Ama Ata Aidoo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ama Ata Aidoo
Fáìlì:Ama Ata Aidoo.png
Ọjọ́ ìbíChristina Ama Ata Aidoo
(1942-03-23)23 Oṣù Kẹta 1942
Abeadzi Kyiakor, Gold Coast (now Ghana)
Ọjọ́ aláìsí31 May 2023(2023-05-31) (ọmọ ọdún 81)[lower-alpha 1]
Accra, Ghana
Iṣẹ́
  • Author
  • playwright
  • professor
Ẹ̀kọ́Wesley Girls' High School
Alma materUniversity of Ghana
Genre
  • Drama
  • fiction
  • poetry
Subject
Notable works
Notable awardsCommonwealth Writers' Prize
1992

Ama Ata Aidoo (tí wọ́n bí ní 23 March 1942 tó sì ṣaláàsí ní 31 May 2023)[1] jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ghana, òǹkọ̀wé, akéwì, olóṣèlú àti ọ̀mọ̀wé.[2][3] Òun ni Secretary for Education ti ìlú Ghana láti ọdún 1982 wọ 1983 lábẹ̀ ìṣèjọba Jerry Rawlings. Ìwé erẹ́-oníṣe rẹ̀ àkọ́kọ́ ni The Dilemma of a Ghost, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 1965, èyí sì mú kí Aidoo jẹ́ òǹkọ̀wébìnrin àkọ́kọ́ tó máa kọ ìtàn eré-oníṣe.[4] Gẹ́gẹ́ bí i òǹkọ̀wé ìtàn àròsọ, ó gba ẹ̀bùn ti Commonwealth Writers' Prize ní ọdún 1992 pẹ̀lú ìwé ìtàn-àròsọ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Changes. Ní ọdún 2000, ó ṣe ìdásílẹ̀ Mbaasem Foundation ní Accra lá́ti pèsè ìrànlọ́wọ́ àti láti ṣe ìgbélárúgẹ fún iṣẹ́ àwọn òǹkọ̀wébìnrin ilẹ̀ Africa.[5]

Ìbẹ̀rèpẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Christina Ama Ata Aidoo ní 23 March 1942 [6] sí ìlú Abeadzi Kyiakor, ní tòsí Saltpond, ní ààrin gbùngùn ilẹ̀ Ghana. Àwon orísun kan bí i [7] Megan Behrent, Brown University, àti Africa Who's Who) sọ ọ́ di mímọ̀ pé ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta ni wọ́n bí i.[8][9] Ìbeji ni, orúkọ èkejì rẹ̀ sì ni, Kwame Ata.[10][11]

Ilé ọlọ́lá ti Fante ni Aidoo dàgbà sí, òun sì ni ọmọbìnrin ti olóyè Abeadzi Kyiakor, àti Maame Abasema.[12] Àwọn amúnisìn ló pa bàba-bàbá àti ìya-bàbá rẹ̀,[13][14] èyí sì ló mú kí bàbá rẹ̀ sojú dé ẹ̀kọ́ àti ìwúlò rẹ̀, tí ó sì tiraka láti gba àwọn ènìyàn níyànjú kí wọ́n fún àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́ tó yanrantí. Látàrí èyí ni bàbá rẹ̀ fi ṣí ilé-ìwé àkọ́kọ́ sí ìlú wọn, tí ó sì mú kí Aidoo lọ sí Wesley Girls' High School, níbi tí ó ti pinnu láti di òǹkọ̀wé.[15]

