strike over arbitrary sack in oil sector". Vanguard News. Retrieved 2020-06-11. 
  8. "The political economy of doctors' strikes in Nigeria: A Marxist interpretation". Social Science & Medicine 22 (4): 467–477. 1986-01-01. doi:10.1016/0277-9536(86)90051-1. ISSN 0277-9536. https://www.sciencedirect.com/science/article/abs/pii/0277953686900511. Retrieved 2020-06-11. 
  9. "BREAKING: Lagos doctors end sit-at-home as NMA orders resumption". Healthwise. 2020-05-21. Retrieved 2020-06-11.