Òkè Ìlá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Òkè-Ìlá Òràngún (tí a ma n gé kúrú sí Òkè-Ìlá) jẹ́ ìlú àdàyé bá ní ìhà gúsù-iwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàíjíríà tí o ti fi ìgbà kan jẹ́ olú-ìlú ẹ̀yà àwọn Igbomina-Yoruba tí a n fi orúko kan an naa pe.

Òkè-Ìlá jẹ́ ọ̀kan l'ára àwọn ìlú tí o wa ní ìpínlẹ̀ Ọṣun, ní orílẹ̀-èdè Nàíjíríà. Òkè-Ìlá wa ni apá ìhà àríwá ilà-oòrùn ilẹ̀ Yoruba ni gúsù-iwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàíjíríà. Òkè-Ìlá ní ìlú kan tí o sunmọ, èyí ti ìtàn sọ fún wa pé ìbátan rẹ ni, tí a n pe ni Ìlá Òràngún. Ìlá Òràngún wa ní ìwọn kìlómítà méjìlá (maili meje ati aabọ) si ìhà ariwa-ilà-oòrùn, àwọn ọ̀gbun ti o ti ìhà ariwa wá si pin wọn si ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ti a mọ si Òkè-Ìlá.

Òkè-Ìlá Òràngún ni olú-ìlú fún ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́dayọ̀ ní ìpínlè Ọṣun. Olú Ilé-ìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́dayọ̀ wa ni ìhà ariwa etí ìlú náà. Àmójútó iṣe'jọba àwọn ilu mejeeji yi, ati ti àwọn ìlú kéréje-kéréje pẹlu àwọn igberiko ti o yi wọn ka ni on ti olú Ilé-ìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́dayọ̀ jade wa.