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti ọdún 1957, Aidoo lọ sí Wesley Girls' Senior High School ní Cape Coast.[16][17] Lẹ́yìn tó parí ẹ̀kọ́ girama, ó lọ sí University of Ghana tó wà ní Legon, ní ọdún 1961. Ibẹ̀ sì ni ó ti gba ìwé-ẹ̀rí Bachelor of Arts nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí ó sì ti kọ ìwé eré-oníṣe rẹ̀ àkọ́kọ́, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Dilemma of a Ghost, ní ọdún 1964.[2] Ilé-iṣẹ́ atẹ̀wétà Longman ló tẹ̀ ẹ́ jáde, èyí sì mú kí Aidoo jẹ́ obìnrin ilẹ̀ Africa àkọ́kọ́ tó máa tẹ ìwé eré-oníṣe jáde.[4]

Ikú rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Aidoo kú ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2023 ní ìlú Accra.[18][19][20][21][22] Wọ́n gbóríyìn fún gẹ́gẹ́ bíi òǹkọ̀wé tó ta yọ, tó sì jà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ilẹ̀ Africa àti ìlọsíwájú àwọn ènìyàn ní àgbáyé. Èyí sì mú kí Ààrẹ Nana Akufo-Addo kéde rẹ̀ pé wọ́n máa fun ni ẹ̀yẹ-ìkẹyìn tó jọjú.[23][24] Wọ́n sì ṣe òkú yìí láti ọjọ́ kẹtàlá oṣù keje wọ ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje. [25][26][27] Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù keje, ètò ìsìnkú náà wáyé ní iwájú State House,[28] lẹ́yìn náà ni wọ́n lọ sin ín sí ìlú rẹ̀, ní Abeadze Kyiakor àti ètò ìdúpẹ́ ní ilé-ìjọsìn.[29][30]

Ìdálọ́lá àti ìṣàfihàn fún àmì-ẹ̀yẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Aidoo ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ bíi ti ẹ̀bùn Mbari Club ní ọdún 1962 fún ìtàn kékeré rẹ̀, ìyẹn "No Sweetness Here",[31] àti ẹ̀bùn ti ọdún 1992 fun Commonwealth Writers' Prize fún ìwé ilẹ̀ Africa tó dára jù lọ, ìyẹn Changes.[32]

Ní ọdún 2012, wọ́n ṣe àtẹ̀jáde ìwé Essays in honour of Ama Ata Aidoo at 70 èyí tí Anne V. Adams jẹ́ olóòtú fún, pẹ̀lú àfikún láti ọ̀dọ̀ àwọn òǹkọ̀wé bíi Atukwei Okai, Margaret Busby, Maryse Condé, Micere Mugo, Toyin Falola, Biodun Jeyifo, Kofi Anyidoho, Naana Jane Opoku-Agyemang, Naana Banyiwa Horne, Nana Wilson-Tagoe, Carole Boyce Davies, Emmanuel Akyeampong, James Gibbs, Vincent O. Odamtten, Jane Bryce, Esi Sutherland-Addy, Femi Osofisan, Kwesi Yankah, Abena Busia, Yaba Badoe, Ivor Agyeman-Duah, Chikwenye Okonjo Ogunyemi, Ngugi Wa Thiong'o, Kinna Likimani, àti others.[33][34][35]

Aidoo ni wọ́n fi sọrí fíìmù ọdún 2014 kan,tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ The Art of Ama Ata Aidoo, èyí tí Yaba Badoe ṣe.[36][37][38]

Wọ́n tún fi Ama Ata Aidoo sọrí Aidoo-Snyder Book Prize, tí ẹgbẹ́ àwọn obìnrin ti African Studies Association máa ń fún ìwé tó bá ta yọ. Wọ́n sì tún fi sọrí Margaret C. Snyder, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ UNIFEM.[39]

Ní ọdún 2016, wọ́n to àwọn eré-oníṣe Aidoo, ìyẹn The Dilemma of a Ghost àti Anowa pọ̀ mọ́ àṣàyàn African Drama ní Cambridge International Examinations.[40]

Wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ Ama Ata Aidoo Centre for Creative Writing (Aidoo Centre) ní oṣù kẹta ọdún 2017, èyí tó jẹ́ ara Kojo Yankah School of Communications Studies ní African University College of Communications (AUCC) ní Adabraka, Accra. Orúkọ rẹ̀ sì ni wọ́n fi sọrí ẹ̀ka yìí. [41] Ẹ̀ka yìí jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní West Africa, pẹ̀lú Nii Ayikwei Parkes, gẹ́gẹ́ bíi olùdarí.[42][43]

Àṣààyàn àwọn iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • The Dilemma of a Ghost (play), Accra: Longman, 1965. New York: Macmillan, 1971.[15][44][45][46]
  • Anowa (eré-oníṣe tó dá lórí akọni ilẹ̀ Ghana), London: Longman, 1970. New York: Humanities Press, 1970.[47]
  • No Sweetness Here: A Collection of Short Stories (Àkójọpọ̀ àwọn ìtàn kéékèèké) , London: Longman, 1970. New York: Doubleday.[48][49]
  • Our Sister Killjoy: or Reflections from a Black-eyed Squint (ìwé ìtàn-àròsọ), Longman, 1977.[15][50]
  • Someone Talking to Sometime (poetry collection), Harare: College Press, 1986.[49][51]
  • The Eagle and the Chickens and Other Stories (fún àwọn ọmọdé), Enugu: Tana Press, 1986.[49]
  • Birds and Other Poems, Harare: College Press, 1987.[51]
  • An Angry Letter in January (poems), Coventry: Dangaroo Press, 1992, ISSN 0106-5734[52]
  • Changes: A Love Story (ìwé ìtàn-àròsọ), London: The Women's Press, 1991. New York: The Feminist Press at CUNY, 1993.[15][53]
  • The Girl Who Can and Other Stories, Accra: Sub-Saharan Publishers, ISBN 978-0435910136; Heinemann African Writers Series, 1997.
  • Diplomatic Pounds & Other Stories, Ayebia Clarke Publishing, 2012, ISBN 978-0956240194.

