Ẹ̀gbá Owódé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Egba Owode

Oludare Olajubu

Babatunde Agiri

Ìwé Àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá tí Olóyè Olúdáre Ọlájubù jẹ́ Olóòtu, Ojú-iwé 1-11, Ikẹja; Longman Nigeria Limited, 1975.

Babátundé Agírí. Gẹ́gẹ́ bí a ti ńní ilẹ̀ ní ẹkùn Ẹ̀gbá Owódé; Ojú-iwé 113-119.

Agbègbè kọ̀ọ̀kan ni ó ní òfin àti àṣà nipa bí ènìyàn ṣe lè ní ilẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ tàbí fún ìgbà pípẹ́. Ní àwọn àgbègbè tí ọ̀làjú ti gòkè ní gbogbo àgbáyé, ilẹ̀ nínú ṣe pàtàkì fún àǹfàní iṣẹ́ẹ jíjẹ, mímu àti òwò nìkan. Ọ̀rọ̀ òṣèlú kò ṣe dandan lóríi rẹ̀ bíkọ̀ṣe nínú àwọn ọ̀ràn tí ó da ìlú méjì pọ̀.

Láti ilẹ̀ wá láàrín àwọn Yorùbá, ilẹ̀ nínú ṣe pàtàkì fún àǹfàní jíjẹ, mímú àti ti òwò. Láti kọ́lé àti láti ṣe oko ni ó ńmú kí gbogbo ènìyàn ní ìfẹ́ láti ní ilẹ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ ni kókó iṣẹ́ẹ wa, àwọn olóyè tàbí àwọn ọba ìlú tí wọn ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lábẹ́ ìtọ́júu wọn máa ńní ilẹ̀ tó pọ̀ ní ikáwọ́ọ wọn ju ẹlòmíràn tí ẹbíi rẹ̀ kéré. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tó wà lábẹ́ àṣẹ olóyè kan, tí wọ́n sì ńṣiṣẹ́ sìn í ti pọ̀ tó ni iyì àti ẹ̀yẹẹ rẹ̀ ṣe máa pọ̀ tó láàrín ẹgbẹ́ àti ìlú. Èyí ni ó mú ọ̀rọ̀ àwọn àgbà kan wá tí o sọ pé, ‘Ohun tó wunni ní ńpọ̀ nínú ọrọ̀ ẹni, ológún ẹrú kú, aṣọ ọ rẹ̀ jẹ́ ọkan.” Ọ̀nà tí ìjòyè yìí fi lè di aláṣẹ lórí àwọn irú ènìyàn wọ̀nyí ni nípa fífi ilẹ̀ fún àwọn ẹbí tàbí ìdílée rẹ̀, ìbátan tàbí àlejò fún ọ̀gbìn ṣíṣe àti àwọn nǹkan míràn gbogbo, àti nípa pínpín oriṣiriṣi ẹ̀bún lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Lílo ilẹ̀ tí a tọrọ yìí lè jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ tàbí fífún láyéláyé. Fún ìdí èyí, a ní láti rí i pé kì í ṣe fún iyì láàrín ẹgbẹ́ tàbí ìlú nìkan ni ó mú kí àwọn ìdílé olóyè kan máa ní ilẹ̀ tó pọ̀, ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ọ̀nà láti pín nǹkan jíjẹ, mímú àti ti òwò tí ó wọ́n eyíyìí ni ilẹ̀, ní ọ̀nà ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ orìíṣiríṣi ènìyàn tí ó wà ní ìlú tàbí abúlé. Nítorí náà, bí a bá wò ó láti ìhín lọ, ó ṣe é ṣe kí a sọ̀rọ̀ ilẹ̀ níní láàrín àwọn Yorùbá láti ipa jíjẹ, mímu àti ti òwò. Ṣùgbọ́n a ó mẹ́nu ba díẹ̀ nínú ètò ìlú ṣíṣe àti ẹgbẹ́ kíkó tí ó bá jẹ mọ́ tí ilẹ̀ nínú. ...