Ọjọ́ Ajé
Ọjọ́ ajé jẹ ọjọ́ tí ó wà láàrin ọjọ́ àìkú àti ọjọ́ ìṣẹ́gun.[1] Gégé bí àjọ International Organization for Standardization's ISO 8601 se sọ, ọjọ́ ajé ni ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀sẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí ó ka ọjọ́ àìkú sí ọjọ́ àkókò inú ọ̀sẹ̀ sì ka ọjọ́ ajé sí ọjọ́ kejì inú ọ̀sẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ni ó sọ ọjọ́ ajé ní orúkọ tẹ̀lé òṣùpá.[2]
Ipò láàrin ọ̀sẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ayé àtijó, ọ̀sẹ̀ àwọn Gíríìkì àti Róòmù bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọjọ́ àìkú(dies solis), tí ọjọ́ ajé sì jẹ́ ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀(dies lunae). Bẹ́ẹ̀ tún ni, ní ariwa America, wón ka ọjọ́ àìkú sí ọjọ́ àkọ́kọ́ inú ọ̀sẹ̀. Ṣùgbọ́n
International Organization for Standardization fi ọjọ́ ajé sí ipò àkọ́kọ́ nínú ọ̀sẹ̀ ní ISO 8601. Àwọn ará China ma ń pe ọjọ́ ajé ní xīngqīyī (星期一) èyí tí ó túmọ̀ sí "ọjọ́ àkọ́kọ́ ọ̀sẹ̀".
Ìbọ̀wọ̀ àwọn ẹṣin fún ọjọ́ ajé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹ̀sìn Kristẹni, islam àti Judaism ka ọjọ́ ajé sí ọjọ́ tí ó wà fún àwẹ̀. Àwọn Hadith kọ̀kan wípé ọjọ́ ajé jẹ́ ọjọ́ tí wón bí Muhammadu, ọjọ́ ajé ṣì ní ọjọ́ tí ó rí ìṣípayá rẹ̀ àkọ́kọ́, èyí tí ó padà di Quran.
Àwọn Ìtókasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Monday Meaning". Cambridge Dictionary.
- ↑ "monday". Online Etymology Dictionary.
Àwọn ọjọ́ ọ̀sẹ̀ |
---|
Ọjọ́ Àìkú · Ọjọ́ Ajé · Ọjọ́ Ìsẹ́gun · Ọjọ́rú · Ọjọ́bọ̀ · Ọjọ́ Ẹtì · Ọjọ́ Àbámẹ́ta |