Ìgbìmọ̀ Òpútà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìgbìmọ́ Òpútà ni ìgbìmọ̀ tí ó túmọ̀ sí "Ìgbìmọ̀ tí ó ń rí sí ìwádí ìlòdì sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Jẹ́ ìgbìmọ̀ tí ọ̀gágun àti Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ fu lọ́lẹ̀ lẹ́yìn ìṣubú ìjọba ológun tí ó ti jẹ gàba ní orí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà títí di ọdún 1998. [1]  In terms of reconciliation, the commission also worked towards unifying communities previously in conflict.[2] Ojú ṣe ìgbìmọ̀ yí ni láti ṣe ìwádí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí àwọn ìjọba ológun ti tẹ̀ lójú lásìkò tí wọ́n ń jẹ gàba, kí wọ́n sì pẹ̀tù sí aáwọ̀ náà, pàá pàá jùlọ kí wọ́n mú Irẹ́pọ̀ wà láàrín ìlú, agbègbè àti àwùjọ tí yánpọn yánrin ti wà tẹ́lẹ̀. [3]

Ìpìlẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wíwà tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà lábẹ́ ìjọba amúnisìn títí di ọdún 1960 tí a gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba HGẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn ìgbòmìnira yí, oríṣiríṣi dàgbà-dìyàn ogun abẹ́lé ni ó bẹ́ sílẹ̀ tí ó sì mú ìfàsẹ́yìn bá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti wà ní ìrẹ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan.[4] Àwọn ìṣòro bí ìjà ẹ̀sìn, ẹlẹ́yà-mẹ̀yà, tí ó mú kí ogun abẹ́lé tí ó bẹ́ sílẹ̀ pẹ́ nílẹ̀ títí di ọdún 1970, ní èyí tí ó mú kí orílẹ̀-èdè náà ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba ológun, tí ogunlọ́gọ̀ ẹ̀mí sì ṣòfò. [4] Bí orílẹ̀-èdè yí ṣe wà láboẹ́ ìṣàkóso ìjọba ológun apàṣẹ wàá, oríṣiríṣi ìdìtẹ̀ gbàjọba ni ó ṣẹlẹ̀, ní èyí tí ìdìtẹ̀-gbàjọba ọdún 1966 bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, títí di àsìkò ìjẹ gàba Ọ̀gágun Ibrahim Babangida tí rògbòdìyàn ìdàbònù tí gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dì yan ní ọdún Olóyè MKO Abiọ́lá. Ìṣẹ̀lẹ̀ yí ni ó sì lé Babangida kúrò lórí ìtẹ́ ní ọdún 1993. [4] Wàhálà òun rògbòdìyàn tún tẹ̀ síwájú nígbà tí Ọ̀gágun Sani Abacha gba ìjọba lẹ́yìn Bàbángídá tí òun náà sì papò dà ní ọdún 1998. Iku Abacha ni ó sì gbe Ọ̀gágun Oluṣẹ́gun Ọbásanjọ́ dé ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ nínú ìjọba Awa arawa.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Hayner, Priscilla B. (2010-09-13). Unspeakable Truths. doi:10.4324/9780203867822. ISBN 9780203867822. 
  2. Nnamani, S. O. (2011-01-01). "Institutional Mechanisms for Human Rights Protection in Nigeria: An Appraisal" (in en). Nnamdi Azikiwe University Journal of International Law and Jurisprudence 2. ISSN 2276-7371. https://www.ajol.info/index.php/naujilj/article/view/82393. 
  3. Bakiner, Onur (2016) (in en). Truth Commissions: Memory, Power, and Legitimacy. University of Pennsylvania Press. ISBN 9780812247626. https://books.google.com/?id=hfZYrgEACAAJ&printsec=%20%20frontcover#v=onepage&q=nigeria&f=false. 
  4. 4.0 4.1 4.2 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :1