Adebáyò Faleti

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Adebayo Faleti
Ọjọ́ìbí26 Oṣù Kejìlá 1930 (1930-12-26) (ọmọ ọdún 93)
Kasmo, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian Nàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ibadan, Nigeria
Iṣẹ́Osere, Akewi, Onkowe

Adébáyọ̀ Àkàndé Fálétí (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá 1930) jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Akéwì , Olùkọ̀tàn, àti eléré orí-Ìtàgé, bákan náà ni ó tún jẹ́ oǹgbufọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá, ó sìn tún jẹ́ Omíròyìn orí Ẹ̀rọ asoro-ma-gbesi Radio, Olóòtú ètò orí Tẹlifíṣọ̀n TV, àti Olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ Afíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Western Nigeria Television (WNTV).[1][2]

Adébáyọ̀ Fálétí náà ló ṣe ògbufọ̀ orin àmúyẹ orílẹ̀-èdè Naigerian National Anthem láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè abínibí Yorùbá. Bákan náà ni ó tún ṣe oǹgbufọ̀ fún ohun tí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí lásìkò Ológun, ìyẹn Ibrahim Babangida sọ, pẹ̀lú tí Ààrẹ-fìdíhẹ nígbà ayé Ológun kan rí Chief Ernest Shoneka, nípa lílo èdè Yorùbá tó gbámúṣé. Fálétí ti tẹ Ìwé-Atúmọ èdè Dictionary Yorùbá ní èyí tí ó ní àbùdá ògidì Yorùbá nínú. Adébáyọ̀ Fálétí ti gba onírúurú àmì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá oríṣiríṣi nílẹ̀ yìí àti lókè Òkun pẹ̀lú.[3] [4]

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Obìin mẹ́ìndínlógún
  2. N ní ń bẹ́ lọ́ọ̀dẹ̀ẹ Ṣàngó
  3. Ńbi ká sánpá
  4. Ńbi ká yan
  5. LỌyá fi gbọkọ lọ́wọ́ọ gbogbo wọn 5
  6. Ńbii ká sọ̀rọ̀, ká fa kòmóòkun yọ
  7. N la ṣe ń perúu yín léléwì pàtàkì
  8. Fohùn òkè ta ko tìsàlẹ̀ nìkan
  9. Kọ́ là ń pè léwì
  10. Yàtọ̀ sáfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ àti tààrà 10
  11. Òwe tún ń bẹ rẹrẹrẹ
  12. Wọn a sọ̀rọ̀ tó gbayì létè
  13. Wọn a fi wíwúni lórí lé e
  14. Èyún-ùn nìkan kọ́, kò sẹ́ni tí ò mọ̀yún-ùn
  15. Àní níbii ká máṣà ìṣẹ̀nbáyé 15
  16. Kí gbogbo rẹ̀ tún kú dùn-ún-ùn bí ojú afọ́jú
  17. N la ṣe ń peruu wọn ní baba
  18. Ẹni tó mọ̀Bàdàn tán tó tún mọ Láyípo pẹ̀lú ẹ̀
  19. Tó gbégùn tó gbọ́ wọ́yọ̀wọ́yọ̀
  20. Iwájú lọ̀pá ẹ̀bìtì ó kúkú máá ré sí 20
  21. A kò ní í sàìmáa rí yín bá


Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "7 things you probably didn't know about late actor". Entertainment. 2017-07-23. Retrieved 2019-12-15. 
  2. "Adebayo Faleti: The Passing of a Cultural Icon, By Akin Adesokan". Premium Times Opinion. 2017-09-27. Retrieved 2019-12-15. 
  3. PeoplePill (1930-12-26). "Biography, Life, Family, Career, Facts, Information". PeoplePill. Retrieved 2019-12-15. 
  4. "Ewi Adebayo Faleti-Iwe Kinni By Olatunde O. Olatunji". Sunshine Bookseller. Archived from the original on 2019-12-15. Retrieved 2019-12-15. 

Àdàkọ:Authority control