Gẹ́gẹ́ bíi olóòtú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkọsílẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Many sources erroneously give 1942 as her date of birth.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Danquah, Nana-Ama (2 June 2023). "We are here: In memory of Ghanaian writer Ama Ata Aidoo". The Africa Report. Retrieved 14 August 2023. 
  2. 2.0 2.1 "Ama Ata Aidoo | Ghanaian writer". Encyclopædia Britannica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 9 March 2019. 
  3. Hugon, Anne (31 August 2021). "Aidoo, Ama Ata". African History. Oxford Research Encyclopedias. ISBN 978-0-19-027773-4. doi:10.1093/acrefore/9780190277734.013.469. Retrieved 29 April 2023. 
  4. 4.0 4.1 Banyiwa Horne, Naana (2001). "Aidoo, Ama Ata". Who's Who in Contemporary Women's Writing. Routledge. 
  5. "Welcome to Mbaasem". Mbaasem Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 9 March 2019. 
  6. "Late Prof. Ama Ata Aidoo to be honoured with state-assisted burial". Modern Ghana. 15 June 2023. 
  7. "Ama Ata Aidoo: Ghana's famous author and feminist dies" (in en-GB). BBC News. 2023-05-31. https://www.bbc.com/news/world-africa-65765581. 
  8. Behrent, Megan. "Ama Ata Aidoo: Biographical Introduction". www.postcolonialweb.org. Retrieved 9 May 2019. 
  9. Uwechue, Raph (1996). Africa Who's Who. London: Africa Books Limited. pp. 80–81. ISBN 9780798303446. 
  10. Odamtten, Vincent Okpoti (26 April 2000). "'For Her Own (Works') Quality' The Poetry of Ama Ata Aidoo". Matatu 21–22 (1): 209–216. doi:10.1163/18757421-90000320. 
  11. Okoampa-Ahoofe, Kwame Jr (6 September 2016). "Prof. Ama Ata Aidoo's action is about principles, not sheer human foibles". GhanaWeb. Retrieved 19 December 2021. 
  12. "AMA ATA AIDOO (1942–)", Postcolonial African Writers, Routledge, 1998.
  13. Diamond, Marie Josephine (2011) (in en). Encyclopedia of World Writers, 1800 to the Present. New York: Facts On File Library of World Literature. pp. 15. ISBN 978-0-8160-8204-9. https://books.google.com/books?id=4e23cQAACAAJ. 
  14. "FRANCIS IMBUGA (1947-)". Postcolonial African Writers. Routledge. 12 November 2012. pp. 260–265. doi:10.4324/9780203058558-25. http://dx.doi.org/10.4324/9780203058558-25. Retrieved 1 June 2023. 
  15. 15.0 15.1 15.2 15.3 "Her Story". BBC World Service Service. Retrieved 12 December 2020. 
  16. Innes, Lyn (11 June 2023). "Ama Ata Aidoo obituary". The Guardian. https://www.theguardian.com/books/2023/jun/11/ama-ata-aidoo-obituary. 
  17. Liukkonen, Petri. "Ama Ata Aidoo". Books and Writers (Authors Calendar). Finland. 
  18. "Renowned Ghanaian writer Prof. Ama Ata Aidoo is dead". GhanaWeb. 31 May 2023. Retrieved 31 May 2023. 
  19. "Ghanaian writer Prof Ama Ata Aidoo is dead". Graphic Online. 31 May 2023. Retrieved 31 May 2023. 
  20. "Ama Ata Aidoo: Ghana's famous author and feminist dies" (in en-GB). BBC News. 31 May 2023. https://www.bbc.com/news/world-africa-65765581. 
  21. Kubi, Vincent (31 May 2023). "Celebrated Playwright Prof Ama Ata Aidoo Is Dead". Daily Guide Network. 
  22. Yeboah-Afari, Ajoa (5 June 2023). "Remembering Professor Ama Ata Aidoo, our 'Auntie Ama'". GhanaWeb. Retrieved 24 June 2023. 
  23. Dapatem, Donald Ato (14 June 2023). "Prof Ama Ata Aidoo to be given state burial". Graphic Online. Retrieved 14 June 2023. 
  24. "Ghana: President Akufo-Addo Condoles With Family Of Ama Ata Aidoo …Renowned Author Gets State-Assisted Funeral". African Business. 15 June 2023. 
  25. "State-assisted funeral arrangements for Ama Ata Aidoo slated for July 13-16". GhanaWeb. 15 June 2023. 
  26. "Ama Ata Aidoo Goes Home In July". Daily Guide Network. 15 June 2023. Retrieved 24 June 2023. 
  27. Annang, Evans (15 June 2023). "Ama Ata Aidoo will get a state assisted funeral – Akufo-Addo". pulse.com.gh. Retrieved 24 June 2023. 
  28. "State funeral for Prof Ama Ata Aidoo on July 13". News Ghana. 3 July 2023. Retrieved 7 July 2023. 
