Aalo Ìjàpá àti ọmọ òrùkan meta

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ààlọ́ oooo

Ààlò

Ààlọ́ mi dá firigbagbo ó dá lórí Ìjàpá àti àwọn ọmọ òrukàn mẹ́ta kan.

Ní ìgbà láéláé, àwọn ọmọ òrukàn mẹ́ta kan wà tí orúkọ wọn ní jẹ́ Otarún, Akọpe, àti Awẹkun[1].

Àwọn ọmọ yìí pinnu láti bẹ̀rẹ̀ isẹ owó, láti ìgbà tí òbí àwọn ọmọ yìí tí kú, Ìjàpá máa ń tọju wọn, ó sì máa ń gbà wọn ní ìyànjú leèkọ̀ọ̀kan.

Àwọn meteeta forí lé ilé Ìjàpá. Nígbà tí wón dé ibè wọn ki, òun náà sì kí wọn dáadáa . Ó fún wọn ní obì, gbogbo wọn sì jókòó ní abé igi níwájú ilé rè .

Otarun ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Ó ní, ‘Èmi àti àwọn àbúrò mi fẹ́ níláti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ gidigidi Ìjàpá , fún akitiyan rẹ lórí wa látìgbà tí àwọn òbí wa ti fi ayé silẹ. Ohun tí a mú wá sódo rẹ lónìí ni wípé àwa fẹ́ kí o gbà wá níyànjú nípa ọ̀rọ̀ isẹ . A fẹ́ láti lọ kọ́ isẹ .

Ìjàpá mí kanlẹ̀ , ó wọ òkè ó wo ilẹ̀ . Ó ní e seun, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín wípé , ẹ ò fojú di àgbà. Inú mi sì dùn lọpọlọpọ pé ẹ ń fẹ́ láti kọ isẹ. Èmi yóò sì gbà yín níyànjú wípé kí ẹ wá bá mi da owo pọ, kí ẹ wá bá mi ṣe iṣẹ́ pọ.

Àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta yìí wo ojú ara wọn. Akope dáhùn pé , ‘ìyẹn ni wípé oníṣòwò ni ìwọ Ìjàpá, àwa kò mọ.

Ìjàpá rẹ rin ó ní , ‘Oníṣòwò ni mí. Ṣùgbọ́n isẹ ọpọlọ ni òwò tèmi ki í se isẹ agbára. Ẹ kò se àkíyèsí pé nkò ní oko, nkò sì ní abà; èmi kì í sì í ra ọjà, nki í sì í tá ọjà. N kò sì se isẹ ìjọba, bẹ́ẹ̀ ni n ò ní ọ̀gá . Ṣùgbọ́n, mo ń jẹ , mo ń mu láìṣe aláìní ohunkóhun.

Àwọn ọmọ ìyá yìí tún wo ara wọn tìyanutìyanu, wọ́n sì tún wo Ìjàpá tìfuratìfura. Ìjàpá dáhùn ó ní , ‘Kílódé tí ẹ fi ń wo mí bíi ẹni pé mo gbé idà sókè láti fi bẹ yín lórí? Ṣé ẹ rò pé alónilọ́wọ́gbà ni mí ni? Èmi kì í se jàǹdùkú o. Ó kàn jẹ́ pé ohunkóhun tí mo bá fẹ́ , n ó ri gbà.

Àwọn ọmọkùnrin yìí kò mọ ohun tí wọn ó fi fèsì. Lẹ́hìn ìṣẹ́jú díè, Otarun dìde ó ní, ‘àwa yíò lọ ro ọ̀rọ̀ tí o fi lọ wa wò, àwa yíò sì fèsì bó bá d’ola’.

Ní ọjọ́ kejì, Otarun nìkan ló lọ sí ilé Ìjàpá , ó sì wí fun pé, ‘Èmi àti àbúrò mi ti ro ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi

lọ wa, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ìmọ̀ràn náà, Ṣùgbọ́bon a ko lè bá ọ ṣiṣẹ́,nítorí pé olótìító ènìyàn ni awa, a fẹ láti fọwọ́ wa se isẹ aṣekáka. Inú bí Ìjàpá púpò , Ojú rẹ̀ sì pón, ó ní ,Aláìmoore ni ẹyin ọmọdé wọ̀nyí, Ṣé ohun tí ẹ ó fi san oore láti ìgbà ítàwọwoòbíbiíy tí àwọn òbí wọn tí jáde kúrò láyé nìyẹn?’

Otarun dáhùn ó wípé , ‘Bẹ́ẹ̀ ni’. Ìjàpá sì wí fún wípé , Bí ó bá wá rí bẹ o, èmi Ìjàpá ti di ọ̀tá yín, èmi o sì fi ojú yín rí èèmọ

Lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ díè, àwọn ọmọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí kó isẹ òwò, wọn sì ṣiṣẹ́ kárakára. Wọ́n se isẹ wọn láṣẹ yọrí ; láìpẹ Otarun bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ọdẹ, ó sì seé ó ní òkìkí nínú isẹ rẹ. Akọpẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síise isẹ emu dídá; bẹẹni Awẹ’kun sise apeja tí ó sì lókìkí láàrin ìlú, nítorí ẹja rẹ a máa tóbi.

Ní ọjọ́ kan, Ìjàpá lọ sí ààfin oba láti sọ fún ọba wípé àwọn ọmọkùnrin yìí fẹ́ da ìlú rú. Èyí ya ọba lénu, ó sì ní kí Ìjàpá se aláyè ọ̀rọ̀. Ìjàpá dáhùn wípé àwọn ọmọkùnrin náà ń parọ káàkiri wípé àwọn le se ohun abàmì tí ẹ̀dá kan kò le è ṣe. Wọ́n ní àwọn le ta ọfà tí yíò kan òfuurufú. Ọkan ní òun le è gun igi ọ̀pẹ laini igbà. Èyí tí ó tí ẹ yàmi lénu jùlọ , òun ní eléyìí àbígbeyìn, ó ní òun le e wẹ òkun já láàrin ìṣẹ́jú kan. Ha! Kábiyèsí , ohun tí ó ńbàmí lẹ́rù ni pé, àwọn ìlú tí ó yí wa ká, tí wọ́n bá gbó ọ̀rọ̀ tí àwọn ọmọkùnrin yìí ń sọ nípa pé àwọn le e se isẹ abàmì i yìí , ìlú wa yíò di ìlú àwọn oníró eléyìí ní sì leè mú àbùkù wá fún wa, Kabiyesi. Ni Ìjàpá bá parí ọ̀rọ̀ rẹ . Inú bí ọba , ó sì ránṣé pe àwọn ọmọ mẹ́ta wọ̀nyí. Nígbà tí wọn dé ààfin, ó pàṣẹ fún wọn pé lẹ́hìn ọjọ́ méje, Otarun gbodọ̀ mú ọfà wá láti ta, kí ọfà náà kan Òfurufú. Akope gbọ́dọ̀ gùn igi láìsí igbà. Awekun yíò sì wẹ òkun já láàrín ìṣẹ́jú kan. Àwọn ọmọkùnrin yìí bẹ ọba , wọn ní àwọn kò mọ ìdí ọ̀rọ̀ tí oba fi lọ àwọn yìí , àwọn ò sì mọ ìdí tí ọba fi ń bínú sí àwọn . Ọba dáhùn pé a tí fi tó òun létí wípé àwọn ọmọkùnrin yìí ń fon-nu pé àwọn le è se ohun abàmì. Òun sì fé kí wọn se gbogbo nǹkan tí wọn ń fọ́n nu pé àwọn lè se. Lẹ́hìn èyí, ọba pàṣẹ fún àwọn dòǹgárì rẹ pé kí won maa sọ́ àwọn ọmọ ìyá mẹteeta náà, wọ́n ko sì gbọ́dọ̀ jẹ́kí wọn kúrò láàrin ìlú. Inú àwọn ọmọkùnrin meteeta náà bàjé gbáà ; wọn mọ pé Ìjàpá ni ó wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí , ṣùgbọ́n wọn kò mọ ohun tí wọ́n le e se. Ọba tilè ti pàṣẹ fáwọn dongari rẹ pé wọn gbọ́dọ̀ má a sọ́ wọn, wọn ò si gbọ́dọ̀ kúrò láàrin ìlú . Pẹ̀lú ìrònú àti iteriba ni àwọn meteeta fi kúrò ní ààfin lọ́jọ́ náà .

Ní òwúrò kùtùkùtù ọjọ́ kan, àwọn ọmọkùnrin yìí tajú lójú oorun; orin ẹyẹ abàmì kan ló jí won.  Wọn súrédìde , wón sí fèrèsé ilé won láti wo ẹyẹ yìí . Ẹyẹ náà lé góńgó sórí igi tí ó wà lẹ́bàá ilé wọn , ó sì ń kọrin pé :[2]

Orin Ààlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọmọdé mẹ́ta ń ṣeré

Eré o o o o ére ayò

Ọmọdé mẹ́ta ń ṣeré

Eré o o o o ére ayò

Ọkàn lòun ó tà’run

Eré o o o o ère ayò

Ọkàn lòun ó gàgbon

Eré o o o o ere ayò

Ọkàn lòun ó we’kun

Ere o o o o ère ayọ̀

Ota’run, Og’agbon, Owe’kun

Eré o o o o ere ayò

Ota’run, Og’agbon, Owe’kun

Ere o o o o ere ayo

Ota’run, Og’agbon, Owe’kun

Ere o o o o ere ayo.

Nígbà tí ẹyẹ yìí parí orin rẹ, ó fò lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọmọkùnrin yìí dá ké jẹ̃ lojukanna ń ibiti wọn wa; wọn sì dúró si i.

Otarun tajú kán , ó sì rí ọfà àti ọ̀run kan lẹgbẹ ibiti ẹyẹ náà tí fò kúrò; lẹgbẹ ibè ni , ó rí igbà, àti i ọjà ìlú we kan lójúkanna ń ibiti ẹyẹ náà ti fò kúrò . Àwọn n ọmọkùnrin yìí sáré lọ síbè, onikaluku mú ohun ti o jọ mọ isẹ rẹ , wọn sì wọlé lọ .