  29. Ekuful, Cliff (14 July 2023). "A literary giant has fallen …President says as he mourns Ama Ata Aidoo". Ghanaian Times. https://www.ghanaiantimes.com.gh/a-literary-giant-has-fallen-president-says-as-he-mourns-ama-ata-aidoo/. 
  30. Ahiable, Gloria Kafui (13 July 2023). "The World Will Miss Ama Ata Aidoo – Akufo-Addo". The Ghana Report. Retrieved 21 August 2023. 
  31. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named Encyclopedia.com
  32. Verge, Violetta Jojo (2015) (PDF). The Re-Presentation of Africa and the African in Anglophone West African Literature: Buchi Emecheta and Ama Ata Aidoo. San Cristóbal de La Laguna, Spain. https://riull.ull.es/xmlui/bitstream/handle/915/26471/Violetta%20Jojo%20Verge.pdf?sequence=1&isAllowed=y. 
  33. Adams, Anne V., ed (2012). Essays in Honour of Ama Ata Aidoo at 70 : A Reader in African Cultural Studies. Ayebia. ISBN 9780956930705. https://library.villanova.edu/Find/Record/1397717/TOC. 
  34. "Ama Ata Aidoo At 70 – New African Magazine". newafricanmagazine.com. March 2012. Retrieved 25 April 2020. 
  35. "Essays in Honour of Ama Ata Aidoo at 70: A Reader in African Cultural Studies | Table of Contents". Barnes & Noble. Retrieved 30 April 2023. 
  36. "The Art of Ama Ata Aidoo – a film by Yaba Badoe", official website.
  37. Ellerson, Beti (December 2013), "Yaba Badoe talks about the documentary film project 'The Art of Ama Ata AidooÀdàkọ:'", African Women in Cinema.
  38. Chambas, Shakira, and Sionne Neely, "The Art of AMA ATA AIDOO: Documentary Film Launch", African Women's Development Fund, 26 September 2014.
  39. "Aidoo-Snyder Book Prize By-Laws" Archived 28 June 2016 at the Wayback Machine., ASA Women's Caucus.
  40. Haffar, Anis (28 September 2016). "The literary genius of Ama Ata Aidoo". Education Matters with Anis Haffar. Retrieved 15 July 2023. 
  41. "AUCC Launches Ama Ata Aidoo Centre for Creative Writing", Modern Ghana, 15 March 2017.
  42. Murua, James (22 March 2017), "Ama Ata Aidoo Centre for Creative Writing opens in Accra, Ghana", James Murua Blog. Archived 26 January 2023 at the Wayback Machine..
  43. Tandoh, Kwamina/Winifred Zuur, "Ama Ata Aidoo Centre for Creative Writing inaugurated", Ghana News Agency, 16 March 2017.
  44. Owomoyela, Oyekan (2008). The Columbia Guide to West African Literature in English. p. 64. 
  45. Dodgson-Katiyo, Pauline (1 November 2016). "Ama Ata Aidoo, Dilemma of a Ghost". The Literary Encyclopedia. https://www.litencyc.com/php/sworks.php?rec=true&UID=9399. Retrieved 10 April 2023. 
  46. Thompson, Clifford, ed (1999). World Authors 1990–1995. H.W. Wilson. p. 6. 
  47. Haffar, Anis (15 September 2016). "Ghana's precious playwright, Ama Ata Aidoo". Education Matters (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 8 March 2021. 
  48. Killam, G. D. (1971). "Modern Black African Writing in English: A Selected Bibliography". Twentieth Century Literature 17 (1): 37–47. ISSN 0041-462X. JSTOR 606803. https://www.jstor.org/stable/606803. 
  49. 49.0 49.1 49.2 "Anglophone and Lusophone African Writers (A Bibliography of Anglophone Women Writers)". University of Exeter. Archived from the original on 22 April 2003. 
  50. Kern, Anita, "Ama Ata Aidoo. Our sister killjoy. London: Longman, 1977" (review), World Literature Written in English, Volume 17, 1978 – Issue 1, pp. 55–57; via Taylor & Francis Online.
  51. 51.0 51.1 Warren, Crystal (2007). "A Bibliography of Zimbabwean Poets". English in Africa 34 (2): 111–121. ISSN 0376-8902. JSTOR 40239082. https://www.jstor.org/stable/40239082. 
  52. Aidoo, Ama (11 June 2019). "Poems". Kunapipi 14 (1). ISSN 0106-5734. https://ro.uow.edu.au/kunapipi/vol14/iss1/20. 
  53. Simpson, Waleska Saltori. Àdàkọ:"'What Fashion of Loving Was She Ever Going to Consider Adequate?' Subverting the 'Love Story' in Ama Ata Aidoo's Changes". English in Africa, 34.1 (2007): 155–71. Print.