L àìpé , wọn lọ sí ààfin láti lọ rí ọba ; ọba sì pàṣẹ fun won pé , ní ọ̀kọ̀ọ̀kan kí wọn bẹ̀rẹ̀ sí í se ohun tí wón fon-nu láti se. Ó kọjú sí Otarun o wípé , ‘Ìwọ ta ọfà , kí o sì kan Òfurufú. Ní kíá mọsá , Otarun mú ọrun àti ọfà rẹ, ọrùn tí ẹyẹ yìí ti fi sílè , ó jẹ orun abàmì, kò sí ẹnikẹ́ni tó le e rí , yàtò sí àwon ọmọ ìyá mẹ́ta yìí. Otarun mú ọfà rè àti ọrun náà , ó ta ọfà, làìpé ofa yìí fò lọ, ó sì kan ojú ọrun . Gbogbo àwọn eeyan tó wà nibẹ bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́, tí wọn sì ń kọrin tí wọ́n sì ńlùlù tí wọn sì ń jó , wón wípé a ò rí irú eléyìí rí.

Lẹ́hìn náà , ọba kojú sí Akope, ó ní ‘Ó yá o, Akope. O ní láti gun ọpẹ láìsí igbà ’ Akope mú igba tí o ti mú wá láti lé , eleyii ti ẹyẹ abàmì náà ti fi sílè fun wọn . Ó mú igbà náà , ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gun igi ọpẹ ; ó ń sáré gùn ún , ó ń gùn Tagbáratagbára. L àìpé , láì jìnà ó gùn ọpẹ járí láìsí igbà . Gbogbo àwọn ènìyàn n tún bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe , wọ́n ńpatẹ́wọ́ .

Ọba ti bẹ̀rẹ̀ sí í dá ké sii, ara rẹ sì bẹ̀rẹ̀ sii balẹ̀ . Ó rú ú lójú , ‘báwo ni àwọn ọmọ yìí se le se àwọn ohun abàmì yìí ?’ Ṣùgbọ́n láìpé , laijina ó kojú sí Awe’kun ó ní , Ó yá o, mú wa lọ sí etí omi, ó ní láti wẹ òkun já.

Láàrin ìṣẹ́jú kan, Awe’kun saaju, gbogbo ìlú sì tẹ̀le. Ó mú ọjà abàmì tí ẹyẹ náà tifi silẹ. Nigbati won de ibi etí omi, ó kán lu omi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lú wẹ e. Ó luwe lọ sókè sódo , láàrin ìṣẹ́jú kan, ó ti luwe tán . Gbogbo ìlú ń pariwo , wón ń hó yee, wọn ńṣe hà! Wọn ní a kò ri irú eléyìí rí o. Ẹnu ya gbogbo won, báwo ló se se e? Ìjàpá rò pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ri òun. Ó sì yọ́ kọ́rọ́, ó fẹ́ má a sá lọ. Ṣùgbọ́n ọkàn nínú àwon dongari ọba kìí mọ́lẹ̀ , ó gbé , o ní, ‘Níbo ni ìwọ rò pé ìwọ ń lọ ? Ìwọ eranko búburú yìí . Ó gbe sí èjìká rẹ, gbogbo ìlú sì kori sí ààfin ọba. Àwọn ọkùnrin àdúgbò , wọn gbé àwọn ọmọkùnrin yìí sí èjìká , wón ń kọrin , wọ́n ńlùlù , wọn ń hó yeee, gbogbo ìlú ndunnu lọpọlọpọ fún ohun ńláńlá tí àwọn ọmọ wọ̀nyí se.

Nígbà tí wọn dé ààfin , ọba sọ fún wọn wípé , òun fẹ́ bẹ wọn pé kí wọn má bínú ẹ̀sùn tí òun fi kàn wọn . Ọba kọjú sí Ìjàpá ó ní, ‘Ìjàpá , eranko búburú ni o; ẹ̀wọ̀n tí o fẹ kí àwọn ọmọkùnrin yìí lọ , ìwọ ni yíò lọ sí ẹ̀wọ̀n náà. Ó wá kọjú sí àwọn ọmọkùnrin n náà ó ní, ‘Mo fẹ́ kí eyin meteeta kí e di olóyè ní ààfin mi’. Gbogbo ìlú hó yeee! Wọn ń kọrin , àwọn onílù si ń lu ìlù, wọn ń yọ ; wọn si ń bá àwọn ọmọkùnrin yìí yọ fún ohun ńláńlá tí wọ́n se.

Ẹ̀kọ́ Inú Ààlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààlọ́ yìí kò wá pé kí a máa gbẹ ọmọnìkejì lẹsẹ yálà níbi isẹ tàbí níbikíbi.

Kí a múra sì ìṣe tí a yàn láàyò ká má kò ẹgbẹ́ kẹgbẹ́.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales